Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Reward of Saints

85 ẹsẹ · 51 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ìwọ ti fi ipa ọ̀nà ìyè hàn mí; Ìwọ yóò kún mi pẹ̀lú ayọ̀ ní iwájú rẹ, pẹ̀lú ìdùnnú ayérayé ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ.

  2. Ṣùgbọ́n ní tèmi, èmi yóò máa wo ojú rẹ ní òdodo; nígbà tí èmi bá jí, èmi yóò ní ìtẹ́lọ́rùn nígbà tí èmi bá rí àwòrán rẹ.

  3. Ìwọ fi ìmọ̀ràn rẹ tọ́ mi ní ìkẹyìn ìwọ ó mú mi lọ sí inú ògo.

  4. Ènìyàn búburú gba èrè ìtànjẹ ṣùgbọ́n ẹni tó fúnrúgbìn òdodo yóò gba èrè tó dájú.

  5. Òun yóò sì gbé ikú mì títí láé. Olúwa Olódùmarè yóò sì nu gbogbo omijé nù, kúrò ní ojú gbogbo wọn, Òun yóò sì mú ẹ̀gàn àwọn ènìyàn rẹ̀ kúrò ní gbogbo ilẹ̀ ayé. Olúwa ni ó ti sọ ọ́.

  6. Ní ọjọ́ náà wọn yóò sọ pé, “Nítòótọ́ eléyìí ni Ọlọ́run wa; àwa ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ̀, òun sì gbà wá là. Èyí ni Olúwa, àwa gbẹ́kẹ̀lé e, ẹ jẹ́ kí a yọ̀ kí inú wa sì dùn nínú ìgbàlà rẹ̀.”

  7. Òòrùn kì yóò sì jẹ́ ìmọ́lẹ̀ rẹ ní ọ̀sán mọ́, tàbí kí ìtànṣán òṣùpá tún ràn sí ọ mọ́, nítorí Olúwa ni yóò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ rẹ ayérayé, àti Ọlọ́run rẹ yóò jẹ́ ògo rẹ.

  8. Láti ìgbà àtijọ́ kò sí ẹni tí ó gbọ́ rí kò sí etí kan tí ó gbọ́ ọ, kò sí ojú tí ó tí ì rí Ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn rẹ, tí ó máa ń ṣe nǹkan lórúkọ àwọn tí ó dúró dè é.

  9. títí ẹni ìgbàanì fi dé, ó sì ṣe ìdájọ́ ìdáláre fún àwọn ẹni mímọ́ Ọ̀gá-ògo, àsìkò náà sì dé nígbà tí àwọn ẹni mímọ́ náà jogún ìjọba.

  10. Àwọn tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n yóò máa tàn bí ìmọ́lẹ̀ ọ̀run, àti àwọn tí ó ń tọ́nisọ́nà sí òdodo, yóò máa tàn bí ìràwọ̀ láé àti láéláé.

  11. Alábùkún fún ni àwọn ọlọ́kàn mímọ́, nítorí wọn yóò rí Ọlọ́run.

  12. Ẹ yọ̀, kí ẹ̀yin sì fò fún ayọ̀, nítorí ńlá ni èrè yín ní ọ̀run, nítorí bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ṣe inúnibíni sí àwọn wòlíì tí ń bẹ ṣáájú yín.

  13. Nítorí Ọmọ Ènìyàn yóò wá nínú ògo baba rẹ pẹ̀lú àwọn angẹli rẹ̀, nígbà náà ni yóò sì san án fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀.

  14. Jesu wí fún un pé, “Bí ìwọ bá fẹ́ di ẹni pípé, lọ ta ohun gbogbo tí ìwọ ní, kí o sì fi owó rẹ̀ tọrẹ fún àwọn aláìní. Ìwọ yóò ní ọrọ̀ ńlá ní ọ̀run. Lẹ́yìn náà, wá láti máa tọ̀ mi lẹ́yìn.”

  15. Jesu dáhùn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé, ‘Nígbà ìsọdọ̀tun ohun gbogbo, nígbà tí Ọmọ Ènìyàn yóò jókòó lórí ìtẹ́ tí ó lógo, dájúdájú, ẹ̀yin ọmọ-ẹ̀yìn mi yóò sì jókòó lórí ìtẹ́ méjìlá láti ṣe ìdájọ́ ẹ̀yà Israẹli méjìlá.

  16. Ó ní, gba èyí tí í ṣé tìrẹ, ki ó sì máa lọ. Èmi fẹ́ láti fún ẹni ìkẹyìn gẹ́gẹ́ bí mo ti fi fún ọ.

  17. Àbí ó lòdì sí òfin pé kí èmi fún ẹnikẹ́ni ní owó mi bí mo bá yàn láti ṣe bẹ́ẹ̀? Kí ni ìdí tí ìwọ ní láti bínú nítorí èmi ṣe ohun rere?’

  18. “Olúwa rẹ̀ wí fún un pé, ‘O ṣeun ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ rere àti olóòtítọ́: ìwọ ṣe olóòtítọ́ nínú ohun díẹ̀, èmi yóò fi ọ́ ṣe olórí ohun púpọ̀, bọ́ sínú ayọ̀ olúwa rẹ.’

  19. “Nígbà náà ni ọba yóò wí fún àwọn tí ó wà lọ́wọ́ ọ̀tún pé, ‘Ẹ wá, ẹ̀yin tí Baba mi ti bùkún fún, ẹ jogún ìjọba tí a ti pèsè fún yín láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé.

  20. Ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin fẹ́ àwọn ọ̀tá yín kí ẹ sì ṣoore, kí ẹ̀yin sì yá ẹlòmíràn, kí ẹ̀yin má ṣe retí láti rí nǹkan gbà padà; èrè yín yóò sì pọ̀, àwọn ọmọ Ọ̀gá-ògo ni a ó sì máa pè yín: nítorí tí ó ṣe rere fún aláìmoore àti fún ẹni búburú.

  21. “Má bẹ̀rù, agbo kékeré, nítorí dídùn inú Baba yín ni láti fi ìjọba fún yín.

  22. Ẹ ta ohun tí ẹ̀yin ní, kí ẹ sì tọrẹ àánú kí ẹ sì pèsè àpò fún ara yín, tí kì í gbó, ìṣúra ní ọ̀run tí kì í tán, ní ibi tí olè kò lè súnmọ́, àti ibi tí kòkòrò kì í bà á jẹ́.

  23. tí kì yóò gba ìlọ́po púpọ̀ sí i ní ayé yìí, àti ní ayé tí ń bọ̀ ìyè àìnípẹ̀kun.”

  24. Mo sì yan ìjọba fún yín, gẹ́gẹ́ bí Baba mi ti yàn fún mi.

  25. Kí ẹ̀yin lè máa jẹ, kí ẹ̀yin sì lè máa mu lórí tábìlì mi ní ìjọba mi, kí ẹ̀yin lè jókòó lórí ìtẹ́, àti kí ẹ̀yin lè máa ṣe ìdájọ́ fún àwọn ẹ̀yà Israẹli méjìlá.”