Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Gospel

110 ẹsẹ · 2 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ǹjẹ́ fún ẹni tí ó ní agbára láti fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀ nípa ìyìnrere mi àti ìpolongo Jesu Kristi, gẹ́gẹ́ bí ìṣípayá ohun ìjìnlẹ̀ tí a ti pamọ́ láti ìgbà ayérayé,

  2. ṣùgbọ́n, nísinsin yìí, a ti fihàn nípa ìwé mímọ́ àwọn wòlíì, àti gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Ọlọ́run ayérayé pa, kí gbogbo orílẹ̀-èdè le ní ìgbọ́ràn tí ó wá láti inú ìgbàgbọ́;

  3. Ṣùgbọ́n sí àwọn tí Ọlọ́run tí pè, àti àwọn Júù àti àwọn Giriki, Kristi ni agbára Ọlọ́run, àti ọgbọ́n Ọlọ́run.

  4. Nítorí pé òmùgọ̀ Ọlọ́run jù ọgbọ́n ènìyàn lọ; àti aláìlera Ọlọ́run ni agbára jù ìlera ènìyàn lọ.

  5. Ìwàásù mi àti ẹ̀kọ́ mi, kì í ṣe nípa ọgbọ́n ènìyàn àti ọ̀rọ̀ tí a fi ń yí ènìyàn lọ́kàn padà, bí kò ṣe nípa ìfihàn agbára Ẹ̀mí.

  6. Kí ìgbàgbọ́ yín kí ó má ṣe dúró lórí ọgbọ́n ènìyàn, ṣùgbọ́n kí ó dúró lórí agbára Ọlọ́run.

  7. Ṣùgbọ́n àwa ń sọ̀rọ̀ ọgbọ́n láàrín àwọn tí a pè, ṣùgbọ́n kì í ṣe ọgbọ́n ti ayé yìí tàbí ti àwọn olórí ayé yìí, èyí tí yóò di asán.

  8. Bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa ń sọ̀rọ̀ ọgbọ́n ti Ọlọ́run tó fi ara sin, ọgbọ́n tí ó ti fi ara pamọ́, èyí tí Ọlọ́run ti lànà sílẹ̀ ṣáájú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé fún ògo wa.

  9. Nítorí pé bí mo ti ń wàásù ìyìnrere, kì í ṣe ohun tí mo lè máa ṣògo lè. Èmi kò tilẹ̀ le è ṣe é ní, kí a tilẹ̀ sọ pé mo fẹ́ kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Ègbé ni fún mi tí mo bá kọ̀ láti wàásù ìyìnrere.

  10. Tó bá jẹ́ pé mò ń wàásù tinútinú mi, mo ní èrè kan, ṣùgbọ́n tí ń kò bá ṣe tinútinú mi, a ti fi iṣẹ́ ìríjú lé mi lọ́wọ́.

  11. Ní irú ipò báyìí, kín ni ẹ rò pé yóò jẹ èrè mi ni láti jẹ́? Èrè mi ní àgbàyanu ayọ̀ tí mo ń rí gbà nípa ìwàásù ìyìnrere láìgba owó lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, láìbéèrè ẹ̀tọ́ mi lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni.

  12. Ǹjẹ́ ará, èmi ń sọ ìyìnrere náà dí mí mọ̀ fún un yín, tí mo ti wàásù fún un yín, èyí tí ẹ̀yin pẹ̀lú ti gbá, nínú èyí tí ẹ̀yin sì dúró.

  13. Nípasẹ̀ ìyìnrere yìí ni a fi ń gbà yín là pẹ̀lú, bí ẹ̀yin bá di ọ̀rọ̀ ti mo ti wàásù fún yín mú ṣinṣin. Bí bẹ́ẹ̀ kọ̀, ẹ̀yin kàn gbàgbọ́ lásán.

  14. Ẹni tí ó mú wa yẹ bí ìránṣẹ́ májẹ̀mú tuntun; kì í ṣe ní ti ìwé àkọsílẹ̀ ṣùgbọ́n ní ti ẹ̀mí, nítorí ìwé a máa pa ni, ṣùgbọ́n ẹ̀mí a máa sọ ní di ààyè.

  15. Ṣùgbọ́n bí iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí ikú, tí a tí kọ tí a sì ti gbẹ́ sí ara òkúta bá jẹ́ ológo tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ọmọ Israẹli kò lè tẹjúmọ́ wíwo ojú Mose nítorí ògo ojú rẹ̀ (ògo ti ń kọjá lọ);

  16. yóò ha ti rí tí iṣẹ́ ìránṣẹ́ ti ẹ̀mí kì yóò kúkú jẹ́ ògo jù?

  17. Nítorí pé bi iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìdálẹ́bi bá jẹ́ ológo, mélòó mélòó ni iṣẹ́ ìránṣẹ́ òdodo yóò tayọ jù ú ní ògo.

  18. Nítorí, èyí tí a tí ṣe lógo rí, kó lógo mọ́ báyìí, nítorí ògo tí ó tayọ.

  19. Nítorí pé bí èyí ti ń kọjá lọ bá lógo, mélòó mélòó ni èyí tí ó dúró kí yóò ní ògo!

  20. Ṣùgbọ́n báyìí, bí ìyìnrere wa bá sí fi ara sin, ó fi ara sin fún àwọn tí ó ń ṣègbé.

  21. Nínú àwọn ẹni tí ọlọ́run ayé yìí ti sọ ọkàn àwọn aláìgbàgbọ́ dí afọ́jú, kí ìmọ́lẹ̀ ìyìnrere Kristi tí ó lógo, ẹni tí í ṣe àwòrán Ọlọ́run, má ṣe mọ́lẹ̀ nínú wọn.

  22. Nítorí ohun ìjà wa kì í ṣe ti ara, ṣùgbọ́n ó lágbára nínú Ọlọ́run láti wó ibi gíga palẹ̀.

  23. Àwa ń sọ gbogbo èrò àti gbogbo ohun gíga ti ń gbe ara rẹ̀ ga sí ìmọ̀ Ọlọ́run kalẹ̀, àwa sì ń di gbogbo èrò ní ìgbèkùn wá sí ìtẹríba fún Kristi.

  24. Àti ẹ̀yin pẹ̀lú darapọ̀ nínú Kristi nígbà tí ẹ̀yin gbọ́ ọ̀rọ̀ òtítọ́ náà àní ìyìnrere ìgbàlà yin. Nígbà tí ẹ̀yin gbàgbọ́, a fi Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe èdìdì ayé yin nínú rẹ, èyí tí a ti ṣe ìlérí rẹ̀ tẹ́lẹ̀,

  25. èyí tí ó jẹ́ ìdánilójú àṣansílẹ̀ ogún wa títí yóò fi di àkókò ìràpadà àwọn tí í ṣe ti Ọlọ́run sí ìyìn ògo rẹ̀.