Fò sí àkóónú

Pharaohnechoh

7 ẹsẹ

A tún mọ̀ ọ́n sí: Necho, Pharaoh-nechoh

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Pharaohnechoh

  1. Nígbà tí Josiah jẹ́ ọba, Farao Neko ọba Ejibiti gòkè lọ sí odò Eufurate láti lọ ran ọba Asiria lọ́wọ́. Ọba Josiah jáde lọ láti lọ bá a pàdé lójú ogun ṣùgbọ́n Neko dojúkọ ọ́, ó sì pa á ní Megido.

  2. Farao Neko sì fi sí inú ìdè ní Ribla ní ilẹ̀ Hamati, kí ó má ba à lè jẹ ọba ní Jerusalẹmu. Ó sì tan Juda jẹ fun iye ìwọ̀n ẹgbẹ̀rin tálẹ́ǹtì wúrà kan.

  3. Farao Neko ṣe Eliakimu ọmọ Josiah ní ọba ní ipò baba rẹ̀ Josiah. Ó sì yí orúkọ Eliakimu padà sí Jehoiakimu. Ṣùgbọ́n ó mú Jehoahasi, ó sì gbé e lọ sí Ejibiti, níbẹ̀ ni ó sì kú.

  4. Jehoiakimu sì san fún Farao Neko fàdákà àti wúrà tí ó béèrè. Láti ṣe bẹ́ẹ̀, ó bu owó òde fún ilẹ̀ náà láti san, ó fi agbára gba fàdákà àti wúrà láti ọwọ́ àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà ní ìbámu pẹ̀lú iye tí a pín.

  5. Lẹ́yìn gbogbo èyí nígbà tí Josiah ti tún ilẹ̀ náà ṣetán, Neko ọba Ejibiti gòkè lọ láti bá Karkemiṣi jà lórí odo Eufurate, Josiah sì jáde lọ láti pàdé rẹ̀ ní ibi ìjà.

  6. Josiah, kò yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ó pa ara rẹ̀ dà kí ó le bá a jà, kó sì fi etí sí ọ̀rọ̀ Neko láti ẹnu Ọlọ́run wá, ó sì wá jagun ní àfonífojì Megido.

  7. Ọba Ejibiti sì mú Eliakimu, arákùnrin Joahasi, jẹ ọba lórí Juda àti Jerusalẹmu, ó sì yí orúkọ Eliakimu padà sí Jehoiakimu, ṣùgbọ́n Neko mú Joahasi arákùnrin Eliakimu lọ sí Ejibiti.