Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Levites

186 ẹsẹ · 17 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. “Ka iye àwọn ọmọ Kohati láàrín àwọn ọmọ Lefi nípa ilé baba wọn àti ìdílé wọn.

  2. Ka gbogbo ọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta ọdún gbogbo àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìpàdé.

  3. Nítorí kí wọ́n lè yè, kí wọ́n má ba à kú nígbà tí wọ́n bá súnmọ́ tòsí àwọn ohun mímọ́ jùlọ: Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ ni kí ó wọ ibi mímọ́ láti pín iṣẹ́ oníkálùkù àti àwọn ohun tí wọn yóò gbé.

  4. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Kohati kò gbọdọ̀ wọlé láti wo àwọn ohun mímọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ ìṣẹ́jú kan, bí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, wọn yóò kú.”

  5. “Yọ àwọn ọmọ Lefi kúrò láàrín àwọn ọmọ Israẹli yòókù, kí o sì wẹ̀ wọ́n mọ́.

  6. Báyìí ni kí o ṣe wẹ̀ wọ́n mọ́. Wọ́n omi ìwẹ̀nùmọ́ sí wọn lára, mú kí wọn ó fá irun ara wọn, kí wọn ó fọ aṣọ wọn, kí wọn ó ba à lè wẹ ara wọn mọ́ nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀.

  7. Jẹ́ kí wọn ó mú akọ ọ̀dọ́ màlúù pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ rẹ̀ tí í ṣe ìyẹ̀fun ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò, kí ìwọ náà mú akọ ọ̀dọ́ màlúù kejì fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.

  8. Ìwọ ó sì mú àwọn ọmọ Lefi wá síwájú àgọ́ ìpàdé, kí o sì kó gbogbo àpapọ̀ ọmọ Israẹli jọ síbẹ̀ pẹ̀lú.

  9. Báyìí ni kí o mú àwọn ọmọ Lefi wá síwájú Olúwa, gbogbo ọmọ Israẹli yóò sì gbọ́wọ́ lé àwọn ọmọ Lefi lórí.

  10. Aaroni yóò sì mú àwọn ọmọ Lefi wá síwájú Olúwa gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fífì láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli wá, kí wọn lè máa ṣiṣẹ́ Olúwa.

  11. “Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Lefi bá gbé ọwọ́ wọn lé orí àwọn akọ ọmọ màlúù náà, ìwọ yóò sì fi ọ̀kan rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti èkejì fún ẹbọ sísun sí Olúwa, láti ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Lefi.

  12. Mú kí àwọn ọmọ Lefi dúró níwájú Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ kí ó sì gbé wọn kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fífì sí Olúwa.

  13. Báyìí ni ìwọ yóò ṣe ya ọmọ Lefi sọ́tọ̀, kúrò láàrín àwọn ọmọ Israẹli yòókù, àwọn ọmọ Lefi yóò sì jẹ́ tèmi.

  14. “Lẹ́yìn tí ó ti wẹ àwọn ọmọ Lefi mọ́, tí ó sì ti gbé wọn kalẹ̀ bí ẹbọ fífì nígbà náà ni kí wọn ó lọ máa ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìpàdé.

  15. Nítorí pé àwọn ni ó jẹ́ ti Èmi pátápátá nínú àwọn ọmọ Israẹli. Mo ti gbà wọ́n fún ara mi dípò àwọn àkọ́bí àní àkọ́bí ọkùnrin gbogbo Israẹli.

  16. Nítorí pé gbogbo àkọ́bí ọmọ lọ́kùnrin ní Israẹli jẹ́ tèmi, ti ènìyàn àti ti ẹranko, láti ọjọ́ tí mo ti pa gbogbo àkọ́bí ní ilẹ̀ Ejibiti ni mo ti yà wọ́n sọ́tọ̀ fún ara mi.

  17. Mo sì ti gba àwọn ọmọ Lefi dípò gbogbo àkọ́bí ọmọ ọkùnrin nínú Israẹli.

  18. Nínú Israẹli, mo fi àwọn ọmọ Lefi fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn láti máa ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìpàdé fun àwọn ọmọ Israẹli àti láti máa ṣe ètùtù fún wọn kí àjàkálẹ̀-ààrùn má ba à kọlu àwọn ọmọ Israẹli nígbà tí wọ́n bá súnmọ́ ibi mímọ́.”

  19. Mose, Aaroni àti gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli sì ṣe fún àwọn ọmọ Lefi gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

  20. Àwọn ọmọ Lefi wẹ ara wọn mọ́, wọ́n sì fọ aṣọ wọn. Aaroni sì mú wọn wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fífì níwájú Olúwa, Aaroni sì ṣe ètùtù fún wọn láti wẹ̀ wọ́n mọ́.

  21. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Lefi tí a kà nínú wọn gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn: ti Gerṣoni, ìdílé àwọn ọmọ Gerṣoni; ti Kohati, ìdílé àwọn ọmọ Kohati; ti Merari, ìdílé àwọn ọmọ Merari.

  22. Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Lefi; ìdílé àwọn ọmọ Libni, ìdílé àwọn ọmọ Hebroni, ìdílé àwọn ọmọ Mahili, ìdílé àwọn ọmọ Muṣi, ìdílé àwọn ọmọ Kora. (Kohati ni baba Amramu,

  23. orúkọ aya Amramu sì ń jẹ́ Jokebedi, ọmọbìnrin Lefi, tí ìyá rẹ̀ bí fún Lefi ní Ejibiti. Òun sì bí Aaroni, Mose, àti Miriamu arábìnrin wọn fún Amramu.

  24. Aaroni ni baba Nadabu àti Abihu, Eleasari àti Itamari.

  25. Ṣùgbọ́n Nadabu àti Abihu kú, nígbà tí wọ́n rú ẹbọ níwájú Olúwa nígbà tí wọ́n mú iná àjèjì wá.)