Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Idolatry

447 ẹsẹ · 205 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Àní nígbà tí wọ́n wà nínú ìjọba wọn, tí wọ́n ń gbádùn oore ńlá tí ìwọ fi fún wọn, ní ilẹ̀ tí ó tóbi tí ó sì lọ́ràá, wọn kò sìn ọ́ tàbí padà kúrò nínú àwọn ọ̀nà búburú wọn.

  2. “Ṣùgbọ́n wò ó, àwa jẹ́ ẹrú lónìí, àwa jẹ́ ẹrú ní ilẹ̀ tí ìwọ fún àwọn baba ńlá wa, nítorí kí wọn bá máa jẹ èso rẹ̀ àti ìre mìíràn tí ó mú jáde.

  3. Nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìkórè rẹ lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ọba tí ó fi ṣe olórí wa. Wọ́n ń ṣe àkóso lórí wa àti lórí ẹran wa bí ó ti wù wọ́n, àwa sì wà nínú ìpọ́njú ńlá.

  4. Wọ́n bí i nínú pẹ̀lú ibi gíga wọn; wọn rú owú rẹ̀ sókè nípa òrìṣà wọn.

  5. Nígbà tí Ọlọ́run gbọ́ wọn, inú bí i gidigidi; ó kọ Israẹli pátápátá.

  6. Ó kọ àgọ́ Ṣilo sílẹ̀, àgọ́ tí ó ti gbé kalẹ̀ láàrín àwọn ènìyàn.

  7. Ó rán àpótí ẹ̀rí, agbára rẹ̀ lọ sí ìgbèkùn, dídán ògo rẹ̀ lọ sí ọwọ́ àwọn ọ̀tá.

  8. Ó fi àwọn ènìyàn rẹ̀ lé idà lọ́wọ́, ó sì bínú sí àwọn ohun ìní rẹ̀.

  9. Iná run àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wọn, àwọn ọmọbìnrin wọn kò sì ní orin ìgbéyàwó:

  10. àfi àlùfáà wọn fún idà, àwọn opó wọn kò sì le è sọkún.

  11. Wọn kò pa àwọn ènìyàn run gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ fún wọn,

  12. Ṣùgbọ́n wọ́n dàpọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè, wọ́n sì gbà láti ṣe bí àṣà wọn.

  13. Wọ́n sì sin àwọn òrìṣà wọn tí ó di ìkẹ́kùn fún wọn.

  14. Wọ́n fi àwọn ọmọkùnrin wọn rú ẹbọ àti àwọn ọmọbìnrin fún òrìṣà.

  15. Wọ́n ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀, ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wọ. Wọ́n fi wọ́n rú ẹbọ sí ère Kenaani, ilẹ̀ náà sì di àìmọ́ fún ẹ̀jẹ̀.

  16. Wọ́n sì fi ìṣe wọn sọ ara wọn di aláìmọ́, wọ́n sì ṣe àgbèrè lọ pẹ̀lú iṣẹ́ wọn.

  17. Nígbà náà ni Olúwa bínú sí àwọn ènìyàn rẹ̀ ó sì kórìíra àwọn ènìyàn ìní rẹ̀

  18. Ó sì fà wọ́n lé àwọn orílẹ̀-èdè lọ́wọ́, àwọn ọ̀tá wọn sì jẹ ọba lórí wọn.

  19. Àwọn ọ̀tá wọn sì ń pọ́n wọn lójú wọn sì mú wọn sìn lábẹ́ àṣẹ wọn.

  20. Fàdákà òun wúrà ni èrè àwọn aláìkọlà, iṣẹ́ ọwọ́ ènìyàn ni.

  21. Wọ́n ní ẹnu, ṣùgbọ́n wọn kò le sọ̀rọ̀, wọ́n ní ojú, ṣùgbọ́n wọn kò fi ríran.

  22. Wọ́n ní etí, ṣùgbọ́n wọn kò fi gbọ́rọ̀: wọ́n ní imú, ṣùgbọ́n wọn kò fi gbóòórùn.

  23. Wọ́n ní ọwọ́, ṣùgbọ́n wọn kò lò ó, wọ́n ní ẹsẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kò rìn; bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sọ̀rọ̀ nínú òfin wọn.

  24. Àwọn tí ń ṣe wọ́n dàbí wọn; gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni olúkúlùkù ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé wọn.

  25. Fàdákà òun wúrà ni èrè àwọn aláìkọlà, iṣẹ́ ọwọ́ ènìyàn ni.