Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Idolatry

447 ẹsẹ · 205 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Wọ́n kọ̀ gbogbo òfin Olúwa Ọlọ́run wọn sílẹ̀, wọ́n sì ṣe òrìṣà méjì fún ara wọn, wọ́n sì gbẹ́ ẹ ọ̀kan ní ère ẹgbọrọ màlúù, àti ọ̀kan ní ère òrìṣà Aṣerah. Wọ́n sì tẹrí wọn ba sí gbogbo ogun ọ̀run, wọ́n sì sin Baali.

  2. Wọ́n sì fi àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wọn rú ẹbọ nínú iná. Wọ́n sì ń fọ àfọ̀ṣẹ, wọ́n sì ń ṣe àlúpàyídà wọ́n sì ta ara wọn láti ṣe ohun búburú níwájú Olúwa, wọ́n sì mú un bínú.

  3. Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa sì bínú gidigidi pẹ̀lú Israẹli ó sì mú wọn kúrò níwájú rẹ̀. Ẹ̀yà Juda nìkan ṣoṣo ni ó kù,

  4. àti pẹ̀lú, Juda kò pa òfin Olúwa Ọlọ́run wọn mọ́. Wọ́n tẹ̀lé ìhùwàsí àwọn Israẹli tí wọ́n ṣe.

  5. Nítorí náà Olúwa kọ gbogbo àwọn ènìyàn Israẹli; ó sì jẹ wọ́n ní yà. Ó sì fi wọ́n lé ọwọ́ àwọn olè títí tí ó fi ta wọ́n nù kúrò níwájú rẹ̀.

  6. Nígbà tí ó ta Israẹli kúrò láti ìdílé Dafidi, wọ́n sì mú Jeroboamu ọmọ Nebati jẹ ọba wọn. Jeroboamu sì mú kí àwọn ọmọ Israẹli yípadà kúrò ní títẹ̀lé Olúwa, ó sí mú kí wọn dẹ́ṣẹ̀ ńlá.

  7. Àwọn ọmọ Israẹli forítì í nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu kò sì yí padà kúrò lọ́dọ̀ wọn,

  8. títí tí Olúwa fi mú wọn kúrò níwájú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti paláṣẹ láti ọ̀dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ wòlíì. Bẹ́ẹ̀ ni a kó gbogbo ènìyàn Israẹli kúrò ní ilẹ̀ wọn lọ sí ìgbèkùn ni Asiria, títí di òní yìí.

  9. Ó sì kọ́ pẹpẹ nínú ilé tí a kọ́ fún Olúwa, èyí tí Olúwa ti sọ pé, “Ní Jerusalẹmu ni èmi yóò kọ orúkọ mi sí.”

  10. Ní àgbàlá méjèèjì ilé Olúwa, ó sì kọ́ pẹpẹ fún gbogbo àwọn ìrúbọ nínú ilé, ṣe iṣẹ́ àkíyèsí àfọ̀ṣẹ, ó sì béèrè lọ́wọ́ àwọn òkú àti àwọn oṣó. Ó sì ṣe ọ̀pọ̀ búburú ní ojú Olúwa, ó sì mú un bínú.

  11. Ó fi àwọn ọmọ ara rẹ̀ rú ẹbọ nínú iná, ó ń ṣe àkíyèsí àfọ̀ṣẹ, ó sì ń lo àlúpàyídà, ó sì ń bá àwọn òku àti oṣó lò. Ó ṣe ọ̀pọ̀ ohun búburú ní ojú Olúwa láti mú un bínú.

  12. Ó sì gbé ère fínfín òrìṣà Aṣerah tí ó ti ṣe, ó sì gbé e sínú ilé Olúwa, èyí tí Olúwa ti sọ fún Dafidi àti sí ọmọ rẹ̀ Solomoni, “Nínú ilé Olúwa yìí àti ní Jerusalẹmu, tí èmi ti yàn jáde lára gbogbo ẹ̀yà Israẹli, èmi yóò kọ orúkọ mi títí láéláé.

  13. Ó sì rìn ní ọ̀nà àwọn ọba Israẹli ó sì ṣe ère dídá fún ìsìn Baali

  14. Ó sì sun ẹbọ ní àfonífojì Hinnomu, ó sì sun àwọn ọmọ rẹ̀ nínú iná, gẹ́gẹ́ bí ohun ìríra àwọn orílẹ̀-èdè tí Olúwa lé jáde níwájú àwọn ọmọ Israẹli

  15. Ó sì rú ẹbọ, ó sì sun tùràrí ní ibi gíga wọ́n nì lórí òkè kékeré àti lábẹ́ gbogbo igi tútù.

  16. Ní àkókò ìpọ́njú rẹ̀ ọba Ahasi sì di aláìṣòótọ́ sí Olúwa.

  17. Ó sì rú ẹbọ sí òrìṣà àwọn Damasku, ẹni tí ó ṣẹ́gun wọn, nítorí ó rò wí pé, “Nítorí àwọn òrìṣà àwọn ọba Siria ti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọn kí ó bà lè ràn mí lọ́wọ́.” Ṣùgbọ́n àwọn ni ìparun rẹ̀ àti ti gbogbo Israẹli.

  18. Nítorí náà, ìwọ fi wọ́n lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́, àwọn tí ó ni wọ́n lára. Ṣùgbọ́n nígbà tí a ni wọ́n lára wọ́n kígbe sí ọ. Ìwọ gbọ́ wọn láti ọ̀run wá àti nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àánú rẹ, ìwọ fún wọn ní olùgbàlà, tí ó gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn.

  19. “Ṣùgbọ́n bí wọ́n bá ti wà nínú ìsinmi, wọn a sì túnṣe búburú lójú rẹ. Nígbà náà ni ìwọ kọ̀ wọ́n sílẹ̀ ṣọ́wọ́ àwọn ọ̀tá kí wọ́n lè jẹ ọba lórí wọn. Nígbà tí wọ́n bá sì tún kígbe sí ọ, ìwọ a gbọ́ láti ọ̀run wá, àti nínú àánú rẹ ni ìwọ gbà láti ìgbà dé ìgbà.

  20. “Ìwọ kìlọ̀ fún wọn láti padà sínú òfin rẹ, ṣùgbọ́n wọ́n hu ìwà ìgbéraga, wọ́n sì ṣe àìgbọ́ràn si àṣẹ rẹ. Wọ́n ṣẹ̀ sí ìlànà rẹ, nípa èyí tí ènìyàn yóò yè tí wọ́n bá pa wọ́n mọ́. Nínú agídí ọkàn wọ́n kọ ẹ̀yìn sí ọ, wọ́n jẹ́ olórí kunkun wọn kò sì fẹ́ gbọ́.

  21. Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ni ìwọ fi ní sùúrù pẹ̀lú wọn. Nípa ẹ̀mí rẹ ni ìwọ kìlọ̀ fún wọn nípasẹ̀ àwọn wòlíì. Síbẹ̀ wọn kò fi etí sílẹ̀, nítorí náà ni ìwọ ṣe fi wọ́n lé àwọn aládùúgbò wọn lọ́wọ́.

  22. Ṣùgbọ́n nínú ọ̀pọ̀ àánú rẹ, ìwọ kò mú òpin bá wọn tàbí kọ̀ wọ́n sílẹ̀, nítorí ìwọ ni Ọlọ́run olóore-ọ̀fẹ́ àti aláàánú.

  23. “Ǹjẹ́ nítorí náà, Ọlọ́run wa, Ọlọ́run tí ó tóbi, tí ó lágbára, tí ó sì ní ẹ̀rù, ẹni tí ó pa májẹ̀mú ìfẹ́ mọ́, má ṣe jẹ́ gbogbo ìnira yìí dàbí ohun kékeré ní ojú rẹ—ìnira tí ó ti wá sórí wa, sórí àwọn ọba wa àti àwọn olórí wa, sórí àwọn àlùfáà wa àti àwọn wòlíì, sórí àwọn baba wa àti sórí gbogbo ènìyàn rẹ̀, láti àwọn ọjọ́ àwọn ọba Asiria wá títí di òní.

  24. Ìwọ jẹ́ olódodo nínú ohun gbogbo tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí wa; ìwọ sì ti ṣe òtítọ́, nígbà tí a bá ṣe búburú.

  25. Àwọn ọba wa, àwọn olórí wa, àwọn àlùfáà wa, àti àwọn baba wa kò tẹ̀lé òfin rẹ; wọn kò fetísílẹ̀ sí àṣẹ rẹ tàbí àwọn ìkìlọ̀ tí ìwọ fún wọn.