Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Tabernacle: Performed all services in
Àwọn ẹsẹ nípa Performed all services in
Kí o sì yan Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ láti máa ṣiṣẹ́ àlùfáà; àlejò tó bá súnmọ́ ibi mímọ́ pípa ni kí ẹ pa á.”
Olúwa sọ fún Aaroni pé, “Ìwọ, àti àwọn ọmọ rẹ àti ìdílé baba rẹ ni yóò ru gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ti dá fún ilé tí a yà sí mímọ́ fún Ọlọ́run, àti ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ nìkan ni yóò máa ru ẹ̀ṣẹ̀ iṣẹ́ àlùfáà yín.
Kí o sì mú àwọn ènìyàn rẹ ará Lefi láti ẹ̀yà ìran rẹ láti dàpọ̀ mọ́ ìwọ láti ràn ọ́ lọ́wọ́ nígbà tí ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin bá ń ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ níwájú Àgọ́ ẹ̀rí.
Ǹjẹ́ nígbà tí a ti ṣe ètò nǹkan wọ̀nyí báyìí, àwọn àlùfáà a máa lọ nígbàkígbà sínú àgọ́ èkínní, wọn a máa ṣe iṣẹ́ ìsìn.