Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Scribes: Levi
Àwọn ẹsẹ nípa Levi
Ṣemaiah ọmọ Netaneli, akọ̀wé ọ̀kan lára àwọn ọmọ Lefi sì kọ orúkọ wọn níwájú ọba àti àwọn ìjòyè: Sadoku àlùfáà, Ahimeleki ọmọ Abiatari àti olórí ìdílé àwọn àlùfáà tí a mú láti ọ̀dọ̀ Eleasari àti ọ̀kan láti ọ̀dọ̀ Itamari.
Wọ́n sì ní olórí àwọn aláàárù àti àwọn alábojútó gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ láti ibi iṣẹ́ sí ibi iṣẹ́, díẹ̀ nínú àwọn ọmọ Lefi sì ní akọ̀wé, olùtọ́jú àti olùṣọ́nà.