Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Miracles Wrought Through Servants of God

158 ẹsẹ · 74 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. tó bẹ́ẹ̀ tí a fi ń mú aṣọ àti aṣọ ìnuwọ́ rẹ̀ tọ àwọn ọlọkùnrùn lọ, ààrùn sì fi wọ́n sílẹ̀, àwọn ẹ̀mí búburú sì jáde kúrò lára wọn.

  2. Nígbà tí Paulu sì sọ̀kalẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ tì i, ó sì gbé e mọ́ra, ó ní, “Ẹ má ṣe yọ ara yín lẹ́nu; nítorí tí òun wà láààyè.”

  3. Nígbà tí ó sì tún gòkè lọ, ó sì jẹ oúnjẹ Olúwa, ó sì sọ̀rọ̀ pẹ́ títí ó fi di àfẹ̀mọ́júmọ́, nígbà náà ni ó sì lọ.

  4. Wọ́n sì mú ọmọkùnrin náà lọ sílẹ̀ láààyè, inú gbogbo wọn sì dùn lọ́pọ̀lọ́pọ̀.

  5. Òun sì gbọn ẹranko náà sínú iná ohunkóhun kan kò sì ṣe é.

  6. Ó sì ṣe, baba Pubiliu dùbúlẹ̀ àìsàn ibà àti ìgbẹ́-ọ̀rìn; ẹni tí Paulu wọlé tọ̀ lọ, tí ó sì gbàdúrà fún, nígbà tí ó sì fi ọwọ́ lé e, ó sì mú un láradá.

  7. Ènìyàn bí àwa ni Elijah, ó gbàdúrà gidigidi pé kí òjò kí ó má ṣe rọ̀, òjò kò sì rọ̀ sórí ilẹ̀ fún ọdún mẹ́ta òun oṣù mẹ́fà.

  8. Ó sì tún gbàdúrà, ọ̀run sì tún rọ̀jò, ilẹ̀ sì so èso rẹ̀ jáde.