Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Ships

79 ẹsẹ · 53 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ọ̀gbọ̀ dáradára aṣọ iṣẹ́ ọnà abẹ́rẹ́ láti Ejibiti wá ni èyí tí ìwọ ta láti fi ṣe àsíá ọkọ̀ rẹ; aṣọ aláró àti elése àlùkò láti erékùṣù ti Eliṣa ni èyí tí a fi bò ó.

  2. Àwọn ará ìlú Sidoni àti Arfadi ni àwọn atukọ̀ rẹ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n ẹ̀rọ rẹ, ìwọ Tire, ni àwọn atukọ̀ rẹ.

  3. Àwọn àgbàgbà Gebali, àti àwọn ọlọ́gbọ́n ibẹ̀, wà nínú ọkọ̀ bí òṣìṣẹ́ atukọ̀ rẹ, gbogbo ọkọ̀ ojú Òkun àti àwọn atukọ̀ Òkun wá pẹ̀lú rẹ láti dòwò pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.

  4. Ọrọ̀ rẹ, ọjà rẹ àti àwọn ohun títà rẹ, àwọn ìṣúra rẹ, òṣìṣẹ́ ìtukọ̀ rẹ. Àwọn oníbàárà rẹ àti gbogbo àwọn jagunjagun rẹ, tí ó wà nínú rẹ, àti nínú gbogbo ẹgbẹ́ rẹ tí ó wà ní àárín rẹ yóò rì sínú àárín gbùngbùn Òkun ní ọjọ́ ìparun rẹ.

  5. Ilẹ̀ etí Òkun yóò mì nítorí ìró igbe àwọn atukọ̀ rẹ.

  6. Gbogbo àwọn alájẹ̀, àwọn atukọ̀ Òkun àti àwọn atọ́kọ̀ ojú Òkun; yóò sọ̀ kálẹ̀ kúrò nínú ọkọ̀ wọn, wọn yóò dúró lórí ilẹ̀.

  7. Nítorí pé, ọkọ̀ ojú omi àwọn ilẹ̀ etídò ìwọ̀-oòrùn yóò takò ó, ọkàn rẹ̀ yóò sì pami. Nígbà náà, ni yóò padà, yóò sì bínú sí májẹ̀mú mímọ́, yóò sì padà, yóò sì fi ojúrere hàn sí àwọn tí ó kọ májẹ̀mú mímọ́ náà.

  8. “Ní ìgbà ìkẹyìn, ọba gúúsù yóò gbé ogun de sí i, ọba àríwá yóò sì jáde bí ìjì láti kọlù ú pẹ̀lú u kẹ̀kẹ́ ogun àti ẹlẹ́ṣin àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkọ̀ ojú omi. Yóò gbógun wọ orílẹ̀-èdè púpọ̀, yóò sì bo wọn mọ́lẹ̀ bí ìkún omi.

  9. Ṣùgbọ́n Jona dìde kúrò láti sálọ sí Tarṣiṣi kúrò níwájú Olúwa, ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí Joppa, ìbí ti ó tí rí ọkọ̀ kan tí ń lọ sí Tarṣiṣi: lẹ́yìn ti ó sanwó ọkọ̀, ó wọlé sínú rẹ̀, láti bá wọn lọ sí Tarṣiṣi kúrò níwájú Olúwa.

  10. Nígbà náà ni Olúwa rán ìjì ńlá jáde sí ojú Òkun, ìjì líle sì wà nínú Òkun tó bẹ́ẹ̀ tí ọkọ̀ náà dàbí ẹni pé yóò fọ́.

  11. Nígbà náà ni àwọn atukọ̀ bẹ̀rù, olúkúlùkù sì ń kígbe sí ọlọ́run rẹ̀, wọ́n kó ẹrù tí ó wà nínú ọkọ̀ dà sínú Òkun, kí ó bá à lè fúyẹ́. Ṣùgbọ́n Jona sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìsàlẹ̀ ọkọ̀ ó sì dùbúlẹ̀, ó sùn wọra.

  12. Bẹ́ẹ̀ ni olórí ọkọ̀ tọ̀ ọ́ wá, ó sì wí fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ fi sùn, ìwọ olóòórùn? Dìde kí o ké pe Ọlọ́run rẹ! Bóyá yóò ro tiwa, kí àwa má ba à ṣègbé.”

  13. Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin náà gbìyànjú gidigidi láti mú ọkọ̀ wà sí ilẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kò lè ṣe é: nítorí tí Òkun túbọ̀ ru sí i, ó sì ja ẹ̀fúùfù líle sí wọn.

  14. Bí ó sì ti kúrò ní ibẹ̀, ò rí àwọn arákùnrin méjì mìíràn, Jakọbu ọmọ Sebede àti Johanu, arákùnrin rẹ̀. Wọ́n wà nínú ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú Sebede baba wọn, wọ́n ń di àwọ̀n wọn, Jesu sì pè àwọn náà pẹ̀lú.

  15. Ìjì líle ńlá kan sì dìde, omi sì ń bù sínú ọkọ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí ọkọ̀ fi bẹ̀rẹ̀ sí í kún fún omi, ó sì fẹ́rẹ rì.

  16. Jesu ti sùn lọ lẹ́yìn ọkọ̀, ó gbé orí lé ìrọ̀rí. Wọ́n sì jí i lóhùn rara wí pé, “Olùkọ́ni, tàbí ìwọ kò tilẹ̀ bìkítà pé gbogbo wa fẹ́ rì?”

  17. Ó sì ṣe, nígbà tí ìjọ ènìyàn súnmọ́ ọn láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí ó sì dúró létí adágún Genesareti.

  18. Ó rí ọkọ̀ méjì ti o wá létí adágún: èyí tí àwọn apẹja ti sọ̀kalẹ̀ kúrò nínú wọn, nítorí tí wọ́n ń fọ àwọ̀n wọn.

  19. Bí ó sì ti dákẹ́ ọ̀rọ̀ sísọ, ó wí fún Simoni pé, “Tì í sí ibú, kí o sì ju àwọ̀n yín sí ìsàlẹ̀ fún àkópọ̀.”

  20. Simoni sì dáhùn ó sì wí fún un pé, “Olùkọ́ni, gbogbo òru ni àwa fi ṣiṣẹ́, àwa kò sì mú nǹkan kan: ṣùgbọ́n nítorí ọ̀rọ̀ rẹ èmi ó ju àwọ̀n náà sí ìsàlẹ̀.”

  21. Nígbà tí wọ́n sì ti ṣe èyí, wọ́n kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹja: àwọ̀n wọn sì ya.

  22. Wọ́n sì pe àwọn ẹgbẹ́ wọn, tí ó wà nínú ọkọ̀ kejì, kí wọn kí ó wá ràn wọ́n lọ́wọ́. Wọ́n sì wá, wọ́n kó ẹja ọkọ̀ méjèèjì sì kún, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í rì.

  23. Nígbà tí Simoni Peteru sì rí i, ó wólẹ̀ lẹ́bàá eékún Jesu, ó wí pé, “Lọ kúrò lọ́dọ̀ mi Olúwa; nítorí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni mí.”

  24. Ẹnu sì yà wọ́n, àti gbogbo àwọn tí ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀, fún àkópọ̀ ẹja tí wọ́n kó,

  25. Nígbà tí wọ́n wa ọkọ̀ ojú omi tó bí ìwọ̀n ibùsọ̀ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n tàbí ọgbọ̀n, wọ́n rí Jesu ń rìn lórí Òkun, ó sì súnmọ́ ọkọ̀ ojú omi náà; ẹ̀rù sì bà wọ́n.