- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
God
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God
Nígbà tí Esau sì ṣe àkíyèsí àwọn ìyàwó àti ọmọ Jakọbu, ó béèrè lọ́wọ́ Jakọbu pé, “Ti ta ni àwọn wọ̀nyí?” Jakọbu sì fèsì wí pé, “Èyí ni àwọn ọmọ tí Ọlọ́run nínú àánú rẹ̀ ti fi fún ìránṣẹ́ rẹ.”
Jakọbu bẹ̀ ẹ́ wí pé, “Rárá bẹ́ẹ̀ kọ́, bí ó bá ṣe pé, mo rí ojúrere rẹ, jọ̀wọ́ gba ọrẹ lọ́wọ́ mi. Bí mo ṣe rí ojú rẹ̀ yìí, ó dàbí wí pé mo rí ojú Ọlọ́run ni báyìí, tí inú rẹ̀ ti dùn sí mi.
Jọ̀wọ́ gba àwọn ohun tí mo mú wá wọ̀nyí lọ́wọ́ mi. Nítorí Ọlọ́run ti fi oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ hàn sí mi, gbogbo ohun tí mo fẹ́ sì ni mo ní.” Nígbà tí Jakọbu sì rọ̀ ọ́ pé Esau gbọdọ̀ gbà wọ́n, Esau sì gbà á.
Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún Jakọbu pé, “Gòkè lọ sí Beteli kí o sì tẹ̀dó síbẹ̀, kí ó mọ pẹpẹ níbẹ̀ fún Ọlọ́run tó farahàn ọ́ nígbà tí o ń sálọ kúrò níwájú Esau arákùnrin rẹ.”
Nígbà náà ni kí ẹ wá, kí ẹ jẹ́ kí a lọ sí Beteli, níbi tí n ó ti mọ pẹpẹ fún Ọlọ́run, tí ó dá mi lóhùn ní ọjọ́ ìpọ́njú mi tí ó sì ti ń pẹ̀lú mi níbi gbogbo tí mo ń lọ.”
Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò wọn. Ìbẹ̀rù Ọlọ́run sì ń bẹ lára gbogbo ìlú tí ó yí wọn ká, wọ́n kò sì lépa àwọn ọmọ Jakọbu.
Níbẹ̀ ni ó sì mọ pẹpẹ kan tí ó pè ní El-Beteli, nítorí níbẹ̀ ni Ọlọ́run ti gbé fi ara hàn án nígbà tí ó ń sálọ fún arákùnrin rẹ̀.
Lẹ́yìn tí Jakọbu padà dé láti Padani-Aramu, Ọlọ́run tún fi ara hàn án, ó sì súre fún un.
Ọlọ́run sì wí fun un pé, “Jakọbu ni orúkọ rẹ, a kì yóò pè ọ́ ní Jakọbu mọ́; bí kò ṣe Israẹli.” Nítorí náà, ó sọ orúkọ rẹ̀ ní Israẹli.
Ọlọ́run sì wí fún un pé, “Èmi ni Ọlọ́run alágbára, El-Ṣaddai; máa bí sí i, kí o sì máa pọ̀ sí i. Orílẹ̀-èdè àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè ni yóò ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá, àwọn ọba yóò sì jáde wá láti ara rẹ̀.
Nígbà náà ni Ọlọ́run gòkè lọ kúrò ní ibi tí ó ti ń bá a sọ̀rọ̀.
Jakọbu sì fi òkúta ṣe ọ̀wọ̀n kan sí ibi tí Ọlọ́run ti bá a sọ̀rọ̀, ó sì ta ọrẹ ohun mímu sí orí rẹ̀, ó sì da òróró olifi sí orí rẹ̀ pẹ̀lú.
Jakọbu sì pe orúkọ ibi tí Ọlọ́run ti bá a sọ̀rọ̀ ní Beteli.
Ṣùgbọ́n Eri àkọ́bí Juda ṣe ènìyàn búburú níwájú Olúwa, Ọlọ́run sì pa á.
Ohun tí ó ń ṣe yìí burú lójú Olúwa, ó sì pa òun náà pẹ̀lú.
Olúwa sì wà pẹ̀lú Josẹfu, ó sì bùkún un, ó sì ń gbé ní ilé ọ̀gá rẹ̀ ará Ejibiti.
Nígbà tí ọ̀gá rẹ̀ rí i pé Olúwa wà pẹ̀lú rẹ̀, àti pé Olúwa jẹ́ kí ó máa ṣe àṣeyọrí nínú ohun gbogbo tí ó dáwọ́ rẹ̀ lé.
Láti ìgbà tí ó ti fi Josẹfu jẹ olórí ilé rẹ̀ àti ohun ìní rẹ̀ gbogbo, ni Ọlọ́run ti bẹ̀rẹ̀ sí ní bùkún àwọn ará Ejibiti nítorí Josẹfu. Ìbùkún Olúwa wà lórí gbogbo ohun tí Potifari ní, nílé àti lóko.
Kò sí ẹni tí ó jù mi lọ nínú ilé yìí, ọ̀gá mi kò fi ohunkóhun dù mi àyàfi ìwọ, tí í ṣe aya rẹ̀. Báwo ni mo ṣe lè ṣe ohun búburú yìí, kí ń sì ṣẹ̀ sí Ọlọ́run?”
Olúwa sì wà pẹ̀lú rẹ̀, ó sì ṣàánú fún un, ó sì mú kí ó rí ojúrere àwọn alábojútó ọgbà ẹ̀wọ̀n.
Wọ́dà náà kò sì mikàn nípa gbogbo ohun tí ó fi sí abẹ́ àkóso Josẹfu, nítorí pé Olúwa wà pẹ̀lú Josẹfu, ó sì ń jẹ́ kí ó ṣe àṣeyọrí nínú ohun gbogbo tí ó dáwọ́lé.
Wọ́n wí pé, “Àwa méjèèjì ni a lá àlá, kò sì sí ẹni tí yóò túmọ̀ rẹ̀.” Josẹfu sì wí fún wọn pé, “Ọlọ́run nìkan ni ó ni ìtumọ̀. Ẹ sọ àwọn àlá yín fún mi.”
Josẹfu dá Farao ní ohùn pé, “Kì í ṣe agbára mi, ṣùgbọ́n, Ọlọ́run ni yóò fi ìdáhùn àlàáfíà fún Farao ní ìtumọ̀ àlá náà.”
Nígbà náà ni Josẹfu wí fún Farao, “Ìtumọ̀ kan náà ni àwọn àlá méjèèjì ní. Ọlọ́run fi ohun tí ó fẹ́ ṣe hàn fún Farao.
“Bí mo ti wí fún Farao ní ìṣáájú náà ni: Ọlọ́run fi ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ han Farao.