Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Tabernacle: With the bars, covered with gold
Àwọn ẹsẹ nípa With the bars, covered with gold
“Ìwọ ó sì ṣe ọ̀pá ìdábùú igi kasia; márùn-ún fún pákó ìhà kan àgọ́ náà,
márùn-ún fún àwọn ìhà kejì, àti márùn-ún fún pákó ni ìhà ìwọ̀-oòrùn ní ìhà ẹ̀yìn àgọ́ náà.
Ọ̀pá ìdábùú àárín ni agbede-méjì gbọdọ̀ tàn láti ìkangun dé ìkangun pákó náà.
Ìwọ́ ó sì bo àwọn pákó náà pẹ̀lú wúrà, kí o sì ṣe òrùka wúrà kí ó lè di ọ̀pá ìdábùú mu. Kí o sì tún bo ọ̀pá ìdábùú náà pẹ̀lú wúrà.
Ó sì bo àwọn pákó pẹ̀lú wúrà, wọ́n sì ṣe àwọn òrùka wúrà láti gbá ọ̀pá náà mú. Wọ́n sì tún bo ọ̀pá náà pẹ̀lú wúrà.