Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Levites

186 ẹsẹ · 17 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili àti àwọn ọmọ ìránṣẹ́ Solomoni jẹ́ irinwó ó dín mẹ́jọ (392).

  2. Àwọn wọ̀nyí gòkè wá láti àwọn ìlú ti Teli-Mela, Teli-Harṣa, Kerubu, Addoni àti Immeri, ṣùgbọ́n wọn kò lè sọ pẹ̀lú ìdánilójú pé ìdílé àwọn wá láti ara ìran ẹ̀yà Israẹli.

  3. Àwọn ọmọ Delaiah, Tobiah àti Nekoda jẹ́ òjìlélẹ́gbẹ̀ta ó lé méjì (642).

  4. Lára àwọn àlùfáà ni: àwọn ọmọ Hobaiah, Hakosi àti Barsillai (ọkùnrin tí ó fẹ́ ọmọbìnrin Barsillai ará Gileadi, ẹni tí a ń fi orúkọ yìí pè).

  5. Àwọn wọ̀nyí wá àkọsílẹ̀ orúkọ ìran wọn, ṣùgbọ́n wọn kò rí í níbẹ̀, fún ìdí èyí, a yọ wọ́n kúrò nínú àwọn tí ń ṣiṣẹ́ àlùfáà gẹ́gẹ́ bí aláìmọ́.

  6. Baálẹ̀ sọ fún wọn nítorí náà pé wọn kò gbọdọ̀ kópa nínú jíjẹ oúnjẹ mímọ́ títí tí àlùfáà tí yóò wá tí ń ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ pẹ̀lú Urimu àti Tumimu yóò fi dé.

  7. Gbogbo ìjọ ènìyàn náà jẹ́ ẹgbàá mọ́kànlélógún ó lé òjìdínnírinwó (42,360),

  8. yàtọ̀ sí àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin tí wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀ta dín lẹ́gbàárin ó dín ẹ̀tàlélọ́gọ́ta (7,337); wọ́n sì tún ní àwọn akọrin ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n jẹ́ òjìlúgba ó lé márùn-ún (245).

  9. Ẹṣin wọn jẹ́ ọ̀tàdínlẹ́gbẹ̀rin ó dín mẹ́rin (736), ìbákasẹ wọn jẹ́ òjìlúgba ó dín márùn-ún (245);

  10. ìbákasẹ wọn jẹ́ òjìlénírinwó ó dín márùn-ún (435); kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀rìnlélọ́gbọ̀n ó dín ọgọ́rin (6,720).

  11. Díẹ̀ lára àwọn olórí ìdílé náà kópa nínú ṣíṣe iṣẹ́ náà. Baálẹ̀ fún ilé ìṣúra ní ẹgbẹ̀rún (1,000) dariki wúrà, àádọ́ta àwo koto àti ọ̀rìndínlẹ́gbẹ̀ta lé mẹ́wàá (530) ẹ̀wù fún àwọn àlùfáà.

  12. Díẹ̀ lára àwọn olórí ìdílé fún ilé ìṣúra ní ogún ẹgbẹ̀rún (20,000) dariki wúrà àti ẹgbọ̀kànlá (2,200) mina fàdákà.

  13. Àròpọ̀ gbogbo ohun tí àwọn ènìyàn tókù fi sílẹ̀ jẹ́ ogún ẹgbẹ̀rún (20,000) dariki wúrà, ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) mina fàdákà àti ẹẹ́tàdínláàdọ́rin ẹ̀wù fún àwọn àlùfáà.

  14. Àwọn àlùfáà, àwọn Lefi, àwọn aṣọ́bodè, àwọn akọrin, àwọn ènìyàn díẹ̀, àwọn ìránṣẹ́ ilé Ọlọ́run, àti gbogbo ènìyàn Israẹli wà ní ìlú wọn. Nígbà tí ó di oṣù keje, tí àwọn ọmọ Israẹli sì ti wà nínú ìlú u wọn,

  15. Àwọn ọmọ Lefi: Jeṣua ọmọ Asaniah, Binnui ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Henadadi, Kadmieli,

  16. àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn: Ṣebaniah, Hodiah, Kelita, Pelaiah, Hanani,

  17. Mika, Rehobu, Haṣabiah,

  18. Sakkuri, Ṣerebiah, Ṣebaniah,

  19. Hodiah, Bani àti Beninu.

  20. Àwọn olórí àwọn ènìyàn: Paroṣi, Pahati-Moabu, Elamu, Sattu, Bani,

  21. Bunni, Asgadi, Bebai.

  22. Adonijah, Bigfai, Adini,

  23. Ateri, Hesekiah, Assuri,

  24. Hodiah, Haṣumu, Besai,

  25. Harifu, Anatoti, Nebai,