Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Money

192 ẹsẹ · 40 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. A gbọdọ̀ ra omi tí à ń mu; igi wa di títà fún wa.

  2. “ ‘Wọn yóò dà fàdákà wọn sí ojú pópó, wúrà wọn yóò sì dàbí èérí fàdákà àti wúrà wọn kò ní le gbà wọ́n ní ọjọ́ ìbínú gbígbóná Olúwa. Wọn kò ní le jẹun tẹ́ ra wọn lọ́rùn tàbí kí wọn kún ikùn wọn pẹ̀lú oúnjẹ nítorí pé ó ti di ohun ìkọ̀sẹ̀ fún wọn.

  3. Pẹ̀lú ọgbọ́n àti ìmọ̀ rẹ, ìwọ tí jèrè ọrọ̀ fún ara rẹ, àti àkójọpọ̀ wúrà àti fàdákà, nínú àwọn ilé ìṣúra rẹ.

  4. Tí ẹ ń wí pé, “Nígbà wo ni oṣù tuntun yóò parí kí àwa bá à lè ta ọkà kí ọjọ́ ìsinmi kí ó lè dópin kí àwa bá à le ta jéró?” Kí a sì dín ìwọ̀n wa kù kí a gbéraga lórí iye tí a ó tà á kí a sì fi òsùwọ̀n èké yàn wọ́n jẹ,

  5. Àwọn olórí rẹ̀ ń ṣe ìdájọ́ nítorí àbẹ̀tẹ́lẹ̀, àwọn àlùfáà rẹ̀ sì ń kọ́ni nítorí owó ọ̀yà àwọn wòlíì rẹ̀ pẹ̀lú sì ń sọtẹ́lẹ̀ nítorí owó. Síbẹ̀, wọn gbẹ́kẹ̀lé Olúwa, wọ́n sì wí pé, “Nítòótọ́, Olúwa wà pẹ̀lú wa! Ibi kan kì yóò bá wa.”

  6. Mo sì wí fún wọn pé, “Bí ó bá dára ní ojú yin, ẹ fún mi ni owó ọ̀yà mi; bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ mú un lọ́wọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n wọn ọgbọ̀n owó fàdákà fún iye owó ọ̀yà mi.

  7. Bí wọ́n tí wọ inú ilé náà, wọn rí ọmọ ọwọ́ náà pẹ̀lú Maria ìyá rẹ̀, wọ́n wólẹ̀, wọ́n foríbalẹ̀ fún un. Nígbà náà ni wọ́n tú ìṣúra wọn, wọ́n sì ta Jesu lọ́rẹ: wúrà, tùràrí àti òjìá.

  8. Lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, ìwọ kì yóò jáde kúrò níbẹ̀ títí tí ìwọ yóò fi san ẹyọ owó kan tí ó kù.

  9. “Ẹ má ṣe mú wúrà tàbí fàdákà tàbí idẹ sínú àpò ìgbànú yín,

  10. Òun pinnu láti san dínárì kan fún iṣẹ́ òòjọ́ kan. Lẹ́yìn èyí ó sì rán wọn lọ sínú ọgbà àjàrà rẹ̀.

  11. Jesu sì wọ inú tẹmpili, Ó sì lé àwọn ti ń tà àti àwọn tí ń rà níbẹ̀ jáde. Ó yí tábìlì àwọn onípàṣípàrọ̀ owó dànù, àti tábìlì àwọn tí ó ń ta ẹyẹlé.

  12. Ẹ fi owó ẹyọ tí a fi ń san owó orí kan hàn mi.” Wọn mú dínárì kan wá fún un,

  13. ó sì bi wọ́n pé, “Àwòrán ta ni èyí? Àkọlé tà sì ní?”

  14. Wọ́n sì dáhùn pé, “Ti Kesari ni.” “Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé,” “Ẹ fi èyí tí í ṣe ti Kesari fún Kesari, ẹ sì fi èyí ti ṣe ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”

  15. Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí ò gba tálẹ́ǹtì kan, ó wa ihò ní ilẹ̀, ó sì bo owó ọ̀gá mọ́ ibẹ̀.

  16. Nígbà náà ìwọ ìbá kúkú fi owó mi sí ilé ìfowópamọ́ tí èmi bá dé èmi ìbá le gba owó mi pẹ̀lú èrè.

  17. Nígbà tí Judasi, ẹni tí ó fi í hàn, rí i wí pé a ti dá a lẹ́bi ikú, ó yí ọkàn rẹ̀ padà, ó sì káàánú nípa ohun tí ó ṣe. Ó sì mú ọgbọ̀n owó fàdákà tí ó gba náà wá fún àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbàgbà Júù.

  18. Nígbà náà ni Judasi da owó náà sílẹ̀ nínú tẹmpili. Ó jáde, ó sì lọ pokùnso.

  19. Wọ́n sì pe ìpàdé àwọn àgbàgbà Júù. Wọ́n sì fohùn ṣọ̀kan láti fi owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ fún àwọn olùṣọ́.

  20. Àwọn olùṣọ́ sì gba owó náà. Wọ́n sì ṣe gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti darí wọn. Ìtàn yìí sì tàn ká kíákíá láàrín àwọn Júù. Wọ́n sì gba ìtàn náà gbọ́ títí di òní yìí.

  21. O sọ fún wọn pé, wọn kò gbọdọ̀ mú ohunkóhun lọ́wọ́, àfi ọ̀pá ìtìlẹ̀ wọn. Wọn kò gbọdọ̀ mú oúnjẹ, àpò ìgbànú, tàbí owó lọ́wọ́.

  22. Ṣùgbọ́n Jesu sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ fún wọn ní oúnjẹ.” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wí fún pé, “Èyí yóò ná wa tó owó iṣẹ́ ọ̀yà oṣù mẹ́jọ, ṣe kí a lọ fi èyí ra àkàrà fún àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn yìí láti jẹ.”

  23. Jesu jókòó ní òdìkejì kọjú sí àpótí ìṣúra: ó ń wo ìjọ ènìyàn ti ń sọ owó sínú àpótí ìṣúra, ọ̀pọ̀ àwọn ọlọ́rọ̀ sì sọ púpọ̀ sí i.

  24. Ṣùgbọ́n obìnrin opó kan wà, ó sì fi ààbọ̀ owó idẹ méjì síbẹ̀, tí ì ṣe ìdá méjì owó-babà kan sínú rẹ̀.

  25. Inú wọn dùn láti gbọ́ èyí, wọ́n sì yọ̀, wọ́n sì ṣe ìlérí láti fún un ní owó. Nítorí náà ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣọ àkókò tí ó rọrùn tí òun yóò fi Jesu lé wọn lọ́wọ́.