Skip to content

Kohath

29 ẹsẹ · 8 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Kohath

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Àwọn ọmọkùnrin Lefi: Gerṣoni, Kohati àti Merari.

  2. Ìwọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ Lefi gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn: Gerṣoni, Kohati àti Merari. Lefi lo ẹ̀tàdínlógóje (137) ọdún láyé.

  3. Àwọn ọmọ Kohati ni: Amramu, Isari, Hebroni àti Usieli. Kohati lo ẹ̀tàléláádóje (133) ọdún láyé.

  4. Wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ Lefi: Gerṣoni, Kohati àti Merari.

  5. Àwọn ìdílé Kohati ni: Amramu, Isari, Hebroni àti Usieli.

  6. Ti Kohati ní ìdílé Amramu, Isari, Hebroni àti Usieli, wọ̀nyí ni ìran Kohati.

  7. Àwọn ìdílé Kohati yóò pa ibùdó wọn sí ìhà gúúsù ní ẹ̀gbẹ́ àgọ́.

  8. “Ka iye àwọn ọmọ Kohati láàrín àwọn ọmọ Lefi nípa ilé baba wọn àti ìdílé wọn.

  9. “Wọ̀nyí ni iṣẹ́ ìsìn àwọn ọmọ Kohati nínú àgọ́ àjọ, láti tọ́jú àwọn ohun èlò mímọ́ jùlọ.

  10. “Lẹ́yìn tí Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ ti parí bíbo ibi mímọ́ àti gbogbo ohun èlò ibi mímọ́, nígbà tí àgọ́ bá sì ṣetán láti tẹ̀síwájú, kí àwọn ọmọ Kohati bọ́ síwájú láti gbé e, ṣùgbọ́n wọn kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan ohun mímọ́ kankan, bí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀ wọn ó kú. Àwọn ọmọ Kohati ni yóò gbé gbogbo ohun tó wà nínú àgọ́ ìpàdé.

  11. Ṣùgbọ́n Mose kò fún àwọn ọmọ Kohati ní nǹkan kan nítorí pé èjìká wọn ni wọn yóò fi ru àwọn ohun mímọ́ èyí tí ó jẹ́ ojúṣe tiwọn.

  12. Kora ọmọ Isari, ọmọ Kohati, ọmọ Lefi àwọn ọmọ Reubeni: Datani àti Abiramu, àwọn ọmọ Eliabu, àti Oni ọmọ Peleti mú ènìyàn mọ́ra.

  13. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Lefi tí a kà nínú wọn gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn: ti Gerṣoni, ìdílé àwọn ọmọ Gerṣoni; ti Kohati, ìdílé àwọn ọmọ Kohati; ti Merari, ìdílé àwọn ọmọ Merari.

  14. Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Lefi; ìdílé àwọn ọmọ Libni, ìdílé àwọn ọmọ Hebroni, ìdílé àwọn ọmọ Mahili, ìdílé àwọn ọmọ Muṣi, ìdílé àwọn ọmọ Kora. (Kohati ni baba Amramu,

  15. Ìyókù àwọn ọmọ Kohati ni a pín ìlú mẹ́wàá fún láti ara ẹ̀yà Efraimu, Dani àti ìdajì Manase.

  16. Ìyókù ìdílé Kohati tí ó jẹ́ ọmọ Lefi ní a pín ìlú fún láti ara ẹ̀yà Efraimu.

  17. Gbogbo ìlú mẹ́wẹ̀ẹ̀wá yìí àti ilẹ̀ pápá wọn ni a fi fún ìyókù ìdílé Kohati.

  18. Àwọn ọmọ Lefi: Gerṣoni, Kohati àti Merari.

  19. Àwọn ọmọ Kohati: Amramu, Isari, Hebroni, àti Usieli.

  20. Àwọn ọmọ Lefi: Gerṣoni, Kohati àti Merari.

  21. Àwọn ọmọ Kohati: Amramu, Isari, Hebroni àti Usieli.

  22. Àwọn ìran ọmọ Kohati: Amminadabu ọmọkùnrin rẹ̀, Kora ọmọkùnrin rẹ̀, Asiri ọmọkùnrin rẹ̀.

  23. ọmọ Isari, ọmọ Kohati, ọmọ Lefi, ọmọ Israẹli;

  24. Ìyókù àwọn ìran ọmọ Kohati ní a pín ìlú mẹ́wàá fún láti àwọn ìdílé ní ti ààbọ̀ ẹ̀yà Manase.

  25. Lára àwọn ìdílé Kohati ni a fún ní ìlú láti ẹ̀yà Efraimu gẹ́gẹ́ bí ìlú agbègbè wọn.