Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Alliance and Society with the Enemies of God: Punishment of

15 ẹsẹ · 51 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Punishment of

  1. Nígbà náà, èmi yóò ṣe sí yín, ohun tí mo ti rò láti ṣe sí wọn.’ ”

  2. torí pé wọ́n yóò yí àwọn ọmọ rẹ padà kúrò lẹ́yìn mi, láti jẹ́ kí wọn máa sin òrìṣà, ìbínú Olúwa yóò sì wá sórí rẹ, yóò sì run yín kíákíá.

  3. Nígbà náà ni ẹ ó mọ̀ dájú pé Olúwa Ọlọ́run yín kì yóò lé àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí jáde mọ́ kúrò níwájú yín. Dípò èyí, wọn yóò jẹ́ ìkẹ́kùn àti tàkúté fún un yín, pàṣán ní ẹ̀yin yín àti ẹ̀gún ní ojú yín, títí ẹ ó fi ṣègbé kúrò ní ilẹ̀ dáradára yí, èyí tí Olúwa Ọlọ́run yín ti fi fún yín.

  4. Ní báyìí, èmi wí fún un yín pé, èmi kì yóò lé àwọn ènìyàn jáde kúrò níwájú yín; ṣùgbọ́n wọn yóò jẹ́ ẹ̀gún ní ìhà yín, àwọn òrìṣà wọn yóò sì jẹ́ ìdánwò fún un yín.”

  5. Àwọn ọmọ Israẹli gbé láàrín àwọn ará Kenaani, àwọn ará Hiti àwọn ará Amori, àwọn ará Peresi, àwọn ará Hifi àti àwọn ará Jebusi.

  6. Dípò kí wọ́n run àwọn ènìyàn wọ̀nyí, Israẹli ń fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn, wọ́n sì ń fi àwọn ọmọbìnrin Israẹli fún àwọn ará ilẹ̀ náà ní aya, wọ́n sì ń sin àwọn òrìṣà wọn.

  7. Àwọn ọmọ Israẹli sì ṣe èyí tí ó burú níwájú Olúwa, wọ́n gbàgbé Olúwa Ọlọ́run wọn, wọ́n sì ń sin Baali àti Aṣerah.

  8. Ìbínú Olúwa sì ru sí Israẹli tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ kí Kuṣani-Riṣataimu ọba Aramu-Naharaimu bá wọn jà kí ó sì ṣẹ́gun wọn, Israẹli sì ṣe ẹrú rẹ̀ fún ọdún mẹ́jọ.

  9. Láti ọjọ́ àwọn baba wá ni ẹ̀bi wa ti pọ̀ jọjọ títí di ìsinsin yìí. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, àwa àti àwọn ọba wa àti àwọn àlùfáà wa ni a ti sọ di ẹni idà, ẹni ìgbèkùn, ìkógun àti ẹni ẹ̀sín lọ́wọ́ àwọn àjèjì ọba, bí ó ti rí lónìí.

  10. Ǹjẹ́ ó yẹ kí àwa tún yẹ̀ kúrò nínú àṣẹ rẹ, kí a sì máa ṣe ìgbéyàwó papọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí wọn ti ṣe onírúurú ohun ìríra báyìí? Ṣe ìwọ kò ní bínú sí wa láti pa wá run tí kì yóò sẹ́ ku ẹnikẹ́ni tí yóò là?

  11. Ó sì fà wọ́n lé àwọn orílẹ̀-èdè lọ́wọ́, àwọn ọ̀tá wọn sì jẹ ọba lórí wọn.

  12. Àwọn ọ̀tá wọn sì ń pọ́n wọn lójú wọn sì mú wọn sìn lábẹ́ àṣẹ wọn.

  13. Nítorí náà, ronúpìwàdà; bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, èmi ó tọ̀ ọ́ wá nísinsin yìí, èmí o sì fi idà ẹnu mi bá wọn jà.

  14. Nítorí náà, èmi ó gbé e sọ sí orí àkéte ìpọ́njú, àti àwọn tí ń bá a ṣe panṣágà ni èmi ó fi sínú ìpọ́njú ńlá, bí kò ṣe bí wọ́n bá ronúpìwàdà iṣẹ́ wọn.

  15. Èmi o pa àwọn ọmọ rẹ̀ run; gbogbo ìjọ ni yóò sì mọ̀ pé, èmi ni ẹni tí ń wádìí inú àti ọkàn, èmi ó sì fi fún olúkúlùkù yín gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀.