Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Thanksgiving

93 ẹsẹ · 57 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Saamu. Orin. Fún Ọjọ́ Ìsinmi. Ohun rere ni láti máa fi ọpẹ́ fún Olúwa àti láti máa kọrin sí orúkọ rẹ̀, Ọ̀gá-ògo,

  2. Ẹ jẹ́ kí a wá sí iwájú rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́ kí a sì pòkìkí rẹ̀ pẹ̀lú ohun èlò orin àti ìyìn.

  3. Ẹ yọ̀ nínú Olúwa, ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ olódodo, kí ẹ sì yin orúkọ rẹ̀ mímọ́.

  4. Ẹ lọ sí ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́ àti sí àgbàlá rẹ̀ pẹ̀lú ìyìn; ẹ fi ọpẹ́ àti ìyìn fún orúkọ rẹ̀.

  5. Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, ké pe orúkọ rẹ̀, jẹ́ kí a mọ ohun tí ó ṣe láàrín àwọn orílẹ̀-èdè.

  6. Yin Olúwa! Ẹ fi ìyìn fún Olúwa, nítorí tí ó ṣeun. Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí tí ó ṣeun, nítorí tí ìfẹ́ rẹ̀ dúró láéláé.

  7. Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó ṣeun; nítorí ìfẹ́ rẹ̀ dúró láéláé.

  8. Èmi yóò rú ẹbọ ọpẹ́ sí ọ èmi yóò sì ké pe orúkọ Olúwa.

  9. Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí tí ó ṣeun; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

  10. Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run àwọn ọlọ́run: nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

  11. Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa àwọn olúwa, nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

  12. Mo dúpẹ́, mo sì fi ìyìn fún ọ, ìwọ Ọlọ́run àwọn baba mi: ó ti fún mi ní ọgbọ́n àti agbára ó ti fi àwọn nǹkan tí a béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ hàn fún mi nítorí tí ìwọ ti fi àlá ọba hàn wá.”

  13. Lóòótọ́, Daniẹli mọ̀ pé a ti fi ọwọ́ sí ìwé òfin náà, síbẹ̀ ó wọ ilé e rẹ̀ lọ, nínú yàrá òkè, ó ṣí fèrèsé èyí tí ó kọjú sí Jerusalẹmu sílẹ̀. Ó kúnlẹ̀ lórí orúnkún un rẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀mẹ́ta lójoojúmọ́, ó gbàdúrà, ó fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀ tẹ́lẹ̀.

  14. Ṣùgbọ́n èmi yóò fi orin ọpẹ́, rú ẹbọ sí ọ. Èmi yóò san ẹ̀jẹ́ tí mo ti jẹ́. ‘Ìgbàlà wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa.’ ”

  15. Nígbà náà ni Jesu wí pé, “Mo yìn ọ Baba, Olúwa ọ̀run àti ayé, nítorí ìwọ ti fi òtítọ́ yìí pamọ́ fún àwọn tó jẹ́ ọlọ́gbọ́n àti amòye, Ìwọ sì ti fi wọ́n hàn fún àwọn ọmọ wẹ́wẹ́.

  16. Bákan náà, ó sì mú ago wáìnì, ó dúpẹ́ fún un, ó sì gbé e fún wọn. Ó wí pé, “Kí gbogbo yín mu nínú rẹ̀.

  17. Nígbà náà ni Simeoni gbé e ní apá rẹ̀, ó fi ìbùkún fún Ọlọ́run, ó ní:

  18. Ó sì wólẹ̀ ní àkókò náà, ó sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run pẹ̀lú, ó sì sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún gbogbo àwọn tí ó ń retí ìdáǹdè Jerusalẹmu.

  19. Èyí Farisi dìde, ó sì ń gbàdúrà nínú ara rẹ̀ báyìí pé, ‘Ọlọ́run mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, nítorí tí èmi kò rí bí àwọn ará ìyókù, àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà, aláìṣòótọ́, panṣágà, tàbí bí agbowó òde yìí.

  20. Jesu sì mú ìṣù àkàrà náà. Nígbà tí ó sì ti dúpẹ́, ó pín wọn fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì pín wọn fún àwọn tí ó jókòó; bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sì ni ẹja ní ìwọ̀n bí wọ́n ti ń fẹ́.

  21. Nígbà náà ni wọ́n gbé òkúta náà kúrò (níbi tí a tẹ́ ẹ sí). Jesu sì gbé ojú rẹ̀ sókè, ó sì wí pé, “Baba, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ nítorí tí ìwọ gbọ́ tèmi.

  22. Nígbà tí ó sì wí nǹkan wọ̀nyí, tí ó sì mú àkàrà, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run níwájú gbogbo wọn: nígbà tí ó si bù ú, ó bẹ̀rẹ̀ sí i jẹ.

  23. Àwọn arákùnrin ibẹ̀ gbúròó pé a ń bọ̀, wọ́n sì rìnrìn àjò títí wọ́n fi dé Apii Foroni àti sí ilé èrò mẹ́ta láti pàdé wa: nígbà tí Paulu sì rí wọn, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, ó sì mú ọkàn le.

  24. Ní àkọ́kọ́, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nípasẹ̀ Jesu Kristi fún gbogbo yín, nítorí a ń ròyìn ìgbàgbọ́ yin káàkiri gbogbo ayé.

  25. Lóòótọ́, wọn ní òye nípa Ọlọ́run dáradára, ṣùgbọ́n wọn kò yìn ín lógo bí Ọlọ́run, wọ́n kò sí dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀; wọ́n ń ro èrò asán, ọkàn aṣiwèrè wọn sì ṣókùnkùn.