Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Righteousness

480 ẹsẹ · 132 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Kíyèsi i, nítorí ohun kan náà yìí tí a mú yin banújẹ́ fún bí ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run, irú ìmúraṣíṣẹ́ tí ó mú jáde nínú yín, wíwẹ ara yín mọ́ ń kọ́, ìbànújẹ́ ń kọ́, ìpayà ń kọ́, ìfojúṣọ́nà ń kọ́, ìtara ń kọ́, ìjẹ́ni-níyà ń kọ́. Nínú ohun àmì kọ̀ọ̀kan yìí ni ẹ̀yin ti fi ara yín hàn bí aláìlẹ́bi nínú ọ̀ràn náà.

  2. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ́ ọ pé: “Ó tí fọ́nká; ó ti fi fún àwọn tálákà, òdodo rẹ̀ dúró láéláé.”

  3. Ǹjẹ́ ẹni tí ń fi irúgbìn fún afúnrúgbìn, àti àkàrà fún oúnjẹ, yóò fi irúgbìn fún un yín, yóò sì sọ ọ́ di púpọ̀, yóò sì mú èso òdodo yín bí sí i.

  4. Àwa ń sọ gbogbo èrò àti gbogbo ohun gíga ti ń gbe ara rẹ̀ ga sí ìmọ̀ Ọlọ́run kalẹ̀, àwa sì ń di gbogbo èrò ní ìgbèkùn wá sí ìtẹríba fún Kristi.

  5. Ẹ máa wádìí ara yín, bí ẹ̀yin bá wà nínú ìgbàgbọ́; ẹ máa dán ara yín wò. Tàbí ẹ̀yin fúnra yín kò mọ ara yín pé Jesu Kristi wá nínú yín? Àfi bí ẹ̀yin bá jẹ́ àwọn tí a tanù.

  6. tí a mọ̀ pé a kò dá ẹnikẹ́ni láre nípa iṣẹ́ òfin, bí kò ṣe nípa ìgbàgbọ́ nínú Jesu Kristi, àní àwa pẹ̀lú gbà Jesu Kristi gbọ́, kí a bá a lè dá wa láre nípa ìgbàgbọ́ tí Kristi, kì í sì i ṣe nípa iṣẹ́ òfin, nítorí pé nípa iṣẹ́ òfin kò sí ènìyàn kan tí a ó dá láre.

  7. Èmi kò ya oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run sí apá kan, nítorí pé bí a bá le ti ipasẹ̀ òfin jèrè òdodo, a jẹ́ pé Kristi kú lásán.”

  8. Nítorí náà òfin ha lòdì sí àwọn ìlérí Ọlọ́run bí? Kí a má rí i; nítorí ìbá ṣe pé a ti fi òfin kan fún ni tí ó lágbára láti sọ ni di ààyè nítòótọ́ òdodo ìbá ti tipasẹ̀ òfin wà.

  9. Àti nítorí tí ẹ̀yin jẹ́ ọmọ, Ọlọ́run sì ti rán Ẹ̀mí Ọmọ rẹ̀ wá sínú ọkàn yín, tí ń ké pé, “Ábbà, Baba.”

  10. Nítorí nípa Ẹ̀mí àwa ń fi ìgbàgbọ́ dúró de ìrètí òdodo.

  11. Ṣùgbọ́n èso ti Ẹ̀mí ni ìfẹ́, ayọ̀, àlàáfíà, ìpamọ́ra, ìwà pẹ̀lẹ́, ìṣoore, ìgbàgbọ́,

  12. ìwà tútù, àti ìkóra-ẹni níjanu, òfin kan kò lòdì sí irú wọ̀nyí,

  13. Kí a má ṣe tàn yín jẹ; a kò lè gan Ọlọ́run: nítorí ohunkóhun tí ènìyàn bá fúnrúgbìn, òhun ni yóò sì ká.

  14. Nítorí ẹni tí ó bá ń fúnrúgbìn sípa ti ara yóò ká ìdíbàjẹ́ ti ara ṣùgbọ́n ẹni tí ń fúnrúgbìn sípa ti ẹ̀mí yóò ti inú ẹ̀mí ká ìyè àìnípẹ̀kun.

  15. Àti ẹ̀yin pẹ̀lú darapọ̀ nínú Kristi nígbà tí ẹ̀yin gbọ́ ọ̀rọ̀ òtítọ́ náà àní ìyìnrere ìgbàlà yin. Nígbà tí ẹ̀yin gbàgbọ́, a fi Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe èdìdì ayé yin nínú rẹ, èyí tí a ti ṣe ìlérí rẹ̀ tẹ́lẹ̀,

  16. èyí tí ó jẹ́ ìdánilójú àṣansílẹ̀ ogún wa títí yóò fi di àkókò ìràpadà àwọn tí í ṣe ti Ọlọ́run sí ìyìn ògo rẹ̀.

  17. Nítorí oore-ọ̀fẹ́ ní a fi gbà yín là nípa ìgbàgbọ́. Èyí kì í ṣe nípa agbára ẹ̀yin fúnra yín: ẹ̀bùn Ọlọ́run ni,

  18. kì í ṣe nípa àwọn iṣẹ́, kí ẹnikẹ́ni má ba à ṣògo.

  19. kí ẹ sì gbé ọkùnrin tuntun ni wọ̀, èyí tí a dá ni àwòrán Ọlọ́run nínú òdodo àti ìwà mímọ́ ti òtítọ́.

  20. (nítorí èso Ẹ̀mí ni ìṣoore, àti òdodo àti òtítọ́).

  21. Ẹ dúró nítorí náà lẹ́yìn tí ẹ fi àmùrè òtítọ́ dì ẹ̀gbẹ́ yin, tí ẹ sì ti di ìgbàyà òdodo mọ́ra.

  22. lẹ́yìn ìgbà ti ẹ ti kún fún àwọn ìwà òdodo láti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi, fún ògo àti ìyìn Ọlọ́run.

  23. Ohun yówù kó ṣẹlẹ̀, ẹ jẹ́ kí ìgbé ayé yín ri gẹ́gẹ́ bí ìyìnrere Kristi: pé yálà bi mo tilẹ̀ wá wò yín, tàbí bí èmi kò wá, kí èmi kí ó lè máa gbúròó bí ẹ ti ń ṣe, pé ẹ̀yin dúró ṣinṣin nínú Ẹ̀mí kan, ẹ̀yin jùmọ̀ jìjàkadì nítorí ìgbàgbọ́ ìyìnrere, pẹ̀lú ọkàn kan.

  24. Kí ẹ má sì jẹ́ ki àwọn ọ̀tá dẹ́rùbà yin ni ohunkóhun: èyí tí í ṣe àmì tí ó dájú pé a ó pa wọ́n run, ṣùgbọ́n Ọlọ́run tìkára rẹ̀ ni yóò gbà yin là.

  25. Nítorí tí a ti fún yin ni àǹfààní, kì í ṣe láti gba Kristi gbọ́ nìkan, ṣùgbọ́n láti jìyà nítorí rẹ̀ pẹ̀lú.