- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Commandments
Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì
síbẹ̀ ẹ mú ayọ̀ mi kún nínú ìṣọ̀kan yín, nípa ìfẹ́ kan náà, wíwà ní ẹ̀mí kan náà àti ète kan náà.
Ẹ má ṣe ohunkóhun nínú ìlépa ara tàbí ògo asán, ṣùgbọ́n ní ìrẹ̀lẹ̀ ọkàn kí olúkúlùkù ro àwọn ẹlòmíràn sí ẹni ti ó sàn ju òun lọ.
Kí olúkúlùkù yín má ṣe ro ohun ti ara rẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n ti ẹlòmíràn pẹ̀lú.
Nínú ìbáṣepọ̀ yin pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, ẹ ni irú ìlépa ọkàn náà bí ti Kristi Jesu.
Ẹni tí, bí o tilẹ̀ jẹ́ ìrísí Ọlọ́run, kò kà á sí ohun tí ìbá fi ìwọra gbámú láti bá Ọlọ́run dọ́gba.
Ṣùgbọ́n ó bọ́ ògo rẹ̀ sílẹ̀, ó sì mú àwọ̀ ìránṣẹ́, a sì ṣe é ni àwòrán ènìyàn.
Ó sì wà ní àwòrán ènìyàn, ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, o sì tẹríba títí de ojú ikú, àní ikú lórí àgbélébùú.
Nítorí náà ẹ̀yin ará mi, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti ń gbọ́rọ̀ nígbà gbogbo, kì í ṣe nígbà ti mo wà lọ́dọ̀ yín nìkan, ṣùgbọ́n pàápàá nísinsin yìí tí èmi kò sí ni àárín yín, ẹ máa ṣiṣẹ́ ìgbàlà yín yọrí pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìwárìrì,
nítorí pé Ọlọ́run ni ó n ṣiṣẹ́ nínú yín, láti fẹ́ àti láti ṣiṣẹ́ fún ète rere rẹ̀.
Ẹ máa ṣe ohun gbogbo láìsí ìkùnsínú àti ìjiyàn.
Kí ẹ̀yin lè jẹ́ aláìlẹ́gàn àti oníwà mímọ́, ọmọ Ọlọ́run, aláìlábàwọ́n, láàrín oníwà wíwọ́ àti alárékérekè orílẹ̀-èdè láàrín àwọn ẹni tí a ń rí yín bí ìmọ́lẹ̀ ní ayé.
Bí ẹ sì ṣe di ọ̀rọ̀ ìyè mú gírígírí, kí èmi lè ṣògo ni ọjọ́ Kristi pé èmi kò sáré lásán, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì ṣe làálàá lásán.
Ẹ máa yọ̀ nínú Olúwa nígbà gbogbo: mo sì tún wí pé. Ẹ máa yọ̀.
Ẹ jẹ́ ki ìpamọ́ra yín di mímọ́ fún gbogbo ènìyàn, Olúwa ń bẹ nítòsí.
Ẹ má ṣe ṣe àníyàn ohunkóhun; ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo, nípa àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́, ẹ máa fi ìbéèrè yín hàn fún Ọlọ́run.
Ní àkótán, ará, ohunkóhun tí í ṣe òtítọ́, ohunkóhun tí í ṣe ọ̀wọ̀, ohunkóhun tí í ṣe títọ́ ohunkóhun tí í ṣe mímọ́, ohunkóhun tí í ṣe fífẹ́, ohunkóhun tí ó ni ìròyìn rere, bí ìwà títọ́ kan bá wà, bí ìyìn kan bá sì wà, ẹ máa gba nǹkan wọ̀nyí rò.
Àwọn nǹkan tí ẹ̀yin ti kọ́, tí ẹ̀yin sì ti gbà, tí ẹ̀yin sì ti gbọ́, tí ẹ̀yin sì ti rí lọ́wọ́ mi, ẹ máa ṣe wọ́n: Ọlọ́run àlàáfíà yóò sì wà pẹ̀lú yín.
Bí ẹ̀yin bá ti kú pẹ̀lú Kristi si àwọn agbára ìlànà ayé yìí, kín ló dé tí ẹ̀yin ń tẹríba fún òfin bí ẹni pé ẹ̀yin wà nínú ayé.
Má ṣe dìímú, má ṣe tọ́ ọ wò, má ṣe fi ọwọ́ bà á.
Gbogbo èyí tí yóò ti ipa lílo run, gẹ́gẹ́ bí òfin àti ẹ̀kọ́ ènìyàn?
Àwọn nǹkan tí ó ní àfarawé ọgbọ́n nítòótọ́, nípasẹ̀ àdábọwọ́ ìsìn, àti ìrẹ̀lẹ̀, àti ìpọ́nra-ẹni-lójú, ṣùgbọ́n tí kò ni èrè láti di ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara ku.
Níwọ́n ìgbà tí a ti jí yín dìde pẹ̀lú Kristi ẹ máa ṣàfẹ́rí àwọn nǹkan tí ń bẹ lókè, níbi tí Kristi gbé wà tí ó jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run.
Ẹ máa ronú àwọn ohun tí ń bẹ lókè kì í ṣe àwọn nǹkan tí ń bẹ ní ayé.
Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹ gbọdọ̀ fi àwọn wọ̀nyí sílẹ̀: ìbínú, ìrunú, àrankàn, fífi ọ̀rọ̀-kẹ́lẹ́-ba-tẹni-jẹ́ àti ọ̀rọ̀ èérí kúrò ní ètè yín.
Ẹ má ṣe purọ́ fún ara yín, níwọ̀n ìgbà tí ẹ ti bọ́ ògbólógbòó ara yín pẹ̀lú ìṣe rẹ̀ sílẹ̀,