Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Widows

90 ẹsẹ · 56 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Dúró síbí títí ilẹ̀ yóò fi mọ́, bí ó bá sì di òwúrọ̀ tí ọkùnrin náà sì ṣe tan láti ṣe ìràpadà, ó dára kí ó ṣe bẹ́ẹ̀, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, bí Olúwa ti ń bẹ láààyè nígbà náà ni èmi yóò ṣe ìràpadà, sùn sí ìhín títí ilẹ̀ yóò fi mọ́.”

  2. Mó sì rò wí pé ó yẹ kí n mú ọ̀rọ̀ náà wá sí etí ìgbọ́ rẹ, wí pé kí o rà á ní iwájú gbogbo àwọn tí ó jókòó sí ibi yìí. Bí ìwọ yóò bá rà á padà rà á. Ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá ní rà á padà, sọ fún mi, kí èmi ó le è mọ̀. Nítorí pé kò sí ẹlòmíràn tí ó ní ẹ̀tọ́ láti rà á ju ìwọ lọ, èmi sì ni ẹni tí ó tún kàn lẹ́yìn rẹ̀.” Ọkùnrin náà sì sọ wí pé, “Èmi yóò rà á padà.”

  3. Nígbà náà ni Boasi sọ wí pé, “Bí ìwọ bá ti ra ilẹ̀ náà lọ́wọ́ Naomi àti lọ́wọ́ Rutu ará Moabu, ìwọ gbọdọ̀ fẹ́ opó ọkùnrin náà, kí orúkọ ọkùnrin tí ó kú náà má ba à parẹ́ pẹ̀lú ohun ìní rẹ̀ àti kí o le è bímọ ní orúkọ rẹ̀.”

  4. Joabu sì ránṣẹ́ sí Tekoa, ó sì mú ọlọ́gbọ́n obìnrin kan láti ibẹ̀ wá, ó sì wí fún un pé, “Èmi bẹ̀ ọ́, ṣe bí ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀, kí o sì fi aṣọ ọ̀fọ̀ sára, kí o má sì ṣe fi òróró pa ara, kí o sì dàbí obìnrin ti ó ti ń ṣọ̀fọ̀ fún òkú lọ́jọ́ púpọ̀.

  5. Ọba sì bi í léèrè pé, “Kín ni o ṣe ọ́?” Òun sì dáhùn wí pé, “Nítòótọ́ opó ni èmi ń ṣe, ọkọ mi sì kú.

  6. Nígbà náà ni ó wí pé, “Jẹ́ kí a fi Abiṣagi ará Ṣunemu fún Adonijah arákùnrin rẹ ní aya.”

  7. Solomoni ọba sì dá ìyá rẹ̀ lóhùn pé, “Èéṣe tí ìwọ fi béèrè Abiṣagi ará Ṣunemu fún Adonijah! Ìwọ ìbá sì béèrè ìjọba fún un pẹ̀lú nítorí ẹ̀gbọ́n mi ní í ṣe, fún òun pàápàá àti fún Abiatari àlùfáà àti fun Joabu ọmọ Seruiah!”

  8. Nígbà náà ni Solomoni ọba fi Olúwa búra pé, “Kí Ọlọ́run ki ó jẹ mí ní yà, àti jù bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú, bí Adonijah kò bá ní fi ẹ̀mí rẹ̀ san ìbéèrè yìí!

  9. Àti nísinsin yìí, bí ó ti dájú pé Olúwa wà láààyè, ẹni tí ó ti mú mi jókòó lórí ìtẹ́ baba mi Dafidi, àti tí ó sì ti kọ́ ilé fún mi bí ó ti ṣèlérí, lónìí ni a ó pa Adonijah!”

  10. “Lọ nísinsin yìí sí Sarefati ti Sidoni, kí o sì dúró síbẹ̀. Èmi ti pàṣẹ fún obìnrin opó kan níbẹ̀ láti máa bọ́ ọ.”

  11. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì lọ sí Sarefati. Nígbà tí ó sì dé ibodè ìlú náà, obìnrin opó kan ń ṣa igi jọ níbẹ̀. Ó sì ké sí i, ó sì béèrè pé, “Ǹjẹ́ o lè bu omi díẹ̀ fún mi wá nínú ohun èlò kí èmi kí ó lè mu?”

  12. Bí ó sì ti ń lọ bù ú wá, ó ké sí i pé, “Jọ̀ ọ́, mú òkèlè oúnjẹ díẹ̀ fún mi wá lọ́wọ́ rẹ.”

  13. Obìnrin opó náà sì dá a lóhùn wí pé, “Bí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti wà, èmi kò ní àkàrà, bí kò ṣe ìkúnwọ́ ìyẹ̀fun nínú ìkòkò àti òróró díẹ̀ nínú kólòbó. Èmi ń ṣa igi díẹ̀ jọ láti kó lọ ilé, kí èmi kí ó sì pèsè rẹ̀ fún mi àti fún ọmọ mi, kí àwa lè jẹ ẹ́: kí a sì kú.”

  14. Elijah sì wí fún un pé, “Má ṣe bẹ̀rù. Lọ, kí o sì ṣe gẹ́gẹ́ bí o ti wí. Ṣùgbọ́n kọ́kọ́ ṣe àkàrà kékeré kan fún mi nínú rẹ̀ ná, kí o sì mú fún mi wá, lẹ́yìn náà, kí o ṣe tìrẹ àti ti ọmọ rẹ.

  15. Nítorí báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí: ‘Ìkòkò ìyẹ̀fun náà kì yóò ṣófo, bẹ́ẹ̀ ni kólòbó òróró náà kì yóò gbẹ, títí di ọjọ́ tí Olúwa yóò rọ òjò sí orí ilẹ̀.’ ”

  16. Ó sì lọ, ó sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Elijah ti sọ fún un. Oúnjẹ sì wà fún Elijah àti obìnrin náà àti ilé rẹ̀ ní ojoojúmọ́.

  17. Ìwọ ti rán àwọn opó padà lọ ní ọwọ́ òfo, apá àwọn ọmọ aláìní baba ti di ṣiṣẹ́.

  18. Wọ́n á sì da kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ aláìní baba lọ, wọ́n a sì gba ọ̀dá màlúù opó ní ohun ògo.

  19. Ẹni tí o hù ìwà búburú sí àgàn tí kò ṣe rere sí opó.

  20. Àwọn tí ó kù nínú tirẹ̀ ni a ó sìnkú nínú àjàkálẹ̀-ààrùn: àwọn opó rẹ̀ kì yóò sì sọkún fún wọn.

  21. Ẹni tí ó ń kìlọ̀ súre fún mi, èmi sì mú àyà opó kọrin fún ayọ̀.

  22. “Bí mo bá fa ọwọ́ sẹ́yìn fún ìfẹ́ inú tálákà, tàbí bí mo bá sì mú kí ojú opó rẹ̀wẹ̀sì,

  23. Baba àwọn aláìní baba àti onídàájọ́ àwọn opó ni Ọlọ́run ní ibùgbé rẹ̀ mímọ́

  24. àfi àlùfáà wọn fún idà, àwọn opó wọn kò sì le è sọkún.

  25. Wọ́n pa àwọn opó àti àlejò, wọ́n sì pa àwọn ọmọ aláìní baba.