Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Alliance and Society with the Enemies of God
Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì
Ègbé ni fún mi tí èmi ṣe àtìpó ní Meṣeki, nítorí èmi gbé nínú àgọ́ ìlú Kedari!
Ó ti pẹ́ tí èmi ti ń gbé láàrín àwọn tí ó kórìíra àlàáfíà.
Ọlọ́run ìbá jẹ́ pa àwọn ènìyàn búburú nítòótọ́; nítorí náà kúrò lọ́dọ̀ mi ẹ̀yin ọkùnrin ẹlẹ́jẹ̀.
Ọmọ mi, bí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bá ń tàn ọ́, má ṣe gbà fún wọn.
Bí wọn bá wí pé, “Wá pẹ̀lú wa; jẹ́ kí á ba ní ibùba fún ẹ̀jẹ̀ ẹnìkan, jẹ́ kí á lúgọ ní ìkọ̀kọ̀ de aláìṣẹ̀ ní àìnídìí;
jẹ́ ká gbé wọn mì láààyè, bí ibojì òkú, àti lódidi, bí àwọn tí ń sọ̀kalẹ̀ lọ sínú kòtò;
a ó rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan tó níye lórí a ó sì fi ìkógun kún inú ilé wa,
da ìpín rẹ pọ̀ mọ́ àárín wa, a ó sì jọ pawó sínú àpò kan náà,”
ọmọ mi, má ṣe bá wọn lọ, má ṣe rìn ní ojú ọ̀nà wọn.
Nítorí ọgbọ́n yóò wọ inú ọkàn rẹ ìmọ̀ yóò sì jẹ́ ìtura fún ọkàn rẹ.
Ìmòye yóò pa ọ mọ́ òye yóò sì máa ṣọ́ ọ.
Ọgbọ́n yóò gbà ọ́ là kúrò ní ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú, lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn tí ọrọ̀ ọ wọn jẹ́ àyídáyidà,
ẹni tí ó kúrò ní ọ̀nà ìdúró ṣinṣin láti rìn ní ọ̀nà tí ó ṣókùnkùn,
ẹni tí ó yọ̀ nínú ṣíṣe búburú, tí ó ṣe inú dídùn sí àyídáyidà àwọn ènìyàn ibi,
ọ̀nà ẹni tí ó wọ́ tí wọ́n sì jẹ́ alárékérekè ní ọ̀nà wọn.
Yóò gba ìwọ pẹ̀lú là kúrò lọ́wọ́ àwọn àjèjì obìnrin, àní, lọ́wọ́ obìnrin àjèjì tí ń fi ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ tannijẹ,
ẹni tí ó ti kọ ọkọ àkọ́fẹ́ ìgbà èwe rẹ̀ sílẹ̀ tí ó sì gbàgbé májẹ̀mú tí ó ti dá níwájú Ọlọ́run rẹ̀.
Nítorí ilé rẹ̀ jẹ́ ọ̀nà sí ikú ipa ọ̀nà rẹ̀ sọ́dọ̀ àwọn òkú.
Kò sẹ́ni tó lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ tí ó padà bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í dé ọ̀nà ìyè.
Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ yóò rìn ní ọ̀nà àwọn ènìyàn rere kí ìwọ kí ó sì pa ọ̀nà àwọn olódodo mọ́.
Má ṣe gbé ẹsẹ̀ rẹ sí ojú ọnà àwọn ènìyàn búburú tàbí kí o rìn ní ọ̀nà àwọn ẹni ibi.
Yẹra fún un, má ṣe rìn níbẹ̀; yàgò fún un kí o sì bá ọ̀nà tìrẹ lọ.
Fi ìwà àìmọ̀kan rẹ sílẹ̀ ìwọ yóò sì yè; rìn ní ọ̀nà òye.
Ẹni tí ó bá dá oko yóò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ, ṣùgbọ́n ẹni tí ń lépa òjìji lásán làsàn kò gbọ́n.
Má ṣe súnmọ́ aláìgbọ́n ènìyàn, nítorí ìwọ kì yóò rí ìmọ̀ ní ètè rẹ̀.