Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Alliance and Society with the Enemies of God: A call to come out from
Àwọn ẹsẹ nípa A call to come out from
Ó sì kìlọ̀ fún ìjọ ènìyàn pé, “Ẹ kúrò ní àgọ́ àwọn ènìyàn búburú yìí! Ẹ má ṣe fọwọ́ kan ohun kan tí í ṣe tiwọn kí ẹ má ba à parun nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”
Nísinsin yìí, ẹ jẹ́wọ́ níwájú Olúwa, Ọlọ́run àwọn baba yín, kí ẹ sì ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Ẹ ya ara yín sọ́tọ̀ kúrò láàrín àwọn ènìyàn tí ó yí i yín ká àti láàrín àwọn ìyàwó àjèjì yín.”
“Sá kúrò ní Babeli! Sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ! Má ṣe ṣègbé torí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ. Àsìkò àti gbẹ̀san Olúwa ni èyí; yóò sán fún òun gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́.
“Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀ ẹ̀yin ènìyàn mi! Sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ! Sá fún ìbínú ńlá Olúwa.
Nítorí náà, “Ẹ jáde kúrò láàrín wọn, kí ẹ sì yá ara yín si ọ̀tọ̀, ni Olúwa wí. Ki ẹ má ṣe fi ọwọ́ kan ohun àìmọ́; Èmi ó sì gbà yín.”
Ní orúkọ Jesu Kristi Olúwa wa, àwa pàṣẹ fún un yín ará, pé kí ẹ yẹra fún gbogbo àwọn arákùnrin yín tí ń ṣe ìmẹ́lẹ́, tí kò sì gbé ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀kọ́ tí ẹ gbà ní ọ̀dọ̀ wa.
Mo sì gbọ́ ohùn mìíràn láti ọ̀run wá, wí pé: “ ‘Ẹ ti inú rẹ̀ jáde, ẹ̀yin ènìyàn mi,’ kí ẹ ma bá a ṣe alábápín nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, kí ẹ ma bà á sì ṣe gbà nínú ìyọnu rẹ̀.