Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Tabernacle: Tabernacle of the Lord
Àwọn ẹsẹ nípa Tabernacle of the Lord
Bí ilẹ̀ ìní yín bá di àìmọ́, ẹ wá sí orí ilẹ̀ ìní Olúwa, ní ibi tí àgọ́ Olúwa dúró sí, kí ẹ sì pín ilẹ̀ náà pẹ̀lú wa. Ṣùgbọ́n kí ẹ má ṣe ṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa tàbí sí wa nípa mímọ pẹpẹ fún ara yín, lẹ́yìn pẹpẹ Olúwa Ọlọ́run wa.
Nígbà tí ìròyìn sì dé ọ̀dọ̀ Joabu, ẹni tí ó ti dìtẹ̀ pẹ̀lú Adonijah bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò wà pẹ̀lú Absalomu, ó sì sálọ sínú àgọ́ Olúwa, ó sì di ìwo pẹpẹ mú.
Dafidi fi Sadoku àlùfáà àti àwọn àlùfáà ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ níwájú Àgọ́ Olúwa ní ibi gíga ní Gibeoni.