Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Thanksgiving: For the grace bestowed on others

8 ẹsẹ · 57 abala

Àwọn ẹsẹ nípa For the grace bestowed on others

  1. Nígbà gbogbo ni mo ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ tó fi fún un yín nínú Kristi Jesu.

  2. Mo ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run mi ní gbogbo ìgbà tí mo bá rántí yín.

  3. Nínú gbogbo àdúrà mi fún un yín, èmi ń fi ayọ̀ gbàdúrà,

  4. nítorí ìdàpọ̀ yín nínú ìyìnrere láti ọjọ́ kìn-ín-ní wá títí di ìsinsin yìí.

  5. Nígbàkígbà tí a bá ń gbàdúrà fún un yín ni a máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run Baba Olúwa wa Jesu Kristi.

  6. Nítorí a ti gbúròó ìgbàgbọ́ yín nínú Jesu Kristi, àti bí ẹ ti ṣe fẹ́ràn gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́.

  7. Ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ tí ń sàn nínú ìrètí tí a gbé pamọ́ fún un yín ní ọ̀run èyí tí ẹ̀yin sì ti gbọ́ tẹ́lẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ òtítọ́ ìyìnrere náà,

  8. èyí tí ó ti dé ọ̀dọ̀ yín. Káàkiri àgbáyé ni ìyìnrere yìí ń so èso tí ó sì ń dàgbà, gẹ́gẹ́ bí ó ti ń ṣe láàrín yín láti ọjọ́ náà tí ẹ ti gbọ́ ọ, tí ẹ sì ní ìmọ̀ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run nínú gbogbo òtítọ́ rẹ̀.