- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Miracles Wrought Through Servants of God
Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì
Olúwa sì yí afẹ́fẹ́ náà padà di afẹ́fẹ́ líle láti apá ìwọ̀-oòrùn wá láti gbá àwọn eṣú náà kúrò ní orí ilẹ̀ Ejibiti lọ sínú Òkun Pupa. Bẹ́ẹ̀ ni ẹyọ eṣú kan kò ṣẹ́kù sí orí ilẹ̀ Ejibiti.
Nígbà náà ni Mose gbé ọwọ́ rẹ sókè sí ojú ọ̀run, òkùnkùn biribiri sì bo gbogbo ilẹ̀ Ejibiti fún ọjọ́ mẹ́ta. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Israẹli ní ìmọ́lẹ̀ ní ibi tí wọn ń gbé.
Ní ọ̀gànjọ́ òru Olúwa kọlu gbogbo àwọn àkọ́bí ilẹ̀ Ejibiti, láti orí àkọ́bí. Farao tí ó wà ní orí ìtẹ́ títí dé orí àkọ́bí ẹlẹ́wọ̀n tí ó wà nínú túbú àti àkọ́bí ẹran ọ̀sìn pẹ̀lú.
Nígbà náà ni Mose na ọwọ́ rẹ̀ sí orí Òkun, ni gbogbo òru náà ni Olúwa fi lé òkun sẹ́yìn pẹ̀lú ìjì líle láti ìlà-oòrùn wá, ó sì sọ ọ́ di ìyàngbẹ ilẹ̀. Omi òkun sì pínyà,
àwọn ọmọ Israẹli sì la ìyàngbẹ ilẹ̀ kọjá nínú òkun pẹ̀lú ògiri omi ní ọ̀tún àti òsì.
Olúwa sì wí fún Mose pé, “Na ọwọ́ rẹ sí orí òkun kí omi òkun lè ya padà sórí àwọn ará Ejibiti, kẹ̀kẹ́ ogun wọn àti sórí ẹlẹ́ṣin wọn.”
Mose sì na ọwọ́ rẹ̀ sí orí òkun, òkun sì padà bọ́ sí ipò rẹ̀ nígbà ti ilẹ̀ mọ́. Àwọn ará Ejibiti ń sá fún omi òkun, Olúwa sì gbá wọn sínú òkun.
Omi òkun sì ya padà, ó sì bo kẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn ẹlẹ́ṣin: àní, gbogbo ọmọ-ogun Farao tiwọn wọ inú òkun tọ àwọn ọmọ Israẹli lọ kò sí ọ̀kan nínú wọn tí ó yè.
Mose sì ké pe Olúwa, Olúwa sì fi igi kan hàn án, ó sì sọ igi náà sínú omi, omi náà sì dùn. Níbẹ̀ ni Olúwa ti gbé ìlànà àti òfin kalẹ̀ fún wọn, níbẹ̀ ni ó sì ti dán wọn wò.
Èmi yóò dúró ni ibẹ̀ dè ọ ni orí àpáta ni Horebu. Ìwọ ó sì lu àpáta, omi yóò sì jáde nínú rẹ̀ fún àwọn ènìyàn láti mu.” Mose sì ṣe bẹ́ẹ̀ ni iwájú àwọn àgbàgbà Israẹli.
Níwọ́n ìgbà tí Mose bá gbé apá rẹ̀ sókè, Israẹli n borí ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá sì rẹ apá rẹ̀ sílẹ̀, Amaleki a sì borí.
Ṣùgbọ́n apá ń ro Mose, wọ́n mú òkúta, wọ́n sì fi sí abẹ́ rẹ̀, ó sì jókòó lé òkúta náà; Aaroni àti Huri sì mu ní apá rẹ̀, ọ̀kan ní apá ọ̀tún àti èkejì ni apá òsì; apá rẹ̀ méjèèjì sì dúró gangan títí di ìgbà ti oòrùn wọ.
Joṣua sì fi ojú idà ṣẹ́gun àwọn ará Amaleki.
Nígbà náà ni Mose wí pé, “Báyìí ni ẹ ó ṣe mọ̀ pé Olúwa ló rán mi láti ṣe gbogbo iṣẹ́ wọ̀nyí àti pé kì í ṣe ìfẹ́ inú mi ni àwọn ohun tí mò ń ṣe.
Bí àwọn ènìyàn yìí bá kú bí gbogbo ènìyàn ti ń kú, bí ìrírí wọn kò bá sì yàtọ̀ sí ti àwọn ènìyàn yòókù, a jẹ́ pé kì í ṣe Olúwa ló rán mi.
Ṣùgbọ́n bí Olúwa bá ṣe ohun tuntun, tí ilẹ̀ sì la ẹnu, tó gbé wọn mì, àwọn pẹ̀lú gbogbo ohun tí wọ́n ní, tí wọ́n sì wọ inú ibojì wọn lọ láààyè, nígbà náà ni ẹ̀yin ó mọ̀ pé àwọn ènìyàn yìí ti kẹ́gàn Olúwa.”
Bí ó sì ṣe parí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ilẹ̀ pín sí méjì nísàlẹ̀ wọn,
ilẹ̀ sì lanu ó sì gbé wọn mì pẹ̀lú gbogbo ará ilé wọn àti àwọn ènìyàn Kora àti gbogbo ohun tí wọ́n ní.
Nígbà náà ni Mose gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè ó sì fi ọ̀pá ọwọ́ rẹ̀ lu àpáta lẹ́ẹ̀méjì. Omi sì tú jáde, gbogbo ìjọ ènìyàn àti àwọn ẹran ọ̀sìn wọn sì mu.
Olúwa sọ fún Mose pé, “Rọ ejò, a ó sì gbé e kọ́ sókè lórí igi, ẹni tí ejò bá ti gé jẹ lè wò ó yóò sì yè.”
Nígbà náà ni Mose sì rọ ejò onírin ó sì gbé e kọ́ sórí igi, bí ejò bá sì bu ẹnikẹ́ni jẹ bí ó bá ti wò ó yóò sì yè.
Èyí ni ẹ̀yin yóò fi mọ̀ pé Ọlọ́run alààyè wà ní àárín yín àti pé dájúdájú yóò lé àwọn ará Kenaani, àwọn ará Hiti, Hifi, Peresi, Girgaṣi, Amori àti Jebusi jáde níwájú u yín.
Àpótí májẹ̀mú Olúwa gbogbo ayé ń gòkè lọ sí Jordani ṣáájú u yín.
Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ẹ mú ọkùnrin méjìlá nínú àwọn ẹ̀yà Israẹli, ẹnìkan nínú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan.
Bí àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí Olúwa, Olúwa gbogbo ayé bá ti ẹsẹ̀ bọ odò Jordani, omi tí ń ti òkè sàn wá yóò gé kúrò yóò sì gbá jọ bí òkìtì kan.”