Fò sí àkóónú

God

11,427 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Mose sì wí fún Ọlọ́run pé, “Bí mo bá tọ àwọn ará Israẹli lọ tí mo sì sọ fún wọn pé, ‘Ọlọ́run àwọn baba yín ni ó rán mi sí i yín,’ tí wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ mi pé, ‘Kí ni orúkọ rẹ̀?’ Kí ni èmi yóò sọ fún wọn ní ìgbà náà?”

  2. Ọlọ́run sì sọ fún Mose pé, “èmi ni ti ń jẹ́ èmi ni. Èyí ni ìwọ yóò sọ fún àwọn ará Israẹli: ‘èmi ni ni ó rán mi sí i yín.’ ”

  3. Ọlọ́run sì wí fún Mose pẹ̀lú pé, “Báyìí ni kí ìwọ sọ fún àwọn ọmọ Israẹli, ‘Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín; Ọlọ́run Abrahamu, Ọlọ́run Isaaki àti Ọlọ́run Jakọbu; ni ó rán mi sí i yín.’ “Èyí ni orúkọ mi títí ayérayé, orúkọ ti ẹ ó fi máa rántí mi láti ìran dé ìran.

  4. “Lọ, kó àwọn àgbàgbà Israẹli jọ, kí o sì wí fún wọn pé, ‘Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín, Ọlọ́run Abrahamu, ti Isaaki, àti ti Jakọbu; ni ó farahàn mi, ó sì wí pé, lóòótọ́ èmi ti ń bojú wò yín, èmi sì ti rí ohun tí wọ́n ṣe sí i yín ni ilẹ̀ Ejibiti.

  5. Èmi sì ti ṣe ìlérí láti mú un yín jáde kúrò nínú ìpọ́njú yín ni ilẹ̀ Ejibiti wá sí ilẹ̀ Kenaani, ará Hiti, Amori, Peresi, Hifi àti Jebusi; ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin.’

  6. “Àwọn àgbàgbà Israẹli yóò fetísílẹ̀ sí ohùn rẹ. Nígbà náà ni ìwọ, àti àwọn àgbàgbà yóò jọ tọ ọba Ejibiti lọ, ẹ ó sì wí fún un pé, ‘Olúwa, Ọlọ́run àwọn ará Heberu ti pàdé wa. Jẹ́ kí a lọ ni ìrìn ọjọ́ mẹ́ta sí inú aginjù láti lọ rú ẹbọ sí Olúwa Ọlọ́run.’

  7. Ṣùgbọ́n èmi mọ̀ pé ọba Ejibiti kò ní jẹ́ kí ẹ lọ bí kò ṣe pé ọwọ́ ńlá Ọlọ́run wà ni ara rẹ̀.

  8. Nítorí náà, èmi yóò na ọwọ́ mí láti lu àwọn ará Ejibiti pẹ̀lú gbogbo ohun ìyanu tí èmi yóò ṣe ni àárín wọn. Lẹ́yìn náà, òun yóò jẹ́ kí ẹ máa lọ.

  9. “Èmi yóò sì jẹ́ kí ẹ bá ojúrere àwọn ará Ejibiti pàdé. Tí yóò fi jẹ́ pé ti ẹ̀yin bá ń lọ, ẹ kò ní lọ ní ọwọ́ òfo.

  10. Mose dáhùn ó sì wí pé, “Ṣùgbọ́n bí wọn kò bá gbà mí gbọ́ ń kọ́? Tàbí tí wọn kò fi etí sílẹ̀ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu mi, tí wọn sì wí pé, ‘Olúwa kò farahàn ọ́’?”

  11. Ní ìgbà náà ni Olúwa sọ fún un pé, “Kí ni ó wà ní ọwọ́ rẹ n nì?” Ó sì dáhùn pé, “Ọ̀pá ni.”

  12. Olúwa sì sọ pé, “Sọ ọ̀pá náà sílẹ̀.” Mose sì sọ ọ̀pá náà sílẹ̀, lọ́gán ni ọ̀pá náà di ejò, ó sì sá fún un.

  13. Nígbà náà ni Olúwa wá sọ fún un pé, “Na ọwọ́ rẹ, kí o sì mú un ni ìrù.” Mose sì na ọwọ́ rẹ̀, ó sì mu ejò náà, ejò náà sì padà di ọ̀pá tí ó wà ni ọwọ́ rẹ̀.

  14. Olúwa sì wí pé, “Èyí rí bẹ́ẹ̀ kí wọn bá à le è gbàgbọ́ pé, Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wọn, Ọlọ́run Abrahamu, Ọlọ́run Isaaki, àti Ọlọ́run Jakọbu; tí farahàn ọ́.”

  15. Ní ìgbà náà ni Olúwa wí pé, “Ti ọwọ́ rẹ bọ inú aṣọ ní igbá àyà rẹ̀.” Mose sì ti ọwọ́ rẹ̀ bọ inú aṣọ ní igbá àyà rẹ̀, ní ìgbà ti ó sì yọ ọ́ jáde, ọwọ́ rẹ̀ ti dẹ́tẹ̀, ó sì ti funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú.

  16. Ó sì wí pé, “Nísinsin yìí, fi ọwọ́ náà padà sí abẹ́ aṣọ ní igbá àyà rẹ.” Mose sì ṣe bẹ́ẹ̀, ọwọ́ rẹ̀ sì padà bọ́ sípò bí àwọn ẹ̀yà ara rẹ̀ tókù.

  17. Mose sì sọ fún Olúwa pé, “Èmi jẹ́ akólòlò, èmi kì í ṣe ẹni tó lè sọ̀rọ̀ já gaara láti ìgbà àtijọ́ wá tàbí láti ìgbà ti o ti ń bá ìránṣẹ́ rẹ sọ̀rọ̀, mo jẹ́ ẹni ti ahọ́n rẹ̀ lọ́, tí ó sì ń lọ́ra àti sọ̀rọ̀.”

  18. Olúwa sì sọ fún un pé, “Ta ni ó fún ènìyàn ni ẹnu? Ta ni ó mú un ya odi tàbí adití? Ta ni ó mú un ríran, tàbí mú un fọ́jú? Ǹjẹ́ kì í ṣe èmi Olúwa?

  19. Lọ nísinsin yìí, Èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti sọ̀rọ̀. Èmi yóò sì kọ́ ọ ni ohun ti ìwọ yóò sọ.”

  20. Mose dáhùn ó wí pé, “Olúwa jọ̀wọ́ rán ẹlòmíràn láti lọ ṣe iṣẹ́ yìí.”

  21. Ìbínú Olúwa ru sókè sí Mose, ó sì sọ pé, “Aaroni ará Lefi arákùnrin rẹ ń kọ́? Mo mọ̀ pé ó lè sọ̀rọ̀ já gaara, ó ti wà ní ọ̀nà rẹ̀ báyìí láti pàdé e rẹ. Inú rẹ̀ yóò sì dùn ti ó bá rí ọ.

  22. Ìwọ yóò sọ̀rọ̀ fún un, ìwọ yóò sì fi ọ̀rọ̀ sí i lẹ́nu, èmi yóò ràn yín lọ́wọ́ láti sọ̀rọ̀. Èmi yóò kọ́ ọ yín ni ohun ti ẹ ó ṣe.

  23. Òun yóò bá ọ sọ̀rọ̀ sí àwọn ènìyàn, yóò sì dàbí i pé ẹnu un rẹ ni a gbà sọ ọ̀rọ̀ náà, ìwọ yóò sì dàbí Ọlọ́run ní iwájú rẹ̀.

  24. Nísinsin yìí, Olúwa ti sọ fún Mose ni ilẹ̀ Midiani pé, “Máa padà lọ sí Ejibiti, nítorí àwọn ti ó fẹ́ pa ọ ti kú.”

  25. Mose mú ìyàwó rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀, ó kó wọn lé orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò rẹ̀ padà sí Ejibiti. Ó sì mú ọ̀pá Ọlọ́run sí ọwọ́ rẹ̀.