Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Beneficence

93 ẹsẹ · 1 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Olúwa yóò máa tọ́ ọ yín nígbà gbogbo; òun yóò tẹ́ gbogbo àìní yín lọ́rùn ní ilẹ̀ tí oòrùn ń tan ìmọ́lẹ̀ yóò sì fún egungun rẹ lókun. Ìwọ yóò sì dàbí ọgbà tí a bomirin dáradára, àti bí orísun tí omi rẹ̀ kì í gbẹ.

  2. Kò sì ni ẹnikẹ́ni lára, ó sì sanwó fún onígbèsè rẹ̀ gẹ́gẹ́ bó ṣe ṣe ìlérí fún un, kò fi ipá jalè ṣùgbọ́n ó fún ẹni tí ebi ń pa ní oúnjẹ, tí ó sì fi ẹ̀wù wọ àwọn tí ó wà ní ìhòhò.

  3. Ẹni tí kò fi fún ni láti gba ẹ̀dá, tàbí kò gba èlé tó pọ̀jù. Ó yọ ọwọ́ rẹ̀ kúrò nínú ìwà ẹ̀ṣẹ̀, ó sì ń ṣe ìdájọ́ òtítọ́ láàrín ọkùnrin kan àti èkejì rẹ̀.

  4. Tí ó ń tẹ̀lé àṣẹ mi, tí ó sì ń pa òfin mi mọ́ lóòtítọ́ àti lódodo. Ó jẹ́ olódodo, yóò yè nítòótọ́, ní Olúwa Olódùmarè wí.

  5. Nítorí ebi pa mi, ẹ̀yin sì fún mi ní oúnjẹ, òǹgbẹ gbẹ mí, ẹ̀yin sì fún mi ní omi. Mo jẹ́ àlejò, ẹ̀yin sì pè mí sínú ilé yín.

  6. Mo wà ní ìhòhò, ẹ̀yin sì daṣọ bò mí. Nígbà tí mo ṣe àìsàn ẹ ṣe ìtójú mi, àti ìgbà tí mo wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n ẹ̀yin bẹ̀ mí wò.’

  7. “Nígbà náà ni àwọn olódodo yóò fèsì pé, ‘Olúwa, nígbà wo ni àwa rí ọ tí ebi ń pa ọ́, tí a sì fún ọ ní oúnjẹ? Tàbí tí òǹgbẹ ń gbẹ ọ́ tí a sì fún ọ ní ohun mímu?

  8. Tàbí tí o jẹ́ àlejò tí a gbà ó sínú ilé wa? Tàbí tí o wà ní ìhòhò, tí a sì daṣọ bò ọ́?

  9. Nígbà wo ni a tilẹ̀ rí i tí o ṣe àìsàn, tàbí tí o wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n, tí a bẹ̀ ọ́ wò?’

  10. “Ọba náà yóò sì dáhùn yóò sì wí fún wọn pé, ‘Lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀yin ṣe nǹkan wọ̀nyí fún àwọn arákùnrin mi yìí tí o kéré jú lọ, ẹ̀ ń ṣe wọn fún mi ni.’

  11. “Nígbà náà ni yóò sọ fún àwọn tí ọwọ́ òsì pé, ‘Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin ẹni ègún, sínú iná àìnípẹ̀kun tí a ti tọ́jú fún èṣù àti àwọn angẹli rẹ̀.

  12. Nítorí tí ebi pa mi, ẹ̀yin kò tilẹ̀ bọ́ mi, òrùngbẹ gbẹ mi, ẹ kò tilẹ̀ fún mi ní omi láti mu.

  13. Mo jẹ́ àlejò, ẹ̀yin kò tilẹ̀ gbà mi sílé. Mo wà ní ìhòhò, ẹ̀yin kò fi aṣọ bò mi. Mo ṣàìsàn, mo sì wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, ẹ̀yin kò bẹ̀ mí wò.’

  14. “Nígbà náà àwọn pẹ̀lú yóò dáhùn pé, ‘Olúwa, nígbà wo ni àwa rí ọ, tí ebi ń pa ọ́ tàbí tí òǹgbẹ ń gbẹ ọ́, tàbí tí o ṣàìsàn, tàbí tí o wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, tí a kò sí ràn ọ́ lọ́wọ́?’

  15. “Nígbà náà àwọn yóò dáhùn pé, ‘Lóòótọ́ ni mo wí fún pé, nígbà tí ẹ̀yin ti kọ̀ láti ran ọ̀kan nínú àwọn tí ó kéré jù lọ́wọ́ nínú arákùnrin mi, ẹ̀yin tí kọ̀ láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún mi ni.’

  16. Ǹjẹ́ ní ọjọ́ wọ̀nyí, nígbà tí iye àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ń pọ̀ sí i, ìkùnsínú wà ní àárín àwọn Helleni tí ṣe Júù àti àwọn Heberu tí ṣe Júù, nítorí tí a gbàgbé nípa ti àwọn opó wọn nínú ìpín fún ni ojoojúmọ́.

  17. Àwọn méjìlá sì pe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn jọ sọ́dọ̀, wọn wí pé, “Kò yẹ kí àwa ó fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílẹ̀, kí a sì máa ṣe ìránṣẹ́ tábìlì.

  18. Nítorí náà, ará, ẹ wo ọkùnrin méje nínú yín, olórúkọ rere, tí ó kún fún Ẹ̀mí Mímọ́ àti fún ọgbọ́n, tí àwa lè yàn sí iṣẹ́ yìí.

  19. Ṣùgbọ́n àwa yóò dúró ṣinṣin nínú àdúrà gbígbà, àti nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ ọ̀rọ̀ náà.”

  20. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì pinnu, olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀ ti tó, láti rán ìrànlọ́wọ́ sí àwọn arákùnrin tí ó wà ní Judea.

  21. Wọn sì ṣe bẹ́ẹ̀, wọn sì fi ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí àwọn àgbà láti ọwọ́ Barnaba àti Saulu.

  22. Ṣùgbọ́n ní báyìí, mo ń lọ sí Jerusalẹmu láti sé ìránṣẹ́ fún àwọn ènìyàn mímọ́ níbẹ̀.

  23. Nítorí pé ó wu àwọn tí ó wà ní Makedonia àti Akaia láti kó owó jọ fún àwọn tálákà tí ó wà ní àárín àwọn ènìyàn mímọ́ ní Jerusalẹmu.

  24. Pẹ̀lú ayọ̀ ni wọ́n ń ṣe èyí, nítorí wọ́n gbà wí pé, wọ́n jẹ́ ajigbèsè fún wọn. Nítorí bí ó bá ṣe pé a fi àwọn Kèfèrí ṣe alájọni nínú ohun ẹ̀mí wọn, ajigbèsè sì ni wọn láti fi ohun ti ara ta wọ́n lọ́rẹ.

  25. Ǹjẹ́ ní ti ìdáwó fún àwọn ènìyàn mímọ́, bí mo tí wí fún àwọn ìjọ Galatia, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ní kí ẹ ṣe.