Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Commandments

394 ẹsẹ · 3 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ẹ jẹ́ kí a di ìjẹ́wọ́ ìrètí wa mu ṣinṣin ni àìṣiyèméjì, nítorí pé olóòtítọ́ ní ẹni tí o ṣe ìlérí.

  2. Ẹ jẹ́ kí a yẹ ara wa wò láti ru ara wa sí ìfẹ́ àti sí iṣẹ́ rere,

  3. kí a ma máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀, gẹ́gẹ́ bi àṣà àwọn ẹlòmíràn; ṣùgbọ́n kí a máa gba ara ẹni níyànjú pẹ̀lúpẹ̀lú bí ẹ̀yin ti rí i pé ọjọ́ náà ń súnmọ́ etílé.

  4. Nítorí náà bí a ti fi ìkùùkuu àwọsánmọ̀ tí o kún fún àwọn ẹlẹ́rìí tó báyìí yí wa ká, ẹ jẹ́ kí a pa ohun ìdíwọ́ gbogbo tì sí apá kan, àti ẹ̀ṣẹ̀ tí o rọrùn láti di mọ́ wa, kí a sì máa fi sùúrù súré ìje tí a gbé ka iwájú wa,

  5. kí a máa wo Jesu Olùpilẹ̀ṣẹ̀ àti aláṣepé ìgbàgbọ́ wa; ẹni nítorí ayọ̀ tí a gbé ka iwájú rẹ, tí o faradà àgbélébùú láìka ìtìjú sí, tí ó sì jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọ́run.

  6. Máa ro ti ẹni tí ó faradà irú ìsọ̀rọ̀-òdì yìí láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ si ara rẹ̀, kí ẹ má ba á rẹ̀wẹ̀sì ni ọkàn yín, kí àárẹ̀ si mu yín.

  7. Ẹ̀yin kò sá à tí ì kọ ojú ìjà si ẹ̀ṣẹ̀ títí dé títa ẹ̀jẹ̀ yín sílẹ̀ nínú ìjàkadì yín.

  8. Ẹ̀yin sì ti gbàgbé ọ̀rọ̀ ìyànjú tí ó n ba yin sọ̀rọ̀ bí ọmọ pé, “Ọmọ mi, ma ṣe aláìnání ìbáwí Olúwa, kí o má sì ṣe rẹ̀wẹ̀sì nígbà tí a bá ń ti ọwọ́ rẹ̀ ba ọ wí,

  9. Nítorí náà, ẹ na ọwọ́ tí ó rọ, àti eékún àìlera,

  10. “Kí ẹ sì ṣe ipa ọ̀nà tí ó tọ́ fún ẹsẹ̀ yin,” kí èyí tí ó rọ má bá a kúrò lórí ike ṣùgbọ́n kí a kúkú wò ó sàn.

  11. Ẹ máa lépa àlàáfíà pẹ̀lú ènìyàn gbogbo, àti ìwà mímọ́, láìsí èyí yìí kò sí ẹni tí yóò rí Olúwa.

  12. Ẹ máa kíyèsára kí ẹnikẹ́ni má ṣe kùnà Oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run; kí gbòǹgbò ìkorò kan máa ba hù sókè kí ó sì yọ yín lẹ́nu, ọ̀pọ̀lọpọ̀ a sì ti ipa rẹ̀ di àìmọ́.

  13. Kí o má bá à si àgbèrè kan tàbí aláìwà-bí-Ọlọ́run bi Esau, ẹni tí o tìtorí òkèlè oúnjẹ kan ta ogún ìbí rẹ̀.

  14. Kí ìfẹ́ ará kí o wà títí.

  15. Ẹ má ṣe gbàgbé láti máa ṣe àlejò; nítorí pé nípa bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlòmíràn ṣe àwọn angẹli ní àlejò láìmọ̀.

  16. Ẹ máa rántí àwọn òǹdè bí ẹni tí a dè pẹ̀lú wọn, àti àwọn tí a ń pọn lójú bí ẹ̀yin tìkára yín pẹ̀lú tí ń bẹ nínú ara.

  17. Ǹjẹ́ nípasẹ̀ rẹ̀, ẹ jẹ́ kí a máa rú ẹbọ ìyìn si Ọlọ́run nígbà gbogbo, èyí yìí ni èso ètè wa, tí ń jẹ́wọ́ orúkọ rẹ̀.

  18. Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe gbàgbé láti máa ṣoore àti láti máa pín fun ni nítorí irú ẹbọ wọ̀nyí ni inú Ọlọ́run dùn sí jọjọ.

  19. Ẹ máa gbọ́ ti àwọn tí ń ṣe olórí yín, kí ẹ sì máa tẹríba fún wọ́n, nítorí wọn ń ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ nítorí ọkàn yín, bí àwọn ti yóò ṣe ìṣirò, kí wọn lè fi ayọ̀ ṣe èyí, kì í ṣe pẹ̀lú ìbànújẹ́, nítorí èyí yìí yóò jẹ àìlérè fún yín.