Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Rivers

89 ẹsẹ · 59 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ní ọdún kẹsànán ti Hosea, ọba Asiria mú Samaria ó sì kó Israẹli lọ sí Asiria. Ó sì fi wọ́n sílẹ̀ ní Hala, ní Gosani ní etí odò Habori àti ní ìlú àwọn ará Media.

  2. Nítorí náà Ọlọ́run Israẹli ru ẹ̀mí Pulu ọba Asiria sókè (èyí ni Tiglat-Pileseri ọba Asiria), ó si kó wọn lọ, àní àwọn ọmọ Reubeni àti àwọn ọmọ Gadi, àti ààbọ̀ ẹ̀yà Manase lọ sí ìgbèkùn. Ó sì kó wọn wá sí Hala, àti Habori, àti Harani, àti sí etí odò Gosani; títí dí òní yìí.

  3. Àwọn ni ẹni tí ó rékọjá Jordani ní oṣù àkọ́kọ́ nígbà tí ó kún bo gbogbo bèbè rẹ̀, wọ́n sì lé gbogbo àwọn tí ó ń gbé nínú àfonífojì, lọ sí ìlà-oòrùn àti níhà ìwọ̀-oòrùn.

  4. Èmi kó wọn jọ pọ̀ si etí odò ti ń sàn lọ sí Ahafa, a pàgọ́ síbẹ̀ fún odidi ọjọ́ mẹ́ta, nígbà ti mo wo àárín àwọn ènìyàn àti àárín àwọn àlùfáà, ń kò rí ọmọ Lefi kankan níbẹ̀.

  5. Kì yóò rí odò wọ̀n-ọn-nì, ìṣàn omi, odò tí ń ṣàn fún oyin àti ti òrí-àmọ́.

  6. Ó sì la ipa odò ṣíṣàn nínú àpáta, ojú inú rẹ̀ sì rí ohun iyebíye gbogbo.

  7. nígbà tí èmi fi òrí-àmọ́ n wẹ ìṣísẹ̀ mi, àti tí àpáta ń tú ìṣàn òróró jáde fún mi wá.

  8. Ó dàbí igi tí a gbìn sí etí odò tí ń sàn, tí ń so èso rẹ̀ jáde ní àkókò rẹ̀ tí ewé rẹ̀ kì yóò rẹ̀. Ohunkóhun tí ó dáwọ́lé, ni yóò máa yọrí sí rere.

  9. Odò ńlá kan wà tí ṣíṣàn rẹ̀ mú inú ìlú Ọlọ́run dùn, ibi mímọ́, níbi ti Ọ̀gá-ògo ń gbé.

  10. Mo ń rì nínú irà jíjìn, níbi tí kò sí ibi ìfẹsẹ̀lé. Mo ti wá sínú omi jíjìn; ìkún omi bò mí mọ́lẹ̀.

  11. Ìwọ ya orísun omi àti ìṣàn omi; Ìwọ mú kí odò tó ń sàn gbẹ.

  12. wọ́n sàn kọjá lórí àwọn òkè, wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ sí àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀, sí ibi tí ìwọ ti yàn fún wọn.

  13. Ìwọ mú kí ìsun da omi sí àwọn àfonífojì; tí ó ń sàn láàrín àwọn òkè.

  14. Ní ẹ̀bá odò Babeli, níbẹ̀ ni àwa gbé jókòó àwa sì sọkún nígbà tí àwa rántí Sioni.

  15. Gbogbo odò ń sàn sí inú Òkun, síbẹ̀síbẹ̀ Òkun kò kún. Níbi tí àwọn odò ti wá, níbẹ̀ ni wọ́n tún padà sí.

  16. Ojú rẹ̀ rí bí i ti àdàbà ní ẹ̀bá odò tí ń sàn, tí a fi wàrà wẹ̀, tí ó jì, tí ó sì dákẹ́ rọ́rọ́.

  17. ǹjẹ́ nítorí náà kíyèsi i, Olúwa ń fa omi odò tí ó le, tí ó sì pọ̀ wá sórí wọn, àní, ọba Asiria àti gbogbo ògo rẹ̀, yóò sì wá sórí gbogbo ọ̀nà odò rẹ̀, yóò sì gun orí gbogbo bèbè rẹ̀,

  18. yóò sì gbá àárín Juda kọjá, yóò sì ṣàn bò ó mọ́lẹ̀, yóò sì mú un dọ́rùn. Nínà ìyẹ́ apá rẹ̀ yóò sì bo gbogbo ìbú ilẹ̀ rẹ̀, ìwọ Emmanueli.”

  19. Òdodo ni yóò jẹ́ ìgbànú rẹ̀ àti òtítọ́ ni yóò ṣe ọ̀já yí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ká.

  20. Gẹ́gẹ́ bí alárìnkiri ẹyẹ tí a tì jáde kúrò nínú ìtẹ́, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àwọn obìnrin Moabu ní àwọn ìwọdò Arnoni.

  21. Ègbé ni fún ilẹ̀ tí ó kún fún ariwo ìyẹ́ eṣú, ní àwọn ipadò Kuṣi,

  22. Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Ejibiti. Kíyèsi i, Olúwa gun àwọsánmọ̀ tí ó yára lẹ́ṣin ó sì ń bọ̀ wá sí Ejibiti. Àwọn ère òrìṣà Ejibiti wárìrì níwájú rẹ̀, ọkàn àwọn ará Ejibiti sì ti domi nínú wọn.

  23. “Èmi yóò rú àwọn ará Ejibiti sókè sí ara wọn arákùnrin yóò bá arákùnrin rẹ̀ jà, aládùúgbò yóò dìde sí aládùúgbò rẹ̀, ìlú yóò dìde sí ìlú, ilẹ̀ ọba sí ilẹ̀ ọba.

  24. Àwọn ará Ejibiti yóò sọ ìrètí nù, èmi yóò sì sọ èrò wọn gbogbo di òfo; wọn yóò bá àwọn òrìṣà àti ẹ̀mí àwọn òkú sọ̀rọ̀, àwọn awoṣẹ́ àti àwọn abókùúsọ̀rọ̀.

  25. Èmi yóò fi Ejibiti lé agbára àwọn ìkà amúnisìn lọ́wọ́, ọba aláìláàánú ni yóò jẹ ọba lé wọn lórí,” ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.