Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Reward of Saints: Saints may feel confident of

5 ẹsẹ · 51 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Saints may feel confident of

  1. Ìwọ fi ìmọ̀ràn rẹ tọ́ mi ní ìkẹyìn ìwọ ó mú mi lọ sí inú ògo.

  2. Òun yóò sì gbé ikú mì títí láé. Olúwa Olódùmarè yóò sì nu gbogbo omijé nù, kúrò ní ojú gbogbo wọn, Òun yóò sì mú ẹ̀gàn àwọn ènìyàn rẹ̀ kúrò ní gbogbo ilẹ̀ ayé. Olúwa ni ó ti sọ ọ́.

  3. Ní ọjọ́ náà wọn yóò sọ pé, “Nítòótọ́ eléyìí ni Ọlọ́run wa; àwa ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ̀, òun sì gbà wá là. Èyí ni Olúwa, àwa gbẹ́kẹ̀lé e, ẹ jẹ́ kí a yọ̀ kí inú wa sì dùn nínú ìgbàlà rẹ̀.”

  4. Nítorí àwa mọ̀ pé, bi ilé àgọ́ wa ti ayé ba wó, àwa ní ilé kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ilé tí a kò fi ọwọ́ kọ́, ti ayérayé nínú àwọn ọ̀run.

  5. Láti ìsinsin yìí lọ a fi adé òdodo lélẹ̀ fún mi, tí Olúwa onídàájọ́ òdodo, yóò fífún mi ni ọjọ́ náà kì í sì í ṣe kìkì èmi nìkan ṣùgbọ́n pẹ̀lú fún gbogbo àwọn tí ó ti fẹ́ ìfarahàn rẹ̀.