Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Rivers: Of the gifts and graces of the Holy Spirit
Àwọn ẹsẹ nípa Of the gifts and graces of the Holy Spirit
Odò ńlá kan wà tí ṣíṣàn rẹ̀ mú inú ìlú Ọlọ́run dùn, ibi mímọ́, níbi ti Ọ̀gá-ògo ń gbé.
Èmi yóò mú kí odò kí ó sàn ní ibi gíga àti orísun omi ní àárín àfonífojì. Èmi yóò sọ aṣálẹ̀ di adágún omi, àti ilẹ̀ tí ó gbẹ gidigidi di orísun omi.
Wò ó, Èmi ń ṣe ohun tuntun! Nísinsin yìí, ó ti yọ sókè; àbí o kò rí i bí? Èmi ń ṣe ọ̀nà kan nínú aṣálẹ̀ àti odò nínú ilẹ̀ ṣíṣá.
Àwọn ẹhànnà ẹranko bọ̀wọ̀ fún mi, àwọn ajáko àti àwọn òwìwí, nítorí pé mo pèsè omi nínú aṣálẹ̀ àti odò nínú ilẹ̀ sísá, láti fi ohun mímu fún àwọn ènìyàn mi, àyànfẹ́ mi,
Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà mí gbọ́ gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti wí, láti inú rẹ̀ ni odò omi ìyè yóò ti máa sàn jáde wá.”
Ṣùgbọ́n ó sọ èyí ní ti ẹ̀mí, tí àwọn tí ó gbà á gbọ́ ń bọ̀ wá gbà, nítorí a kò tí ì fi Èmí Mímọ́ fún ni; nítorí tí a kò tí ì ṣe Jesu lógo.