Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Scribes

50 ẹsẹ · 27 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Àwọn kan jáde wá láti Efraimu, àwọn tí gbòǹgbò wọn wà ní Amaleki; Benjamini wà pẹ̀lú àwọn tí ó tẹ̀lé ọ. Láti Makiri ni àwọn aláṣẹ ti sọ̀kalẹ̀ wá, láti Sebuluni ni àwọn ẹni tí ń mú ọ̀pá oyè lọ́wọ́.

  2. Sadoku ọmọ Ahitubu, àti Ahimeleki ọmọ Abiatari, ni àwọn àlùfáà; Seraiah a sì máa ṣe akọ̀wé.

  3. Ṣefa sì jẹ́ akọ̀wé; Sadoku àti Abiatari sì ni àwọn àlùfáà.

  4. Ìgbàkígbà tí wọ́n bá ti rí wí pé owó púpọ̀ wà nínú àpótí, akọ̀wé ọba àti olórí àlùfáà yóò wá, wọ́n á ka owó náà tí wọ́n ti mú wá sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa. Wọn a sì kó o sínú àwọn àpò.

  5. Àti àwọn tí ó kù ní ìlú, ó mú ìwẹ̀fà kan tí ó fi se olórí àwọn ológun, àti ọkùnrin márùn-ún nínú àwọn tó ń gba ọba ní ìmọ̀ràn. Ó sì tún mú akọ̀wé olórí ogun, tí ó ń to àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà àti ọgọ́ta nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ tí wọ́n rí ní ìlú.

  6. àti àwọn ìdílé àwọn akọ̀wé, ẹni tí ń gbé ní Jabesi: àti àwọn ọmọ Tirati àti àwọn ará Ṣimeati àti àwọn ará Sukati. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ará Keni, ẹni tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Hamati, baba ilé Rekabu.

  7. Ṣemaiah ọmọ Netaneli, akọ̀wé ọ̀kan lára àwọn ọmọ Lefi sì kọ orúkọ wọn níwájú ọba àti àwọn ìjòyè: Sadoku àlùfáà, Ahimeleki ọmọ Abiatari àti olórí ìdílé àwọn àlùfáà tí a mú láti ọ̀dọ̀ Eleasari àti ọ̀kan láti ọ̀dọ̀ Itamari.

  8. Jonatani, arákùnrin Dafidi jẹ́ olùdámọ̀ràn, ọkùnrin onímọ̀ àti akọ̀wé. Jehieli ọmọ Hakmoni bojútó àwọn ọmọ ọba.

  9. Ussiah sì ní àwọn ẹgbẹ́ ogun tí wọ́n kọ́ dáradára, wọ́n múra tán láti lọ pẹ̀lú ẹgbẹgbẹ́ gẹ́gẹ́ bí iye kíkà wọn gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ Jeieli akọ̀wé àti Maaseiah ìjòyè lábẹ́ ọwọ́ Hananiah, ọ̀kan lára àwọn olórí ogun ọba.

  10. Wọ́n sì ní olórí àwọn aláàárù àti àwọn alábojútó gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ láti ibi iṣẹ́ sí ibi iṣẹ́, díẹ̀ nínú àwọn ọmọ Lefi sì ní akọ̀wé, olùtọ́jú àti olùṣọ́nà.

  11. Esra yìí sì gòkè wá láti Babeli. Olùkọ́ tí ó ní ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa òfin Mose, èyí tí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, ti fi fún wọn. Ọba sì fi gbogbo ohun tí ó béèrè fún un, nítorí ọwọ́ Olúwa Ọlọ́run wà lára rẹ̀.

  12. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù keje ni àlùfáà Esra gbé ìwé òfin jáde ní iwájú ìjọ ènìyàn, èyí tí ó jẹ́ àpapọ̀ ọkùnrin àti obìnrin àti gbogbo àwọn ènìyàn tí wọ́n le è gbọ́ ọ ní àgbọ́yé.

  13. Ó kà á sókè láti òwúrọ̀ títí di ọ̀sán bí ó ti kọjú sí ìta ní iwájú ibodè omi ní ojú u gbogbo ọkùnrin, obìnrin àti àwọn ènìyàn tókù tí òye le è yé tí wọ́n wà níbẹ̀. Gbogbo ènìyàn sì fetísílẹ̀ sí ìwé òfin náà pẹ̀lú ìfarabalẹ̀.

  14. Akọ̀wé Esra dìde dúró lórí i pẹpẹ ìdúrólé tí a fi igi kàn fún ètò yìí. Ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ọ̀tún ni Mattitiah, Ṣema, Anaiah, Uriah, Hilkiah àti Maaseiah gbé dúró sí, ní ẹ̀gbẹ́ òsì rẹ̀ ní Pedaiah, Misaeli, Malkiah, Haṣumu, Haṣabadana, Sekariah àti Meṣullamu dúró sí.

  15. Esra ṣí ìwé náà, gbogbo ènìyàn sì le rí í nítorí ó dúró níbi tí ó ga ju gbogbo ènìyàn lọ; bí ó sì ti ṣí ìwé náà, gbogbo ènìyàn dìde dúró.

  16. Esra yin Olúwa, Ọlọ́run alágbára; gbogbo ènìyàn gbé ọwọ́ wọn sókè, wọ́n sì wí pé, “Àmín! Àmín!” Nígbà náà ni wọ́n wólẹ̀ wọ́n sì sin Olúwa ní ìdojúbolẹ̀.

  17. Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹtàlá oṣù kìn-ín-ní àkọ́kọ́, wọ́n pe àwọn akọ̀wé ọba jọ. Wọ́n kọ ọ́ ní ìlànà bí ìgbèríko kọ̀ọ̀kan ṣe ń kọ̀wé, ó kọ̀wé sí àwọn ènìyàn kọ̀ọ̀kan ní èdè wọn gbogbo èyí tí Hamani ti pàṣẹ sí àwọn akọ̀wé ọba, sí baálẹ̀ ìgbèríko kọ̀ọ̀kan àti àwọn ọlọ́lá àwọn onírúurú ènìyàn. A kọ èyí ní orúkọ ọba Ahaswerusi fúnra rẹ̀ ó sì fi òrùka ọba ṣe èdìdì i rẹ̀.

  18. Fún adarí orin. Tí ohun orin “Lílì.” Ti orin àwọn ọmọ Kora. Maskili. Orin ìgbéyàwó. Ọkàn mi mọ ọ̀rọ̀ rere gẹ́gẹ́ bí mo ṣe ń sọ ohun tí mo ti ṣe fún ọba ahọ́n mi ni kálámù ayára kọ̀wé.

  19. Mo mú ìwé tí mo fi rà á, èyí tí a di pa nípa àṣẹ àti òfin wa, àti èyí tí a kò lẹ̀.

  20. Èmi sì fi èyí fún Baruku, ọmọ Neriah, ọmọ Maseiah, ní ojú Hanameli, ọmọ ẹ̀gbọ́n mi àti níwájú àwọn ẹlẹ́rìí tí ó ti fi ọwọ́ sí ìwé àti ní ojú àwọn Júù gbogbo tí wọ́n jókòó ní àgbàlá ilé túbú.

  21. Nígbà náà ni Jeremiah wí fún Baruku pé, “A sé mi mọ́! Èmi kò lè lọ sí ilé Olúwa.

  22. Dípò èyí ọba pàṣẹ fún Jerahmeeli ọmọ Hameleki, Seraiah ọmọ Asrieli àti Ṣelemiah ọmọ Abdeeli láti mú Baruku akọ̀wé àti Jeremiah wòlíì ṣùgbọ́n Olúwa fi wọ́n pamọ́.

  23. Nínú àwọn tí ó kù ní ilẹ̀ náà, ó mú ìwẹ̀fà kan, tí ó wà ní ìtọ́jú àwọn ológun, àti àwọn olùdámọ̀ràn ọba méje. Bákan náà, ó tún mu akọ̀wé olórí ogun tí ó wà ní ìtọ́jú títo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà, àti ọgọ́ta nínú àwọn ọkùnrin rẹ̀ tí wọ́n rí ní ìlú náà.

  24. Lójú ẹsẹ̀ ni ọkùnrin mẹ́fà jáde láti ẹnu-ọ̀nà òkè tó kọjú sí ìhà àríwá, olúkúlùkù pẹ̀lú ohun ìjà olóró lọ́wọ́ wọn. Ọkùnrin kan tó wọ aṣọ funfun gbòò wa láàrín wọn, pẹ̀lú ohun ìkọ̀wé lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Gbogbo wọn sì dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ idẹ.

  25. Ògo Ọlọ́run Israẹli sì gòkè kúrò lórí kérúbù, níbi tó wà tẹ́lẹ̀ lọ sí ibi ìloro tẹmpili. Nígbà náà ni Olúwa pe ọkùnrin tó wọ aṣọ funfun náà tí ó sì ní ohun ìkọ̀wé lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀.