Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Alliance and Society with the Enemies of God: Blessedness of forsaking
Àwọn ẹsẹ nípa Blessedness of forsaking
Nítorí náà, ẹ má ṣe fi àwọn ọmọbìnrin yín fún àwọn ọmọkùnrin wọn ní ìyàwó tàbí kí ẹ fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin yín ní ìyàwó. Ẹ má ṣe dá májẹ̀mú àlàáfíà pẹ̀lú wọn nígbàkígbà kí ẹ̀yin kí ó sì le lágbára, kí ẹ sì le máa jẹ ire ilẹ̀ náà, kí ẹ sì le fi í sílẹ̀ fún àwọn ọmọ yín gẹ́gẹ́ bí ogún ayérayé.’
Fi ìwà àìmọ̀kan rẹ sílẹ̀ ìwọ yóò sì yè; rìn ní ọ̀nà òye.
Nítorí náà, “Ẹ jáde kúrò láàrín wọn, kí ẹ sì yá ara yín si ọ̀tọ̀, ni Olúwa wí. Ki ẹ má ṣe fi ọwọ́ kan ohun àìmọ́; Èmi ó sì gbà yín.”
Àti, “Èmi o sì jẹ́ Baba fún yín. Ẹ̀yin ó sì jẹ́ ọmọkùnrin mi àti ọmọbìnrin mi, ní Olúwa Olódùmarè wí.”