Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Tabernacle: Made of the free-will offerings of the people

19 ẹsẹ · 94 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Made of the free-will offerings of the people

  1. Olúwa sì wí fún Mose pé,

  2. “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli kí wọn mú ọrẹ wá fún mi, ìwọ yóò gba ọrẹ náà fún mi ni ọwọ́ ọkùnrin kọ̀ọ̀kan ti ọkàn rẹ bá fẹ́ láti fi fún mi.

  3. “Wọ̀nyí ni ọrẹ ti ìwọ yóò gbà ni ọwọ́ wọn: “wúrà, fàdákà àti idẹ;

  4. aṣọ aláró, elése àlùkò, òdòdó, ọ̀gbọ̀; irun ewúrẹ́.

  5. Awọ àgbò tí a rẹ ní pupa àti awọ ewúrẹ́ igbó; igi kasia;

  6. Òróró olifi fún iná títàn; òróró olóòórùn dídùn fún ìtasórí àti fún tùràrí olóòórùn dídùn;

  7. àti òkúta óníkìsì àti òkúta olówó iyebíye ti a fi ṣe ọ̀ṣọ́ sí ara ẹ̀wù efodu àti ẹ̀wù ìgbàyà.

  8. “Nígbà náà ni ìwọ yóò jẹ́ kí wọn kọ́ ibi mímọ́ fún mi. Èmi yóò sì máa gbé ní àárín wọn.

  9. Mose sọ fún gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa pàṣẹ.

  10. Láti inú ohun tí ẹ ni ni kí ẹ ti mú ọrẹ fún Olúwa. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ ni kí ó mú ọrẹ fún Olúwa ní ti: “wúrà, fàdákà àti idẹ;

  11. olúkúlùkù ẹni tí ó fẹ́ àti ẹni tí ọkàn rẹ̀ gbé sókè wá, wọ́n sì mú ọrẹ fún Olúwa, fún iṣẹ́ àgọ́ àjọ, fún gbogbo ìsìn rẹ̀ àti fún aṣọ mímọ́ náà.

  12. Gbogbo àwọn tí ó fẹ́, ọkùnrin àti obìnrin, wọ́n wá wọ́n sì mú onírúurú ìlẹ̀kẹ̀ wúrà: òrùka etí, òrùka àti ọ̀ṣọ́. Gbogbo wọn mú wúrà gẹ́gẹ́ bí ọrẹ wá fún Olúwa.

  13. Olúkúlùkù ẹni tí ó ni aṣọ aláró elése àlùkò, òdòdó àti ọ̀gbọ̀ dáradára, tàbí irun ewúrẹ́, awọ àgbò tí a rì ní pupa tàbí awọ màlúù odò, kí ó mú wọn wá.

  14. Àwọn tí ó mú ọrẹ fàdákà tàbí idẹ wá, mú ọrẹ wá fún Olúwa, àti olúkúlùkù ẹni tí ó ní igi ṣittimu fún ipa kankan nínú iṣẹ́ mú un wá.

  15. Gbogbo àwọn obìnrin tí ó ní ọgbọ́n ríran owú pẹ̀lú ọwọ́ rẹ̀, kí ó mú èyí ti ó ti ran wá ti aláró, ti elése àlùkò, ti òdòdó tàbí ti ọ̀gbọ̀ dáradára.

  16. Gbogbo àwọn obìnrin tí ó fẹ́, tí ó sì ní ọgbọ́n ń ran òwú irun ewúrẹ́.

  17. Àwọn olórí mú òkúta óníkìsì wá láti tò ó lórí ẹ̀wù efodu àti ìgbàyà.

  18. Wọ́n sì tún mú olóòórùn àti òróró olifi wá fún títanná àti fún òróró ìtasórí àti fún tùràrí dídùn.

  19. Gbogbo àwọn ènìyàn Israẹli ọkùnrin àti obìnrin ẹni tí ó fẹ́ mú ọrẹ àtinúwá fún Olúwa fún gbogbo iṣẹ́ tí Olúwa ti pàṣẹ fún wọn láti ṣe nípasẹ̀ Mose.