Fò sí àkóónú

David

968 ẹsẹ · 40 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan David

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Miktamu ti Dafidi. Pa mí mọ́, Ọlọ́run, nítorí nínú rẹ ni ààbò mi wà.

  2. Àdúrà ti Dafidi. Gbọ́, Olúwa, ẹ̀bẹ̀ òtítọ́ mi; fi etí sí igbe mi. Tẹ́tí sí àdúrà mi tí kò ti ètè ẹ̀tàn jáde.

  3. Fún adarí orin. Ti Dafidi ìránṣẹ́ Olúwa tí ó kọ sí Olúwa, ọ̀rọ̀ orin tí ó kọ sí Olúwa fún ìdáǹdè kúrò lọ́wọ́ Saulu ọ̀tá rẹ̀. Ó wí pé. Mo fẹ́ ọ, Olúwa, agbára mi.

  4. Ó fún ọba rẹ̀ ni ìṣẹ́gun ńlá; ó fi ìkáàánú àìṣẹ̀tàn fún ẹni àmì òróró rẹ̀, fún Dafidi àti ìran rẹ̀ títí láé.

  5. Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi. Àwọn ọ̀run ń sọ nípa ti ògo Ọlọ́run; àwọsánmọ̀ ń sọ nípa ti iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.

  6. Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi. Kí Olúwa kí ó gbóhùn rẹ ní ọjọ́ ìpọ́njú; kí orúkọ Ọlọ́run Jakọbu kí ó dáàbò bò ọ́.

  7. Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi. Háà! Olúwa, ọba yóò yọ̀ nínú agbára rẹ, àti ní ìgbàlà rẹ, yóò ti yọ̀ pẹ́ tó!

  8. Fún adarí orin. Tí ohùn orin “àgbọ̀nrín òwúrọ̀.” Saamu ti Dafidi. Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí sílẹ̀? Èéṣe tí o fi jìnnà láti gbà mí là, àní sí igbe ìkérora mi?

  9. Saamu ti Dafidi. Olúwa ni olùṣọ́ èmi àgùntàn rẹ̀, èmi kì yóò ṣe aláìní.

  10. Ti Dafidi. Saamu. Ti Olúwa ni ilẹ̀, àti ẹ̀kún rẹ̀, ayé àti àwọn tí ó tẹ̀dó sínú rẹ̀;

  11. Ti Dafidi. Olúwa, ìwọ ni mo gbé ọkàn mi sókè sí.

  12. Ti Dafidi. Ṣe ìdájọ́ mi, Olúwa, nítorí tí mo ti ń rìn nínú ìwà òtítọ́ ọ̀ mi, mo sì ti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa, ǹjẹ́ ẹsẹ̀ mi kì yóò yẹ̀.

  13. Ti Dafidi. Olúwa ni ìmọ́lẹ̀ mi àti ìgbàlà mi; ta ni èmi yóò bẹ̀rù? Olúwa ni ibi ìsádi ẹ̀mí mi, ẹ̀rù ta ni yóò bà mí?

  14. Ti Dafidi. Ìwọ Olúwa, mo ké pe àpáta mi. Má ṣe kọ etí dídi sí mi. Tí ìwọ bá dákẹ́ sí mi, èmí yóò dàbí àwọn tí ó lọ sí ọ̀gbun.

  15. Saamu ti Dafidi. Ẹ fi fún Olúwa, ẹ̀yin ẹ̀dá ọ̀run, ẹ fi fún Olúwa, ògo àti alágbára.

  16. Saamu. Orin. Fún ìyàsímímọ́ Tẹmpili. Ti Dafidi. Èmi yóò kókìkí i rẹ, Olúwa, nítorí ìwọ ni ó gbé mi lékè tí ìwọ kò sì jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi kí ó yọ̀ mí.

  17. Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi. Nínú rẹ̀, Olúwa ni mo ti rí ààbò; má ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí; gbà mí nínú òdodo rẹ.

  18. Ti Dafidi. Maskili. Ìbùkún ni fún àwọn tí a dárí ìrékọjá wọn jì, tí a sì bo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀.

  19. Tí Dafidi. Nígbà tí ó díbọ́n bí ẹni tí ń ṣe wèrè níwájú Abimeleki, ẹni tí ó lé e lọ, ó sì jáde lọ. Èmi yóò máa fi ìbùkún fún Olúwa nígbà gbogbo; ìyìn rẹ̀ yóò máa wà ní ẹnu mi títí láé.

  20. Ti Dafidi. Olúwa, gbógun ti àwọn tí ń gbóguntì mí; kí o sì kọ ojú ìjà sí àwọn tí ó ń bá mi í jà!

  21. Fún adarí orin. Ti Dafidi ìránṣẹ́ Olúwa. Ìré-òfin-kọjá ènìyàn búburú jẹ́ kí n mọ̀ nínú ọkàn mi pé, ìbẹ̀rù Ọlọ́run kò sí níwájú wọn.

  22. Ti Dafidi. Má ṣe ìkanra nítorí àwọn olùṣe búburú, kí ìwọ má sì ṣe ṣe ìlara nítorí àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀;

  23. Saamu Dafidi. Ẹ̀bẹ̀. Olúwa, má ṣe bá mi wí nínú ìbínú rẹ, bẹ́ẹ̀ ni kí o má ṣe fi ìyà jẹ mí nínú ìrunú rẹ̀.

  24. Fún adarí orin. Fún Jedutuni. Saamu Dafidi. Mo wí pé, “Èmi yóò ṣọ́ ọ̀nà mi kí èmi kí ó má fi ahọ́n mi ṣẹ̀; èmi yóò fi ìjánu kó ara mi ní ẹnu níwọ̀n ìgbà tí ènìyàn búburú bá ń bẹ ní iwájú mi.”

  25. Fún adarí orin. Ti Dafidi. Saamu. Mo fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ dúró de Olúwa; ó sì dẹtí sí mi, ó sì gbọ́ ẹkún mi.