Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Tabernacle: Renewed by David, and pitched on Mount Zion

4 ẹsẹ · 94 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Renewed by David, and pitched on Mount Zion

  1. Lẹ́yìn ìgbà tí Dafidi ti kọ́ ilé fún ara rẹ̀ ní ìlú Dafidi. Ó sì fi ààyè sílẹ̀ fún àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run ó sì pàgọ́ fún un.

  2. Wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run, wá sínú àgọ́ ti Dafidi ti pèsè fún un, wọ́n sì gbé ẹbọ sísun àti ọrẹ ìdàpọ̀ kalẹ̀ níwájú Ọlọ́run.

  3. Lẹ́yìn tí Dafidi parí ẹbọ sísun àti ọrẹ ìdàpọ̀, ó bùkún àwọn ènìyàn ní orúkọ Olúwa.

  4. Nísinsin yìí, Dafidi ti gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run wá láti Kiriati-Jearimu sí ibi tí ó ti pèsè fún un, nítorí ó ti kọ́ àgọ́ fún un ni Jerusalẹmu.