Skip to content

Riblah

11 verses · 2 known names

A tún mọ̀ ọ́n sí: Diblath

34.4300, 36.5400 Wo lórí Google Maps

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Riblah

  1. Farao Neko sì fi sí inú ìdè ní Ribla ní ilẹ̀ Hamati, kí ó má ba à lè jẹ ọba ní Jerusalẹmu. Ó sì tan Juda jẹ fun iye ìwọ̀n ẹgbẹ̀rin tálẹ́ǹtì wúrà kan.

  2. wọ́n sì mú un. Wọ́n sì mú lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Babeli ní Ribla, níbi tí à ti ṣe ìdájọ́ lórí rẹ̀.

  3. Nebusaradani, olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ kó gbogbo wọn, ó sì mú wọn tọ ọba Babeli wá ní Ribla.

  4. Níbẹ̀ ní Ribla, ní ilẹ̀ Hamati, ọba Babeli sì kọlù wọ́n. Bẹ́ẹ̀ ni a mú Juda kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀.

  5. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ọmọ-ogun Babeli lé wọn, wọ́n bá Sedekiah láàrín aginjù Jeriko. Wọ́n mú un ní ìgbèkùn, wọ́n sì mú u tọ Nebukadnessari ọba Babeli àti Ribla ní ilẹ̀ Hamati, níbi tí wọ́n ti ṣe ìdájọ́ rẹ̀.

  6. Níbẹ̀ ní Ribla, ni ọba Babeli ti dúńbú àwọn ọmọ Sedekiah lójú rẹ̀, tí ó sì tún pa gbogbo àwọn ọlọ́lá ilẹ̀ Juda.

  7. Wọ́n sì mu ní ìgbèkùn. Wọn mú un lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Babeli, ní Ribla ní ilẹ̀ Hamati níbẹ̀ ni ó ti ṣe ìdájọ́ lórí rẹ̀.

  8. Ní Ribla ni ọba Babeli ti pa ọmọkùnrin Sedekiah lójú rẹ̀; ó sì tún pa gbogbo àwọn aláṣẹ Juda.

  9. Nebusaradani, balógun ìṣọ́ kó gbogbo wọn, ó sì mú wọn tọ ọba Babeli wá ní Ribla.

  10. Ọba Babeli sì kọlù wọ́n, ó sì pa wọ́n ní Ribla ni ilẹ̀ Hamati. Báyìí ni a mú Juda kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀.

  11. Èmi yóò na ọwọ́ mi jáde sí wọn láti mú kí ilẹ̀ náà ṣòfò, kí ó sì dahoro dé aṣálẹ̀ ìhà Dibila—ní gbogbo ibùgbé wọn. Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa.’ ”