Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Minister (1)

256 ẹsẹ · 2 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nígbà náà ni Mose kọ orin yìí kalẹ̀ ní ọjọ́ náà ó sì kọ ọ́ sí Israẹli.

  2. Olúwa sì fún Joṣua ọmọ Nuni ní àṣẹ yìí: “Jẹ́ alágbára àti onígboyà, nítorí ìwọ yóò mú Israẹli wá sí ilẹ̀ tí mo ṣèlérí fún wọn lórí ìbúra, èmi fúnra à mi yóò sì wà pẹ̀lú rẹ.”

  3. Lẹ́yìn ikú u Mose ìránṣẹ́ Olúwa, Olúwa sọ fún Joṣua ọmọ Nuni, olùrànlọ́wọ́ ọ Mose,

  4. “Mose ìránṣẹ́ mi ti kú. Nísinsin yìí, ìwọ àti gbogbo àwọn ènìyàn wọ̀nyí, ẹ múra láti kọjá odò Jordani lọ sí ilẹ̀ tí Èmi ó fi fún wọn fún àwọn ará Israẹli.

  5. Èmi yóò fún un yín ní gbogbo ibi tí ẹ bá fi ẹsẹ̀ ẹ yín tẹ̀, gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe ìlérí fún Mose.

  6. Ilẹ̀ ẹ yín yóò fẹ̀ láti aginjù Lebanoni, àti láti odò ńlá, ti Eufurate—gbogbo orílẹ̀-èdè Hiti títí ó fi dé Òkun Ńlá ní ìwọ̀-oòrùn.

  7. Kì yóò sí ẹnikẹ́ni tí yóò le è dúró níwájú rẹ ní ọjọ́ ayé è rẹ gbogbo. Bí mo ti wà pẹ̀lú u Mose, bẹ́ẹ̀ ni Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ, Èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Èmi kì yóò kọ̀ ọ́.

  8. “Jẹ́ alágbára kí o sì mú àyà le, nítorí ìwọ ni yóò ṣe amọ̀nà àwọn ènìyàn wọ̀nyí, láti lè jogún ilẹ̀ tí mo ti búra fún àwọn baba ńlá a wọn láti fi fún wọn.

  9. Jẹ́ alágbára, kí o sì mú àyà le gidigidi. Kí o sì ṣọ́ra láti pa gbogbo òfin tí Mose ìránṣẹ́ mi fún ọ mọ́, má ṣe yà kúrò nínú u rẹ̀ sí ọ̀tún tàbí sí òsì, kí ìwọ kí ó lè ṣe rere níbikíbi tí ìwọ bá ń lọ.

  10. Má ṣe jẹ́ kí ìwé òfin yìí kúrò ní ẹnu rẹ, máa ṣe àṣàrò nínú u rẹ̀ ní ọ̀sán àti ní òru, kí ìwọ kí ó lè ṣọ́ra láti ṣe gbogbo nǹkan tí a kọ sí inú u rẹ̀. Nígbà náà ni yóò dára fún ọ, ìwọ yóò sì ní àṣeyọrí.

  11. Èmi kò ha ti pàṣẹ fún ọ bí? Jẹ́ alágbára kí o sì mú àyà le. Má ṣe bẹ̀rù, má sì ṣe rẹ̀wẹ̀sì, nítorí pé Olúwa à rẹ yóò wà pẹ̀lú rẹ ní ibikíbi tí ìwọ bá ń lọ.”

  12. Ó sì tún sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, lọ ni ìsinsin yìí bá mi sọ ọ̀rọ̀ mi fún ilé Israẹli.

  13. “Nítorí ètè àlùfáà ní òye láti máa pa ìmọ̀ mọ́, kí àwọn ènìyàn lè máa wá ìtọ́ni ni ẹnu rẹ̀: nítorí òun ni ìránṣẹ́ Olúwa àwọn ọmọ-ogun.

  14. Àwọn méjèèjìlá wọ̀nyí ni Jesu ran, ó sì pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ má ṣe lọ sì ọ̀nà àwọn kèfèrí, ẹ má ṣe wọ̀ ìlú àwọn ará Samaria.

  15. Ẹ kúkú tọ̀ àwọn àgùntàn ilé Israẹli tí ó nù lọ.

  16. Bí ẹ̀yin ti ń lọ, ẹ máa wàásù yìí wí pé, ‘Ìjọba ọ̀run kù sí dẹ̀dẹ̀.’

  17. Ẹ máa ṣe ìwòsàn fún àwọn aláìsàn, ẹ si jí àwọn òkú dìde, ẹ sọ àwọn adẹ́tẹ̀ di mímọ́, kí ẹ sì máa lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde. Ọ̀fẹ́ ni ẹ̀yin gbà á, ọ̀fẹ́ ni kí ẹ fi fún ni.

  18. “Ẹ má ṣe mú wúrà tàbí fàdákà tàbí idẹ sínú àpò ìgbànú yín,

  19. ẹ má ṣe mú àpò fún ìrìnàjò yín, kí ẹ má ṣe mú ẹ̀wù méjì, tàbí bàtà, tàbí ọ̀pá; oúnjẹ oníṣẹ́ yẹ fún un.

  20. Ìlúkílùú tàbí ìletòkíletò tí ẹ̀yin bá wọ̀, ẹ wá ẹni ti ó bá yẹ níbẹ̀ rí, níbẹ̀ ni kí ẹ sì gbé nínú ilé rẹ̀ títí tí ẹ̀yin yóò fi kúrò níbẹ̀.

  21. Nígbà tí ẹ̀yin bá sì wọ ilé kan, ẹ kí i wọn.

  22. Bí ilé náà bá sì yẹ, kí àlàáfíà yín kí ó bà sórí rẹ̀; ṣùgbọ́n bí kò bá yẹ, kí àlàáfíà yín kí ó padà sọ́dọ̀ yín.

  23. Bí ẹnikẹ́ni tí kò bá sì gbà yín, tàbí tí kò gba ọ̀rọ̀ yín, ẹ gbọn eruku ẹ̀ṣẹ̀ yín sílẹ̀ tí ẹ bá ń kúrò ní ilé tàbí ìlú náà.

  24. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, yóò sàn fún ìlú Sodomu àti Gomorra ní ọjọ́ ìdájọ́ ju àwọn ìlú náà lọ.

  25. “Mò ń rán yín lọ gẹ́gẹ́ bí àgùntàn sáàrín ìkookò. Nítorí náà, kí ẹ ní ìṣọ́ra bí ejò, kí ẹ sì ṣe onírẹ̀lẹ̀ bí àdàbà.