Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Titles and Names of Christ

138 ẹsẹ · 117 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. “Àti sí angẹli ìjọ ní Laodikea kọ̀wé. Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni ẹni tí ń jẹ́ Àmín wí, ẹlẹ́rìí olódodo àti olóòtítọ́, olórí ìṣẹ̀dá Ọlọ́run.

  2. Ọ̀kan nínú àwọn àgbà náà sì wí fún mi pé, “Má ṣe sọkún: kíyèsi i, kìnnìún ẹ̀yà Juda, Gbòǹgbò Dafidi, tí borí láti ṣí ìwé náà, àti láti tú èdìdì rẹ̀ méjèèje.”

  3. Mo sì rí Ọ̀dọ́-Àgùntàn ni àárín ìtẹ́ náà, àti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà, àti ni àárín àwọn àgbà náà, Ọ̀dọ́-àgùntàn kan dúró bí èyí tí a ti pa, ó ní ìwo méje àti ojú méje, tí o jẹ́ Ẹ̀mí méje tí Ọlọ́run, tí a rán jáde lọ sì orí ilẹ̀ ayé gbogbo.

  4. Wọn ń wí lóhùn rara pé: “Yíyẹ ni Ọ̀dọ́-àgùntàn náà tí a tí pa, láti gba agbára, àti ọ̀rọ̀ àti ọgbọ́n, àti ipá, àti ọlá, àti ògo, àti ìbùkún.”

  5. Gbogbo àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé yóò sì máa sìn ín, olúkúlùkù ẹni tí a kò kọ orúkọ rẹ̀, sínú ìwé ìyè Ọ̀dọ́-Àgùntàn tí a tí pa láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé.

  6. Wọ́n sì ń kọ orin ti Mose, ìránṣẹ́ Ọlọ́run, àti orin ti Ọ̀dọ́-Àgùntàn, wí pé: “Títóbi àti ìyanu ni àwọn iṣẹ́ rẹ, Olúwa Ọlọ́run Olódùmarè; òdodo àti òtítọ́ ni ọ̀nà rẹ̀, ìwọ ọba àwọn orílẹ̀-èdè.

  7. Àwọn wọ̀nyí ni yóò si máa bá Ọ̀dọ́-Àgùntàn jagun, Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà yóò sì ṣẹ́gun wọn: nítorí òun ni Olúwa àwọn Olúwa, àti ọba àwọn ọba: àwọn tí ó sì wà pẹ̀lú rẹ̀, tí a pè, tí a yàn, tí wọ́n sì jẹ́ olóòtítọ́ yóò sì ṣẹ́gun pẹ̀lú.”

  8. A sì wọ̀ ọ́ ní aṣọ tí a tẹ̀ bọ inú ẹ̀jẹ̀, a sì ń pe orúkọ rẹ̀ ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

  9. Èmi kò sì ri tẹmpili nínú rẹ̀, nítorí pé Olúwa Ọlọ́run Olódùmarè ni tẹmpili rẹ̀, àti Ọ̀dọ́-àgùntàn.

  10. Ègún kì yóò sì ṣí mọ: ìtẹ́ Ọlọ́run àti tí Ọ̀dọ́-àgùntàn ni yóò sì máa wà níbẹ̀; àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò sì máa sìn ín.

  11. Ó sì wí fún mi pé, “Òdodo àti òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: Olúwa Ọlọ́run ẹ̀mí àwọn wòlíì ni ó sì ran angẹli rẹ̀ láti fi ohun tí ó ní láti ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ yìí hàn àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.”

  12. Èmi ni Alfa àti Omega, ẹni ìṣáájú àti ẹni ìkẹyìn, ìpilẹ̀ṣẹ̀ àti òpin.

  13. “Èmi, Jesu, ni ó rán angẹli mi láti jẹ́rìí nǹkan wọ̀nyí fún yin ní tí àwọn ìjọ. Èmi ni gbòǹgbò àti irú-ọmọ Dafidi, àti ìràwọ̀ òwúrọ̀ tí ń tàn.”