Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Rivers: (Overflowing of,) of God's judgments

5 ẹsẹ · 59 abala

Àwọn ẹsẹ nípa (Overflowing of,) of God's judgments

  1. ǹjẹ́ nítorí náà kíyèsi i, Olúwa ń fa omi odò tí ó le, tí ó sì pọ̀ wá sórí wọn, àní, ọba Asiria àti gbogbo ògo rẹ̀, yóò sì wá sórí gbogbo ọ̀nà odò rẹ̀, yóò sì gun orí gbogbo bèbè rẹ̀,

  2. yóò sì gbá àárín Juda kọjá, yóò sì ṣàn bò ó mọ́lẹ̀, yóò sì mú un dọ́rùn. Nínà ìyẹ́ apá rẹ̀ yóò sì bo gbogbo ìbú ilẹ̀ rẹ̀, ìwọ Emmanueli.”

  3. Kíyèsi i, Olúwa ní ẹnìkan tí ó le, tí ó sì lágbára, gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ yìnyín àti bí ìjì apanirun, gẹ́gẹ́ bí àrọ̀dá òjò àti òjò tí ó mú ìkún omi wá, òun yóò fi tipátipá sọ ọ́ sílẹ̀.

  4. Májẹ̀mú yín tí ẹ bá ikú dá ni a ó fa igi lé; àdéhùn yín pẹ̀lú ibojì ni kì yóò dúró. Nígbà tí ìbínú gbígbóná náà bá fẹ́ kọjá, a ó ti ipa rẹ̀ lù yín bolẹ̀.

  5. Báyìí ni Olúwa wí: “Wo bí omi ti ń ru sókè ní àríwá, wọn ó di odò tí ń bo bèbè mọ́lẹ̀. Wọn kò ní borí ilẹ̀ àti ohun gbogbo tó wà lórí rẹ̀, ìlú àti àwọn tó ń gbé nínú wọn. Àwọn ènìyàn yóò kígbe, gbogbo olùgbé ilẹ̀ náà yóò hu