Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Select Readings

802 ẹsẹ · 47 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Èmi kò sì ri tẹmpili nínú rẹ̀, nítorí pé Olúwa Ọlọ́run Olódùmarè ni tẹmpili rẹ̀, àti Ọ̀dọ́-àgùntàn.

  2. Ìlú náà kò sì ní oòrùn, tàbí òṣùpá, láti máa tan ìmọ́lẹ̀ sí i, nítorí pé ògo Ọlọ́run ni ó ń tàn ìmọ́lẹ̀ sí i, Ọ̀dọ́-àgùntàn sì ni fìtílà rẹ̀.

  3. Àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì máa rìn nípa ìmọ́lẹ̀ rẹ̀, àwọn ọba ayé sì ń mú ògo wọn wá sínú rẹ̀.

  4. A kì yóò sì ṣé àwọn ẹnu ibodè rẹ̀ rárá ní ọ̀sán: nítorí ki yóò si òru níbẹ̀.

  5. Wọ́n ó sì máa mú ògo àti ọlá àwọn orílẹ̀-èdè wá sínú rẹ̀.

  6. Ohun aláìmọ́ kan ki yóò sì wọ inú rẹ̀ rárá, tàbí ohun tí ń ṣiṣẹ́ ìríra àti èké; bí kò ṣe àwọn tí a kọ sínú ìwé ìyè Ọ̀dọ́-àgùntàn.

  7. Ó sì fi odò omi ìyè kan hàn mi, tí ó mọ́ bí kirisitali, tí ń tí ibi ìtẹ́ Ọlọ́run àti tí Ọ̀dọ́-Àgùntàn jáde wá,

  8. ní àárín ìgboro rẹ̀, àti níhà èkínní kejì odò náà, ni igi ìyè gbé wà, tí o máa ń so onírúurú èso méjìlá, a sì máa so èso rẹ̀ ni oṣooṣù ewé igi náà sí wà fún mímú àwọn orílẹ̀-èdè láradà.

  9. Ègún kì yóò sì ṣí mọ: ìtẹ́ Ọlọ́run àti tí Ọ̀dọ́-àgùntàn ni yóò sì máa wà níbẹ̀; àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò sì máa sìn ín.

  10. Wọ́n ó si máa rí ojú rẹ̀; orúkọ rẹ̀ yóò si máa wà ni iwájú orí wọn.

  11. Òru kì yóò sí mọ́; wọn kò sì ní wa ìmọ́lẹ̀ fìtílà, tàbí ìmọ́lẹ̀ oòrùn; nítorí pé Olúwa Ọlọ́run ni yóò tan ìmọ́lẹ̀ fún wọn: wọn ó sì máa jẹ ọba láé àti láéláé.

  12. Ó sì wí fún mi pé, “Òdodo àti òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: Olúwa Ọlọ́run ẹ̀mí àwọn wòlíì ni ó sì ran angẹli rẹ̀ láti fi ohun tí ó ní láti ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ yìí hàn àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.”

  13. “Kíyèsi i, èmi ń bọ̀ kánkán! Ìbùkún ni fún ẹni tí ń pa ọ̀rọ̀ ìsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé yìí mọ́!”

  14. Èmi, Johanu, ni ẹni tí ó gbọ́ tí ó sì ri nǹkan wọ̀nyí. Nígbà tí mo sì gbọ́ tí mo sì rí, mo wólẹ̀ láti foríbalẹ̀ níwájú ẹsẹ̀ angẹli náà, tí o fi nǹkan wọ̀nyí hàn mi.

  15. Nígbà náà ni ó wí fún mi pé, “Wó ò, má ṣe bẹ́ẹ̀, ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ ni èmi, àti ti àwọn arákùnrin rẹ̀ wòlíì, àti ti àwọn tí ń pa ọ̀rọ̀ inú ìwé yìí mọ́. Foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run!”

  16. Ó sì wí fún mi pé, “Má ṣe fi èdìdì di ọ̀rọ̀ ìsọtẹ́lẹ̀ tí inú ìwé yìí, nítorí ìgbà kù sí dẹ̀dẹ̀.

  17. Ẹni tí ń ṣe aláìṣòótọ́, kí ó máa ṣe aláìṣòótọ́ nì só; àti ẹni tí ń ṣe ẹlẹ́gbin, kí ó máa ṣe ẹ̀gbin nì só; àti ẹni tí ń ṣe olódodo, kí ó máa ṣe òdodo nì só; àti ẹni tí ń ṣe mímọ́, kí ó máa ṣe mímọ́ nì só.”

  18. “Kíyèsi i, èmi ń bọ̀ kánkán; èrè mí sì ń bẹ pẹ̀lú mi, láti sán fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀ yóò tí rí.

  19. Èmi ni Alfa àti Omega, ẹni ìṣáájú àti ẹni ìkẹyìn, ìpilẹ̀ṣẹ̀ àti òpin.

  20. “Ìbùkún ni fún àwọn ti ń fọ aṣọ wọn, kí wọ́n lè ni ẹ̀tọ́ láti wá sí ibi igi ìyè náà, àti kí wọ́n lè gbà àwọn ẹnu ibodè wọ inú ìlú náà.

  21. Nítorí ni òde ni àwọn ajá gbé wà, àti àwọn oṣó, àti àwọn àgbèrè, àti àwọn apànìyàn, àti àwọn abọ̀rìṣà, àti olúkúlùkù ẹni tí ó fẹ́ràn èké tí ó sì ń hùwà èké.

  22. “Èmi, Jesu, ni ó rán angẹli mi láti jẹ́rìí nǹkan wọ̀nyí fún yin ní tí àwọn ìjọ. Èmi ni gbòǹgbò àti irú-ọmọ Dafidi, àti ìràwọ̀ òwúrọ̀ tí ń tàn.”

  23. Ẹ̀mí àti ìyàwó wí pé, “Máa bọ!” Àti ẹni tí ó ń gbọ́ kí ó wí pé, “Máa bọ̀!” Àti ẹni tí òǹgbẹ ń gbẹ kí ó wá, àti ẹni tí o bá sì fẹ́, kí ó gba omi ìyè náà lọ́fẹ̀ẹ́.

  24. Èmi kìlọ̀ fún olúkúlùkù ẹni tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ ìsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé yìí pé, bí ẹnikẹ́ni ba fi kún wọn, Ọlọ́run yóò fi kún àwọn ìyọnu tí a kọ sínú ìwé yìí fún un.

  25. Bí ẹnikẹ́ni bá sì mú kúrò nínú ọ̀rọ̀ ìwé ìsọtẹ́lẹ̀ yìí, Ọlọ́run yóò sì mú ipa tirẹ̀ kúrò nínú ìwé ìyè, àti kúrò nínú ìlú mímọ́ náà, àti kúrò nínú àwọn ohun tí a kọ sínú ìwé yìí.