Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Levites

186 ẹsẹ · 17 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. mo sì rán wọn tí àwọn ti àṣẹ sí ọ̀dọ̀ Iddo, tí ó jẹ́ olórí ní ibi ti a ń pè ni Kasifia, mo sì sọ fún wọn ohun tí wọn yóò wí fun Iddo àti àwọn Lefi arákùnrin rẹ̀, tí wọ́n jẹ́ òṣìṣẹ́ tẹmpili ní Kasifia pé, kí wọn mú àwọn ìránṣẹ́ wá sí ọ̀dọ̀ wa fún ilé Ọlọ́run wa.

  2. Nítorí ọwọ́ àánú Ọlọ́run wa wà lára wa, wọ́n sì mú Ṣerebiah wá fún wa, ẹni tí ó kún ojú òsùwọ̀n láti ìran Mahili, ọmọ Lefi, ọmọ Israẹli, àti àwọn ọmọ Ṣerebiah àti àwọn arákùnrin rẹ̀, wọ́n jẹ́ ọkùnrin méjìdínlógún.

  3. Àti Haṣabiah, pẹ̀lú Jeṣaiah láti ìran Merari, pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ àti àwọn ọmọ wọ́n jẹ́ ogún ọkùnrin.

  4. Wọ́n sì tún mú ogún lé nígba (220) àwọn òṣìṣẹ́ tẹmpili wá—àwọn ènìyàn tí Dafidi àti àwọn ìjòyè rẹ̀ gbé kalẹ̀ láti ran àwọn ọmọ Lefi lọ́wọ́. Gbogbo wọn ni a ṣe àkọsílẹ̀ orúkọ wọn.

  5. Lẹ́yìn ìgbà tí a ti ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí tán, àwọn olórí tọ̀ mí wá, wọ́n sì wí pé, “Àwọn ènìyàn Israẹli, tí ó fi mọ́ àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi, kò tì í ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò láàrín àwọn ènìyàn agbègbè tí wọ́n ń ṣe ohun ìríra bí i ti àwọn ará Kenaani, àwọn ará Hiti, àwọn ará Peresi, àwọn ará Jebusi, àwọn ará Ammoni, àwọn ará Moabu, àwọn ará Ejibiti àti ti àwọn ará Amori.

  6. Wọ́n ti fẹ́ lára àwọn ọmọbìnrin wọn fún ara wọn àti fún àwọn ọmọkùnrin wọn gẹ́gẹ́ bí aya, wọ́n ti da irú-ọmọ ìran mímọ́ pọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn ti ó wà ní àyíká wọn. Àwọn olórí àti àwọn ìjòyè ta àwọn ènìyàn tókù yọ nínú híhu ìwà àìṣòótọ́.”

  7. Lára àwọn ọmọ Lefi: Josabadi, Ṣimei, Kelaiah (èyí tí í ṣe Kelita), Petahiah, Juda àti Elieseri.

  8. Nínú àwọn akọrin: Eliaṣibu. Nínú àwọn aṣọ́nà: Ṣallumu, Telemu àti Uri.

  9. Àwọn ọmọ Lefi: àwọn ọmọ Jeṣua (láti ipasẹ̀ Kadmieli, láti ipasẹ̀ Hodafiah) jẹ́ mẹ́rìnléláàádọ́rin (74).

  10. Àwọn akọrin: àwọn ọmọ Asafu jẹ́ méjìdínláàádọ́jọ (148).

  11. Àwọn aṣọ́nà: àwọn ọmọ Ṣallumu, Ateri, Talmoni, Akkubu, Hatita, àti Ṣobai jẹ́ méjìdínlógóje (138).

  12. Àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili. Àwọn ọmọ Siha, Hasufa, Tabboati,

  13. Kerosi, Sia, Padoni,

  14. Lebana, Hagaba, Ṣalmai,

  15. Hanani, Giddeli, Gahari,

  16. Reaiah, Resini, Nekoda,

  17. Gassamu, Ussa, Pasea,

  18. Besai, Mehuni, Nefisimu,

  19. Bakbu, Hakufa, Harhuri,

  20. Basluti, Mehida, Harṣa,

  21. Barkosi, Sisera, Tema,

  22. Nesia, àti Hatifa.

  23. Àwọn ọmọ àwọn ìránṣẹ́ Solomoni: àwọn ọmọ Sotai, Sofereti; Perida,

  24. Jaala, Darkoni, Giddeli,

  25. Ṣefatia, Hattili, Pokereti-Haṣṣebaimu, àti Amoni.