Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Tabernacle: Sprinkled with blood

8 ẹsẹ · 94 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Sprinkled with blood

  1. “Nígbà yìí ni yóò pa ewúrẹ́ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó wà fún àwọn ènìyàn yóò sì mú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá sí ẹ̀yìn aṣọ títa, bí ó ti ṣe ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù náà ni yóò ṣe ti ewúrẹ́ yìí, yóò sì wọ́n ọn sórí ìtẹ́ ètùtù àti síwájú ìtẹ́ ètùtù.

  2. Báyìí ni yóò ṣe ètùtù fún Ibi Mímọ́ Jùlọ nítorí àìmọ́ àwọn ará Israẹli àti nítorí gbogbo ìrékọjá wọn àti ìṣọ̀tẹ̀ wọn nípa ẹ̀ṣẹ̀ wọn gbogbo, bákan náà ni yóò sì ṣe fún àgọ́ ìpàdé, èyí tí ó wà láàrín wọn nínú àìmọ́ wọn.

  3. Kí ó má ṣe sí ẹyọ ènìyàn kan nínú àgọ́ ìpàdé nígbà tí òun bá wọ Ibi Mímọ́ Jùlọ lọ láti ṣe ètùtù, títí di ìgbà tí yóò fi jáde lẹ́yìn tí ó ba ṣe ètùtù fúnra rẹ̀ fún ìdílé rẹ̀ àti fún gbogbo àgbájọpọ̀ Israẹli.

  4. “Lẹ́yìn náà òun yóò lọ sí ibi pẹpẹ tí ó wà níwájú Olúwa, yóò sì ṣe ètùtù fún pẹpẹ náà. Yóò sì mú nínú ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù àti nínú ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ náà, yóò sì fi sí orí ọ̀kọ̀ọ̀kan ìwo pẹpẹ náà yíká.

  5. Lẹ́yìn náà, òun yóò wọ́n ẹ̀jẹ̀ náà sórí rẹ̀ pẹ̀lú ìka rẹ̀ nígbà méje láti wẹ̀ ẹ́ mọ́ àti láti sọ ọ́ dí mímọ́ kúrò nínú àìmọ́ àwọn ọmọ Israẹli.

  6. “Lẹ́yìn ti Aaroni ti parí ṣíṣe ètùtù ti Ibi Mímọ́ Jùlọ, ti àgọ́ ìpàdé àti ti pẹpẹ, òun yóò sì mú ààyè ewúrẹ́ wá.

  7. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ó sì fi ẹ̀jẹ̀ wọ́n àgọ́, àti gbogbo ohun èlò ìsìn.

  8. Nítorí náà a kò lè ṣàì fi ìwọ̀nyí wé àwọn àpẹẹrẹ ohun tí ń bẹ lọ́run mọ́; ṣùgbọ́n ó yẹ kí a fi ẹbọ tí ó sàn ju ìwọ̀nyí lọ wẹ àwọn ohun ọ̀run pàápàá mọ́; ṣùgbọ́n ó yẹ kí a fi ẹbọ tí ó sàn ju ìwọ̀nyí lọ wẹ àwọn ohun ọ̀run pàápàá mọ́.