Fò sí àkóónú

David

968 ẹsẹ · 40 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan David

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Olúwa, níbo ni ìṣeun ìfẹ́ rẹ àtijọ́ wà, tí ìwọ ti fi òtítọ́ rẹ búra fún Dafidi?

  2. Ti Dafidi. Saamu. Èmi yóò kọrin ìfẹ́ àti òdodo; sí ọ Olúwa, èmi yóò máa kọrin ìyìn.

  3. Ti Dafidi. Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi; àti gbogbo ohun tí ó wà nínú mi, yín orúkọ rẹ̀ mímọ́.

  4. Orin. Saamu ti Dafidi. Ọlọ́run, ọkàn mi dúró ṣinṣin èmi ó máa kọrin, èmi ó máa fi ọkàn mi kọrin.

  5. Fún adarí orin. Ti Dafidi. Saamu. Ọlọ́run, ti èmi ń fi ìyìn fún, má ṣe dákẹ́,

  6. Ti Dafidi. Saamu. Olúwa sọ fún Olúwa mi pé, “Ìwọ jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi, títí èmi yóò fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.”

  7. Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi. Inú mi dùn nígbà tí wọ́n wí fún mi pé, “Ẹ jẹ́ kí á lọ sílé Olúwa.”

  8. Nítorí ibẹ̀ ni a gbé ìtẹ́ ìdájọ́ kalẹ̀, àwọn ìtẹ́ ilé Dafidi.

  9. Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi. “Ìbá má ṣe pé Olúwa tí ó ti wà fún wa,” kí ni Israẹli kí ó máa wí nísinsin yìí;

  10. Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi. Olúwa àyà mi kò gbéga, bẹ́ẹ̀ ni ojú mi kò gbé sókè: bẹ́ẹ̀ ni èmi kò fi ọwọ́ mi lé ọ̀ràn ńlá, tàbí lé ohun tí ó ga jù mí lọ.

  11. Orin fún ìgòkè. Olúwa, rántí Dafidi nínú gbogbo ìpọ́njú rẹ̀.

  12. Nítorí tí Dafidi ìránṣẹ́ rẹ̀, má ṣe yí ojú ẹni òróró rẹ padà.

  13. Olúwa ti búra nítòótọ́ fún Dafidi, Òun kì yóò yípadà kúrò nínú rẹ̀, nínú irú-ọmọ inú rẹ ni èmi ó gbé kalẹ̀ sí orí ìtẹ́ rẹ.

  14. Níbẹ̀ ni èmi yóò gbé mú ìwo Dafidi yọ̀, èmi ti ṣe ìlànà fìtílà kan fún ẹni òróró mi.

  15. Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi. Kíyèsi, ó ti dára ó sì ti dùn tó fún àwọn ará láti máa jùmọ̀ gbé ní ìrẹ́pọ̀.

  16. Ti Dafidi. Èmi yóò yìn ọ́ tinútinú mi gbogbo; níwájú àwọn òrìṣà ni èmi ó kọrin ìyìn sí ọ.

  17. Fún adarí orin. Ti Dafidi. Saamu. Olúwa, ìwọ tí wádìí mi, ìwọ sì ti mọ̀ mí.

  18. Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi. Olúwa, gbà mi lọ́wọ́ ọkùnrin búburú u nì, yọ mí lọ́wọ́ ọkùnrin ìkà a nì,

  19. Saamu ti Dafidi. Olúwa, èmi ké pè ọ́; yára wá sí ọ̀dọ̀ mi. Gbọ́ ohùn mi, nígbà tí mo bá ń ké pè ọ́.

  20. Maskili ti Dafidi. Nígbà tí ó wà nínú ihò òkúta. Àdúrà. Èmi kígbe sókè sí Olúwa; èmi gbé ohùn mi sókè sí Olúwa fún àánú.

  21. Saamu ti Dafidi. Olúwa gbọ́ àdúrà mi, fetísí igbe mi fún àánú; nínú òtítọ́ àti òdodo rẹ, wá fún ìrànlọ́wọ́ mi.

  22. Ti Dafidi. Ìyìn sí Olúwa àpáta mi, ẹni tí ó kọ́ ọwọ́ mi fún ogun, àti ìka mi fún ìjà.

  23. Òun ni ó fi ìgbàlà fún àwọn ọba, ẹni tí ó gba Dafidi ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ idà ìpanilára. Lọ́wọ́ pípanirun.

  24. Saamu ìyìn. Ti Dafidi. Èmi yóò gbé ọ ga, Ọlọ́run ọba mi; èmi yóò yin orúkọ rẹ̀ láé àti láéláé.

  25. Àwọn òwe ti Solomoni, ọmọ Dafidi, ọba Israẹli.