Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Minister (1)

256 ẹsẹ · 2 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ago omi tútù fún ọ̀kan nínú àwọn onírẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí mu nítorí tí ó jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn mi, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, kò ní pàdánù èrè rẹ̀.”

  2. Ẹnikẹ́ni tí kò bá sì gbà yín, tí kò sì gbọ́rọ̀ yín, nígbà tí ẹ̀yin bá jáde kúrò níbẹ̀, ẹ gbọn eruku ẹsẹ̀ yín síbẹ̀ fún ẹ̀rí fún wọn.”

  3. Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Olúwa sì yan méjìléláàádọ́rin ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn pẹ̀lú, ó sì rán wọn ní méjì méjì lọ ṣáájú rẹ̀, sí gbogbo ìlú àti ibi tí òun tìkára rẹ̀ yóò sì dé.

  4. Ó sì wí fún wọn pé, “Ìkórè pọ̀, ṣùgbọ́n àwọn alágbàṣe kò tó nǹkan, nítorí náà ẹ bẹ Olúwa ìkórè, kí ó lè rán àwọn alágbàṣe sínú ìkórè rẹ̀.

  5. Ẹ mú ọ̀nà yín pọ̀n: sá wò ó, èmi rán yín lọ bí ọ̀dọ́-àgùntàn sáàrín ìkookò.

  6. Ẹ má ṣe mú àpò, ẹ má ṣe mú àpamọ́wọ́, tàbí bàtà: ẹ má sì ṣe kí ẹnikẹ́ni lọ́nà.

  7. “Ní ilékílé tí ẹ̀yin bá wọ̀, kí ẹ kọ́ wí pé, ‘Àlàáfíà fún ilé yìí!’

  8. Bí ọmọ àlàáfíà bá sì wà níbẹ̀, àlàáfíà yín yóò bà lé e: ṣùgbọ́n bí kò bá sí, yóò tún padà sọ́dọ̀ yín.

  9. Ẹ dúró sínú ilé náà, kí ẹ máa jẹ, kí ẹ sì máa mu ohunkóhun tí wọ́n bá fi fún yín, nítorí ọ̀yà alágbàṣe tọ́ sí i. Ẹ má ṣe lọ láti ilé dé ilé.

  10. “Ìlúkílùú tí ẹ̀yin bá wọ̀, tí wọ́n bá sì gbà yín, ẹ jẹ ohunkóhun tí a bá gbé ka iwájú yín.

  11. Ẹ sì mú àwọn aláìsàn tí ń bẹ nínú rẹ̀ láradá, kí ẹ sì wí fún wọn pé, ‘Ìjọba Ọlọ́run kù sí dẹ̀dẹ̀ sí yín!’

  12. Ṣùgbọ́n ní ìlúkílùú tí ẹ̀yin bá sì wọ̀, tí wọn kò bá sì gbà yín, nígbà tí ẹ̀yin bá sì jáde ní ìgboro ìlú náà, kí ẹ̀yin sì wí pé,

  13. ‘Eruku ìlú yín tí ó kù sí wa lẹ́sẹ̀, a gbọ̀n ọ́n sílẹ̀ fún yín! Ṣùgbọ́n ẹ mọ èyí pé, ìjọba Ọlọ́run kù sí dẹ̀dẹ̀.’

  14. Ṣùgbọ́n mo wí fún yín, yóò sàn fún Sodomu ní ọjọ́ náà, ju fún ìlú náà lọ.

  15. “Ègbé ni fún ìwọ, Korasini! Ègbé ni fún ìwọ Betisaida! Nítorí ìbá ṣe pé a ti ṣe iṣẹ́ agbára tí a ṣe nínú yín, ní Tire àti Sidoni, wọn ìbá ti ronúpìwàdà lọ́jọ́ pípẹ́ sẹ́yìn, wọn ìbá sì jókòó nínú aṣọ ọ̀fọ̀ àti nínú eérú.

  16. Ṣùgbọ́n yóò sàn fún Tire àti Sidoni nígbà ìdájọ́ jù fún yín lọ.

  17. Àti ìwọ, Kapernaumu, a ó ha gbé ọ ga dé òkè ọ̀run? A ó rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ dé isà òkú.

  18. “Ẹni tí ó bá gbọ́ tiyín, ó gbọ́ tèmi. Ẹni tí ó bá sì kọ̀ yín, ó kọ̀ mi. Ẹni tí ó bá sì kọ̀ mi, ó kọ ẹni tí ó rán mi.”

  19. Ẹ máa tẹ̀lé àpẹẹrẹ mi, gẹ́gẹ́ bí èmi náà ti ń tẹ̀lé àpẹẹrẹ Kristi.

  20. Èmí yìn yín fún rírántí mi nínú ohun gbogbo àti fún dídi gbogbo ẹ̀kọ́ tí mo kọ́ ọ yín mú ṣinṣin gẹ́gẹ́ bí mo ṣe fi lélẹ̀ fún un yín.

  21. Ǹjẹ́ mo bẹ̀ yín ará, ẹ ṣá mọ ilé Stefana pé, àwọn ni ẹni àkọ́kọ́ tó gba Jesu ní Akaia, àti pé, wọn sì tí fi ará wọn fún iṣẹ́ ìránṣẹ́ àwọn ènìyàn mímọ́.

  22. Kí ẹ̀yin tẹríba fún irú àwọn báwọ̀nyí, àti fún olúkúlùkù olùbáṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú wa tí ó sì ń ṣe làálàá.

  23. Ará, ẹ jùmọ̀ ṣe àfarawé mi, ẹ ṣe àkíyèsí àwọn tí ń rìn bẹ́ẹ̀, àní bí ẹ ti ní wa fún àpẹẹrẹ.

  24. Aristarku, ẹlẹgbẹ́ mí nínú túbú kí i yín, àti Marku, ọmọ arábìnrin Barnaba. (Nípasẹ̀ ẹni tí ẹ̀yin ti gba àṣẹ; bí ó bá sì wá sí ọ̀dọ̀ yín, ẹ gbà á.)

  25. Ẹ̀yin ará, ẹ fi ọlá fún àwọn olórí tí ń ṣe iṣẹ́ àṣekára láàrín yín tí wọn ń kìlọ̀ fún yín nínú Olúwa.