Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Tabernacle: The Lord appeared in, over the mercy-seat
Àwọn ẹsẹ nípa The Lord appeared in, over the mercy-seat
Níbẹ̀, ni òkè ìtẹ́, ní àárín kérúbù méjèèjì ti ó wà ni orí àpótí ẹ̀rí ni èmi yóò ti pàdé rẹ, ti èmi yóò sì fún ọ ní àwọn òfin mi fún àwọn ọmọ Israẹli.
Olúwa sì sọ fún Mose pé, “Kìlọ̀ fún Aaroni arákùnrin rẹ pé kí ó má ṣe máa wá nígbà gbogbo sí Ibi Mímọ́ Jùlọ tí ó wà lẹ́yìn aṣọ títa ní ibi tí àpótí ẹ̀rí àti ìtẹ́ àánú wà, kí ó má ba à kú nítorí pé Èmi ó farahàn nínú ìkùùkuu lórí ìtẹ́ àánú.
Nígbà tí Mose wọ inú àgọ́ ìpàdé láti bá Olúwa sọ̀rọ̀, Olúwa sì sọ̀rọ̀ sí i láti àárín àwọn kérúbù méjì láti orí ìtẹ́ àánú tí ó bo àpótí ẹ̀rí, ohùn náà sì bá Mose sọ̀rọ̀.