God
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God
Olúwa ti dá ọ̀pá ìkà náà, ọ̀pá àwọn aláṣẹ,
Ìwọ sọ nínú ọkàn rẹ pé, “Èmi yóò gòkè lọ sí ọ̀run; èmi yóò gbé ìtẹ́ mi sókè ga ju àwọn ìràwọ̀ Ọlọ́run, Èmi yóò gúnwà ní orí òkè àpéjọ ní ṣóńṣó orí òkè mímọ́.
Èmi yóò gòkè lọ rékọjá àwọn àwọsánmọ̀; èmi yóò ṣe ara mi gẹ́gẹ́ bí Ọ̀gá-ògo.”
“Èmi yóò dìde sókè sí wọn,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. “Èmi yóò ké orúkọ rẹ̀ kúrò ní Babeli àti àwọn tí ó sálà, àwọn ọmọ àti ìran rẹ̀,” ni Olúwa wí.
Èmi yóò yí i padà sí ibùgbé àwọn òwìwí àti sí irà; Èmi yóò fi ọwọ́ ìparun gbá a, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti búra, “Gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣètò, bẹ́ẹ̀ ni yóò rí, àti bí mo ti pinnu, bẹ́ẹ̀ ni yóò sì dúró.
Èmi yóò run Asiria ní ilẹ̀ mi, ní àwọn orí òkè mi ni èmi yóò ti rún un mọ́lẹ̀. Àjàgà rẹ̀ ni a ó mú kúrò lọ́rùn àwọn ènìyàn mi, ẹrù u rẹ̀ ni ó mú kúrò ní èjìká wọn.”
Nítorí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti pète, ta ni yóò sì ká a lọ́wọ́ kò? Ọwọ́ọ rẹ ti nà jáde, ta ni ó sì le è fà á padà?
Kí ni ìdáhùn tí a ó fún agbẹnusọ orílẹ̀-èdè náà? “Olúwa ti fi ìdí Sioni kalẹ̀, àti nínú rẹ̀ ni àwọn ènìyàn rẹ̀ tí a ti pọ́n ọn lójú yóò ti rí ààbò o wọn.”
Omi Dimoni kún fún ẹ̀jẹ̀, síbẹ̀ èmi ó tún mu ohun tí ó jù báyìí lọ wá sórí Dimoni— kìnnìún kan wá sórí àwọn ìsáǹsá Moabu àti lórí àwọn tí ó tún ṣẹ́kù sórí ilẹ̀ náà.
Jẹ́ kí àwọn ìsáǹsá Moabu gbé pẹ̀lú rẹ, jẹ́ ààbò fún wọn kúrò lọ́wọ́ ìparun.” Aninilára yóò wá sí òpin, ìparun yóò dáwọ́ dúró; òfinràn yóò pòórá kúrò lórí ilẹ̀.
Nínú ìfẹ́ a ó fi ìdí ìjọba kan múlẹ̀, ní òdodo ọkùnrin kan yóò jókòó lórí rẹ̀ ẹnìkan láti ilé Dafidi wá. Ẹni yóò ṣe ìdájọ́, yóò sì máa wá ìdájọ́, yóò sì máa yára wá ohun tí í ṣe òdodo.
Nítorí náà mo sọkún, gẹ́gẹ́ bí Jaseri ṣe sọkún, fún àwọn àjàrà Sibma. Ìwọ Heṣboni, ìwọ Eleale, mo bomirin ọ́ pẹ̀lú omi ojú! Igbe ayọ̀ lórí àwọn èso pípọ́n rẹ àti lórí ìkórè èyí tí o ti mọ́wọ́ dúró.
Ayọ̀ àti ìdùnnú ni a ti mú kúrò nínú ọgbà-igi eléso rẹ; kò sí ẹnìkan tí ó kọrin tàbí kígbe nínú ọgbà àjàrà: ẹnikẹ́ni kò fún ọtí níbi ìfúntí, nítorí mo ti fi òpin sí gbogbo igbe.
Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa ti sọ nípa Moabu.
Ṣùgbọ́n ní àkókò yìí Olúwa wí pé, “Láàrín ọdún mẹ́ta gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀fà tí ó wà lábẹ́ ìdè ọgbà rẹ̀ ti máa kà á, ògo Moabu àti àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn rẹ̀ ni a ó kẹ́gàn, àwọn tí ó sálà nínú rẹ̀ yóò kéré níye, wọn yóò sì jẹ́ akúrẹtẹ̀.”
Ìlú olódi ni yóò pòórá kúrò ní Efraimu, àti agbára ọba kúrò ní Damasku; àwọn àṣẹ́kù Aramu yóò dá gẹ́gẹ́ bí ògo ti àwọn Israẹli,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
Síbẹ̀síbẹ̀ irúgbìn díẹ̀ yóò ṣẹ́kù, gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí a gbọn igi olifi, tí èso olifi méjì tàbí mẹ́ta ṣẹ́kù sórí ẹ̀ka tí ó ga jùlọ, mẹ́rin tàbí márùn-ún lórí ẹ̀ka tí ó so jù,” ni Olúwa wí, àní Ọlọ́run Israẹli.
Ní ọjọ́ náà, àwọn ènìyàn yóò gbójú sókè sí Ẹlẹ́dàá wọn, wọn yóò sì síjú wo Ẹni Mímọ́ Israẹli.
Nítorí ìwọ ti gbàgbé Ọlọ́run ìgbàlà rẹ; tí ìwọ kò sì náání àpáta ìgbàlà rẹ̀, nítorí náà ni ìwọ ti gbin ọ̀gbìn dáradára ìwọ sì tọ́ àjèjì ẹ̀ka sínú rẹ̀.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn ń bú ramúramù gẹ́gẹ́ bí ìrúmi odò, nígbà tí ó bá wọn wí wọ́n sálọ jìnnà réré, a tì wọ́n lọ gẹ́gẹ́ bí ìyàngbò ní orí òkè, àti gẹ́gẹ́ bí ewéko níwájú ìjì líle.
Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún mi: “Èmi yóò dákẹ́ jẹ́ẹ́, èmi yóò sì máa wo òréré láti ibùgbé e mi wá, gẹ́gẹ́ bí ooru gbígbóná nínú ìtànṣán oòrùn, gẹ́gẹ́ bí òjò-dídì ní àárín gbùngbùn ìkórè.”
Nítorí, kí ìkórè tó bẹ̀rẹ̀, nígbà tí ìrudí bá kún, nígbà tí ìtànná bá di èso àjàrà pípọ́n. Òun yóò sì fi dòjé rẹ́ ẹ̀ka tuntun, yóò sì mu kúrò, yóò sì gé ẹ̀ka lulẹ̀.
Ní àkókò náà ni a ó mú ẹ̀bùn wá fún Olúwa àwọn ọmọ-ogun láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn gíga tí ẹran-ara wọn jọ̀lọ̀, láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tí a bẹ̀rù níbi gbogbo, orílẹ̀-èdè aláfojúdi àti alájèjì èdè, ilẹ̀ ẹni tí omi pín sí yẹ́lẹyẹ̀lẹ— a ó mú àwọn ẹ̀bùn náà wá sí òkè Sioni, ibi tí orúkọ Olúwa àwọn ọmọ-ogun gbé wà.
Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Ejibiti. Kíyèsi i, Olúwa gun àwọsánmọ̀ tí ó yára lẹ́ṣin ó sì ń bọ̀ wá sí Ejibiti. Àwọn ère òrìṣà Ejibiti wárìrì níwájú rẹ̀, ọkàn àwọn ará Ejibiti sì ti domi nínú wọn.