Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Levites

186 ẹsẹ · 17 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Àwọn ọmọ Lefi. Àwọn ọmọ Jeṣua àti Kadmieli (ti ìdílé Hodafiah) jẹ́ mẹ́rìnléláàádọ́rin (74).

  2. Àwọn akọrin. Àwọn ọmọ Asafu jẹ́ méjìdínláàádóje (128).

  3. Àwọn aṣọ́bodè. Àwọn ará Ṣallumu, Ateri, Talmoni, Akkubu, Hatita àti Ṣobai jẹ́ mọ́kàndínlógóje (139).

  4. Àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili. Àwọn ọmọ. Siha, Hasufa, Tabboati,

  5. Kerosi, Siaha, Padoni,

  6. Lebana, Hagaba, Akkubu,

  7. Hagabu, Ṣalmai, Hanani,

  8. Giddeli, Gahari, Reaiah,

  9. Resini, Nekoda, Gassamu,

  10. Ussa, Pasea, Besai,

  11. Asna, Mehuni, Nefisimu,

  12. Bakbu, Hakufa, Harhuri.

  13. Basluti, Mehida, Harṣa,

  14. Barkosi, Sisera, Tema,

  15. Nesia àti Hatifa.

  16. Àwọn ọmọ àwọn ìránṣẹ́ Solomoni. Àwọn ọmọ Sotai, Sofereti, Peruda,

  17. Jaala, Darkoni, Giddeli,

  18. Ṣefatia, àwọn ọmọ Hattili, Pokereti ti Haṣebaimu àti àwọn ọmọ Ami.

  19. Àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili àti àwọn ọmọ àwọn ìránṣẹ́ Solomoni jẹ́ irinwó ó dín mẹ́jọ (392).

  20. Àwọn wọ̀nyí gòkè wá láti àwọn ìlú ti Teli-Mela, Teli-Harṣa, Kerubu, Addoni àti Immeri, ṣùgbọ́n wọn kò lè sọ pẹ̀lú ìdánilójú pé ìdílé àwọn wá láti ara ìran ẹ̀yà Israẹli.

  21. Àwọn ọmọ Delaiah, Tobiah àti Nekoda jẹ́ àádọ́ta lé lẹ́gbẹ̀ta ó lé méjì (652).

  22. Àti nínú àwọn ọmọ àwọn àlùfáà. Àwọn ọmọ: Hobaiah, Hakosi àti Barsillai (ọkùnrin tí ó fẹ́ ọmọbìnrin Barsillai ará Gileadi a sì ń fi orúkọ náà pè é).

  23. Àwọn wọ̀nyí wá ìwé ìrántí ìdílé wọn, ṣùgbọ́n wọn kò rí i, bẹ́ẹ̀ ni a kò kà wọ́n kún ara àlùfáà nítorí, a kà wọ́n sí aláìmọ́.

  24. Baálẹ̀ pa á láṣẹ fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ jẹ nínú oúnjẹ mímọ́ jùlọ títí tí àlùfáà kan yóò fi ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ pẹ̀lú Urimu àti Tumimu.

  25. Nígbà náà ni mo pe Elieseri, Arieli, Ṣemaiah, Elnatani, Jaribi, Elnatani, Natani, Sekariah, àti Meṣullamu, tí wọ́n jẹ́ olórí, àti Joiaribu àti Elnatani tí wọ́n jẹ́ onímọ̀ ìjìnlẹ̀,