Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Alliance and Society with the Enemies of God

229 ẹsẹ · 51 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, mo rí àwọn ọkùnrin Juda tí wọ́n fẹ́ àwọn obìnrin láti Aṣdodu, Ammoni àti Moabu.

  2. Ìdajì àwọn ọmọ wọn ń sọ èdè Aṣdodu tàbí èdè ọ̀kan lára àwọn ènìyàn mìíràn tókù, wọn kò sì mọ bí a ṣe ń sọ èdè Juda.

  3. Mo bá wọn wí mo sì gégùn ún lé wọn lórí. Mo lu àwọn ènìyàn díẹ̀ nínú wọn mo sì fa irun orí wọn tu. Mo mú kí wọn búra ní orúkọ Ọlọ́run, kí wọn wí pé, “Ẹ̀yin kì yóò fi àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin yín ní ìyàwó tàbí fún ẹ̀yin tìkára yín.

  4. Kì í ha á ṣe àwọn ìgbéyàwó bí irú èyí ni ọba Solomoni fi dá ẹ̀ṣẹ̀? Láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, kò sí ọba kan bí i tirẹ̀. Ọlọ́run rẹ̀ fẹ́ràn rẹ̀, Ọlọ́run sì fi jẹ ọba lórí i gbogbo Israẹli, ṣùgbọ́n àwọn obìnrin àjèjì ti sọ ọ́ sínú òfin ẹ̀ṣẹ̀.

  5. Ǹjẹ́ ó ha yẹ kí àwa tún gbọ́ báyìí pé ẹ̀yin náà tún ń ṣe àwọn nǹkan tí ó burú jọjọ wọ̀nyí tí ẹ sì ń ṣe aláìṣòótọ́ sí Ọlọ́run wa nípa fífẹ́ àwọn obìnrin àjèjì?”

  6. Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà, tí kò rìn ní ìmọ̀ àwọn ènìyàn búburú, ti kò dúró ní ọ̀nà àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, tàbí tí kò sì jókòó ní ibùjókòó àwọn ẹlẹ́gàn.

  7. Kúrò lọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe iṣẹ́ ibi, nítorí Olúwa ti gbọ́ igbe mi.

  8. ní ojú ẹni tí ènìyànkénìyàn di gígàn ṣùgbọ́n ó bọ̀wọ̀ fún àwọn tí ó bẹ̀rù Olúwa, ẹni tí ó búra sí ibi ara rẹ̀ àní tí kò sì yípadà,

  9. Èmi kò jókòó pẹ̀lú aláìṣòótọ́, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò bá àwọn àgàbàgebè wọlé.

  10. Èmi ti kórìíra àwùjọ àwọn ènìyàn búburú èmi kì yóò sì bá àwọn ènìyàn ìkà jókòó.

  11. Èmi ti kórìíra àwọn ẹni tí ń fiyèsí òrìṣà tí kò níye lórí; ṣùgbọ́n èmi gbẹ́kẹ̀lé Olúwa.

  12. Nígbà tí ìwọ rí olè, ìwọ dára pọ̀ mọ́ ọn, ìwọ sì da ara rẹ dé àwọn alágbèrè.

  13. Mo wà ní àárín àwọn kìnnìún; mo dùbúlẹ̀ ni abẹ́ àwọn ẹ̀dá búburú, àwọn ènìyàn tí eyín wọn dàbí ọ̀kọ̀ àti ọfà ẹni tí ahọ́n rẹ̀ jẹ́ idà mímú.

  14. Agídí ọkàn yóò kúrò lọ́dọ̀ mi; èmi kì yóò mọ ènìyàn búburú.

  15. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń sọ̀rọ̀ ẹnìkejì rẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀, òun ní èmi yóò gé kúrò ẹni tí ó bá gbé ojú rẹ̀ ga tí ó sì ní ìgbéraga àyà, òun ní èmi kì yóò faradà fún.

  16. Ojú mi yóò wà lára àwọn olóòtítọ́ lórí ilẹ̀, kí wọn kí ó lè máa bá mi gbé; ẹni tí ó bá n rin ọ̀nà pípé òun ni yóò máa sìn mí.

  17. Ẹni tí ó bá ń ṣe ẹ̀tàn, kì yóò gbé ilé mi, kò sí ẹni tí ń ṣèké tí yóò dúró ní iwájú mi.

  18. wọ́n mú Ọlọ́run bínú pẹ̀lú ohun búburú tí wọn ń ṣe àjàkálẹ̀-ààrùn jáde láàrín wọn.

  19. Wọ́n sì sin àwọn òrìṣà wọn tí ó di ìkẹ́kùn fún wọn.

  20. Wọ́n fi àwọn ọmọkùnrin wọn rú ẹbọ àti àwọn ọmọbìnrin fún òrìṣà.

  21. Wọ́n ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀, ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wọ. Wọ́n fi wọ́n rú ẹbọ sí ère Kenaani, ilẹ̀ náà sì di àìmọ́ fún ẹ̀jẹ̀.

  22. Nígbà náà ni Olúwa bínú sí àwọn ènìyàn rẹ̀ ó sì kórìíra àwọn ènìyàn ìní rẹ̀

  23. Ó sì fà wọ́n lé àwọn orílẹ̀-èdè lọ́wọ́, àwọn ọ̀tá wọn sì jẹ ọba lórí wọn.

  24. Àwọn ọ̀tá wọn sì ń pọ́n wọn lójú wọn sì mú wọn sìn lábẹ́ àṣẹ wọn.

  25. Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin olùṣe búburú, kí èmi lè pa àṣẹ Ọlọ́run mi mọ́!