Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Idolatry: Judicial death
Àwọn ẹsẹ nípa Judicial death
Bí ọkùnrin tàbí obìnrin kan tó ń gbé láàrín yín ní èyíkéyìí ìlú wọ̀n-ọn-nì, tí Olúwa fún un yín bá ń ṣe ibi ní ojú Olúwa Ọlọ́run yín, ní ríré májẹ̀mú rẹ̀ kọjá,
èyí tí ó lòdì sí òfin mi, ó ń sin ọlọ́run mìíràn, ó ń foríbalẹ̀ fún wọn: àní sí oòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run,
tí èyí sì dé etí ìgbọ́ ọ yín, kí ẹ wádìí ọ̀rọ̀ náà dájúdájú. Bí ó bá jẹ́ òtítọ́ tí ó sì hàn gbangba pé ó ti ṣe ohun ìríra yìí, ní Israẹli.
Ẹ mú ọkùnrin tàbí obìnrin tí ó ti ṣe ibi yìí wá sí ẹnu-ọ̀nà ibodè ìlú u yín, kí ẹ sọ ọ́ ní òkúta pa.